Yemi Osinbajo: Osinbajo wọ́gilé ìrìn-àjò rẹ̀ lẹ́yìn tí ọ̀kan lára ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ kú lọ́nà pápákọ̀ òfurufú

Ojogbon Yemi Osinbajo

Oríṣun àwòrán, Twitter/Prof Yemi Osinbajo

Ọkan lara awọn ẹṣọ igbakeji aarẹ, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo ṣagbako iku ojiji ninu ijamba alupupu lọjọ Ẹti.

Ali Gomina, to jẹ ọlọpaa insipẹkitọ gbẹmi mi ninu ijamba naa to ṣẹlẹ lọna papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe niluu Abuja.

Gẹgẹ bi ọrọ ti oludamọran igbakeji aarẹ lori ọrọ iroyin, Laolu Akande sọ, Gomina wa lara awọn ẹṣọ to n sin igbakeji aarẹ lọ nigba ti iṣẹlẹ buruku naa ṣẹlẹ.

Ọgbẹni Akande ṣalaye pe igbakeji aarẹ ti wọgile irin-ajo to fẹ rin naa lẹyin iku ọlọpaa ọun to jẹ ẹni ọdun mẹẹdọgbọn.

Ojogbon Yemi Osinbajo

Oríṣun àwòrán, Twitter/Prof Yemi Osinbajo

Ọjọgbọn Osinbajo ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bi ẹni to jara mọ iṣẹ to ṣi ṣe fi ọkan tan an.

Gomina fi iyawo atawọn ọmọ silẹ lọ, oludamọran igbakeji aarẹ gbadura pe ki Eleduwa tẹ ẹ si afẹfẹ rere.