Coronavirus: Ushbebe, adẹ́rínpòṣónú ní bí ìjọba ṣe fòfin de ìrìnàjò wọlé láti ilẹ̀ òkèrè mú òun pàdánù owó l

Justice Nuagbe Ushbebe

Oríṣun àwòrán, Instagram/ushbebecomedia

Igbesẹ ijọba apapọ orilẹede Naijiria to fofin de irinajọ lọ si awọn orilẹede mẹtala ti arun coronavirus ti n ṣọṣẹ ti ni ipalara fun ọpọ ọmọ Naijiria ti wọn ti rinrin ajo lọ si awọn orilẹede naa tabi ti wọn fẹ ṣẹṣẹ lọ si bẹ.

Awọn orilẹede ti ọrọ kan naa ni orilẹede China, Italy, Iran, South Korea, Spain, Japan, Faranse, Germany, Amẹrika, Norway, ilẹ Gẹẹsi, Netherlands ati orilẹede Switzerland.

Ijọba apapọ ni ohun gbe igbesẹ yii nitori awọn eeyan to ti lugbadi arun Coronavirus ti ju ẹgbẹrun kan lọ lawọn ilẹ naa.

Lara awọn ti wọn ti wa lọhun ki ijọba to kede l'Ọjọru ṣalaye pe ajalu airotẹlẹ ni ikede ijọba apapọ Naijiria jẹ fawọn nitori awọn ni lati maa tete bọ wa si Naijiria ṣaaju ọjọ Satide ti ofin naa yoo di mimuṣẹ.

Adẹrinpoṣonu ọmọ Naijiria to rinrin ajo lọ si ilẹ Gẹẹsi, Justice Nuagbe ti ọpọ mọ si Ushbebe ikede naa ti mu ki wọgile eto ti mo fẹ ṣe lọjọ Aiku to n bọ niluu London ati awọn eto miiran to mu oun rinrin ajo lọ si ilẹ Gẹẹsi.

Justice Nuagbe Ushbebe

Oríṣun àwòrán, Instagram/ushbebe comedian

Ko tan sibẹ o, Ushbebe ni igbesẹ ijọba lati fofin de irinajo sawọn orilẹede mẹtala naa na oun owo lowo airotẹlẹ nitori oun ni lati ra tikẹti mii ki oun le pada sile.

Ṣugbọn o ni ilera ara oun ṣe pataki ju owo ti oun padanu lọ nitori igbesẹ ijọba to fofin de irin ajo sawọn orilẹede ilẹ okeere ti arun coronavirus ti ba wọn finra.

Coronavirus: 'Mo sáré padà sí Nàìjíríà láti Uk lẹ́yìn t'íjọba fòfin de ìrìnàjò sílẹ̀ òkèrè'

Ninu ọrọ tiẹ, Arabinrin kan toun naa ṣẹṣẹ de lati ilẹ Gẹẹsi bayii to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe erongba oun tẹlẹ ni lati gba ilẹ Geẹṣi lọ si orilẹede Amẹrika.

Amọ o sọ pe ko le ṣeeṣe mọ foun bayii lẹyin ti ijọba ti fofin de irinajo si awọn orilẹede mejeeji.

O fikun ọrọ rẹ wi pe ohun to f'oun bayii ni lati dari wale ki o di ọjọ Satide.

Awọn Naijiria ni papakọ ofurufu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O sọ fun BBC Yoruba pe ninu ibẹru lawọn n gbe nilẹ Geẹṣi bayii nitori yala o wa ninu ọkọ, tabi oun n wo ẹrọ amohunmaworan, ọrọ coronavirus lawọn eeyan n sọ.

Arabinrin naa ni ojoojumọ lọpọ eeyan n lugbadi arun coronavirus, debi wi pe coronavirus lẹ maa ri lori foonu tabi lori ẹrọ ayelujara ati ẹrọ agbọrọkaye.

Ṣugbọn ''inu mi dun wi pe mo ti lanfaani lati pada si orilẹede Naijiria, ṣugbọn ibẹrubojo ni mo fi kuro nilẹ Gẹẹsi silẹ.''

O sọ pe oun ṣetan lati ya ara oun sọtọ fun ọjọ mẹrinla bayii gẹgẹ bi alakalẹ ijọba fawọn to ba ṣeṣẹ rinrin ajo de lati awọn orilẹede mẹtala ti ijọba apapọ fofin de.