Coronavirus: Ìjọba àpapọ̀ fi Austria, Sweden kún àwọn orílẹ̀èdè mẹ́tàlá tí kò lè wọ Nàìjíríà

Agolo ayẹwo ẹjẹ fun Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba orilẹede Naijiria ti fi orukọ orilẹede Sweden ati Austria kun awọn orilẹede mẹtala miran ti wọn se ilẹkun ati wọ orilẹede Naijiria mọ.

Minisita feto ilera, Dokita Osagie Ehanire lo kede awọn orilẹede meji ti wọn fi kun iye awọn orilẹede to wa nilẹ tẹlẹ.

Ni ọjọru ni ijsba apapọ kede pe ko ni si aye fun awọn arinrinajo lati orilẹede mẹtala kan lati wọ orilẹede Naijiria.

Awọn orilẹede mẹtala naa ni wọn ṣakiyesi pe ọwọja itankalẹ arun coronavirus pọju si lagbaye.

Awọn orilẹede ti ọrọ kan ni China, Iran, South Korea, Germany, Italy, Amẹrika, Ilẹ Gẹẹsi, Switzerland, Norway, Netherlands, Spain, France ati Japan.

Ni bayii ti orilẹede Austria ati Sweden ti kun un, a jẹ wi pe iye orilẹede ti Naijiria ti se ilẹkun rẹ mọ bayii ti di marundinlogun.