Cornavirus: Makinde tọrọ aforiji fun ìpàdé ìta gbangba ẹgbẹ́ PDP tó wáyé nílu Ibadan

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinde
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde titọrọ aforiji lọwọ awọn eeyan ipinlẹ naa fun ipade ita gbangba ẹgbẹ PDP to waye nilu Ibadan laarin awuyeeuye Coronavirus to gbode.
Makinde lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan to fi soju opo Twitter rẹ.
O ni "Mo ti gbọ ẹdun ọkan yin nipa iwọde ti a ṣe lana, mo si fẹ sọ wipe a pinu lati ṣe miwọde naa lasiko yii nitori awọn iroyin to tẹ wa lọwọ lasiko naa."
- Dandan kọ́ ni kí Buhari ó bá ayín sọ̀rọ̀ lórí coronavirus, ó ti ṣe gbogbo nkan tó yẹ kó ṣe - Iléèṣẹ́ ààrẹ
- Iléyá! Àwọn ọmọ Nàìjíríà ń sáré wálé torí àṣẹ ìjọba tó wọ́gilé ìrìnàjò láti òké òkun
- Ilé ẹjọ́ dá pásítọ̀ ìjọ Sotitobire padà sọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ó sún ẹjọ́ síwájú
- Ẹgbẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi kéde àdúrà nítórí àrùn Coronavirus
"Ko yẹ ki iwọde naa waye, mo gba pe mo ṣe jẹbi lati gunle iwọde naa."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Makinde tẹsiwaju pe ojuṣe oun gẹgẹ bi gomina ni lati dabo bo awọn eeyanb ipinlẹ naa, ati pe ijọba rẹ yoo ṣe gbogboi ohun to yẹ ni ṣiṣe lati dena arun Coronavirus.
Lẹyin naa lo rọ awọn ara ilu lati ma foya lori iroyin itankalẹ arun Coronavirus nitor ale bori arun naa ti a ba fọwọ sowọpọ.
Gomina ọhun tẹsiwaju pe imọtoto ara ẹni ṣe pataki lasiko yii.
O ni "Awọn eleto ilera ti fi han pe fifọ ọwọ ẹni pẹlu ọṣẹ ati omi fun ogun aaya ati lilo ipawọ apa kokoro lee jẹ ki arun naa jina si eeyan.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Makinde fi da awọn eeyan ipinlẹ naa loju ijọba ti bẹrẹ igbesẹ lati daabo bo wọn lọwọ ajakalẹ arun naa, leyi ti oun tikalara rẹ n dari.
Gomina ọhun pari ọrọ rẹ nipa fifi nọmba wọyin lede 08038210122, 08023229267, 08073431342.
O si rọ awọn eeyan lati pe eyikeyi ninu awọn nọmba naa ti wọn ba n ri apẹrẹ run naa bii, iba, inu riru, ẹfọri lile, iṣoro lati mi ati bẹbẹ lọ lara wọn tabi lara ẹnikẹni to ba sun mọ wọn.













