Nigeria: Afunrasí ẹ̀sùn jìbìtì ló ni iléeṣẹ́ tó ń ṣe ìwé àṣẹ wọléwọ̀de ní Nàìjíríà

ìwé àṣẹ wọléwọ̀de ní Nàìjíríà

Iwadii ajumọṣe laarin BBC ati iwe iroyin Premium Times ti fihan pe ẹni to ni ileeṣẹ ti ijọba apapọ lorilẹede Naijiria gbe kalẹ si idi iṣakoso titẹ iwe aṣẹ irinna wọle sorilẹede Naijira lati orilẹede gbogbo lagbaye n jẹ ẹjọ lori ẹsun ikowojẹ ati gbigbọna ẹburu ko owo lọ soke okun.

Ko si ẹri pe ileeṣẹ to n mojuto titẹ iwe aṣẹ iwọle sorilẹede Naijiria naa ni ẹsun iwa ibajẹ kankan tabi boya ẹsun ti wọn fi kan ẹni to nii ni ohunkohun lati ṣe pẹlu iṣẹ iwe aṣẹ irinna ti wọn gbe le wọn lọwọ.

Ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ lorilẹede Naijiria, EFCC gbe Mahmood Ahmadu ati ileeṣẹ rẹ tẹlẹ, Drexel Tech lọ si ile ẹjọ lori ẹsun gbigbọna ẹburu ko owo lọ soke okun.

Ninu awọn mẹta miran to n baa jẹjọ la ti ri minisita fọrọ abẹle tẹlẹ, Abba Moro ti wọn js n jẹjọ liluni ni jibiti ati titẹ ofin kọngila ọja rira fun ijọba loju mọlẹ.

Gbogbo awọn ti wọn n foju ba ile ẹjọ lori ọrọ naa titi kan Ọgbẹni Moro ati Ahmadu ni wọn sọ fun ile ẹjọ pe awọn ko jẹbi ẹsun naa.

Eeyan iyi ni Ọgbẹni Ahmadu lorilẹede Naijiria, koda ijọba fi ọkan lara awọn ami ẹyẹ to ga ju nilẹ naa daa lọla lasiko iṣejọba aarẹ Goodluck Jonathan lọdun 2014.

Awọn agbejọro rẹ sọ pe ko si igba kankan ti ajọ EFCC tabi awọn alasẹ miran ni Naijiria tabi ibomiran sọ pe awọn n wa a.

Awọn eniyan tẹ ara wọn pa ni Papa isere

Ṣugbọn iwe ti ajọ EFCC fi pe e l'ẹjọ fi ẹsun kan Ọgbẹni Ahmadu, ati awọn miran pe, wọn seto igbani sisẹ to yọri si iku awọn ọmọ Naijiria.

Ileesẹ Ọgbẹni Ahmadu nigba kan, Drexel Tech, ni wọn gbe isẹ fun ni ọdun 2013, lati seto ilana igbani sisẹ fun ẹgbẹrun mẹrin eniyan, fun awọn ipo to ṣófo nileesẹ ajọ to n risi iwọle-wode ni Naijiria.

papa iṣire kan atawọn to n waṣẹni inu rẹ

Oríṣun àwòrán, AFP

Ṣugbọn ajọ naa pada sọ pe ko si eto igbani sisẹ kankan.

Lapapọ, ẹgbẹrun lọna ọrinlelẹgbẹta din mẹrin ati ọrinlelẹgbẹta din maarun (676,675) awọn ọmọ Naijiria lo forúkọ silẹ fun eto igbani sisẹ naa.

Ẹni kọọkan wọn si san ẹgbẹrun kan Naira lati fi orukọ silẹ.

Nigba ti wọn da ọjọ idanwo, ogunlọgọ eniyan lo kú lasiko ti wọn tẹ ara a wọn pa nitori ọpọ eero to wa ni papa isere ilu Abuja, nibi ti idanwo naa ti ileesẹ ìjọba fun ọrọ abẹle seto.

"Eto igbani sisẹ naa ya mi l'ẹnu, nitori mi o mọ nipa rẹ", ni ohun ti Ọga Agba ajọ Immigration nigba naa, David Paradang, pada sọ fun ile ẹjọ giga ti jọba àpapọ̀ nilu Abuja.

'O fara pamọ nilẹ Yuroopu'

Ajọ EFCC ti sọ pe Ọgbẹni Ahmadu, iwe ìpéjọ salaye pe o ti ṣa lọ, ati awọn ti wọn jọ fi ẹsun kan, pa ẹgbẹrun lọna ọrinlelẹgbẹta din mẹta milionu (677m) Naira lara eto igbani sisẹ naa.

Iwe ìpéjọ naa pada sọ pe Ọgbẹni Ahmadu ati ileesẹ Drexel Tech Nigeria Ltd, ná lara owo naa lati ra dukia ni ilu Abuja. Ti wọn si tun ṣẹ ọgọrun milionu Naira sì Dọla, fun lilo Ọgbẹni Ahmadu ati ileesẹ naa.

Nigba ti awọn olujẹjo yooku, to fi mọ Ọgbẹni Moro, yọnda ara wọn fun iwadii, ti wọn si ti n jẹ jọ bayii, ajọ EFCC sọ pe Ọgbẹni Ahmadu ko yọju lati sọrọ l'ori ipa to ko ninu eto igbani sisẹ naa.

Iwe iraja

Lọdun 2016, agbenusọ ajọ EFCC nigba naa, Wilson Uwajaren, sọ fun iwe iroyin The Nation pe: "O seese ki a kọwe pe ọlọpaa

ilẹ okeere ati awọn ajọ miran lati tọ pinpin Mahmood Ahmadu. O ni ileesẹ nigba kan nilẹ Gẹẹsi, ti ko si si ibi to le sapamọ si nitori awọn akọsilẹ nipa rẹ lori ayarabiasa.

A ti fi orukọ rẹ silẹ gẹgẹ bii ẹni ti a n wa."

Ni ọsẹ to kọja, agbenusọ ajọ EFCC lọwọ-lọwọ, Tony Orilade, sọ fun BBC pe ẹjọ si wa nilẹ fun Ọgbẹni Ahmadu lati jẹ.

"Iwe ìpéjọ sọ pe o ti ṣa lọ. Bakan naa ni ajọ EFCC si n sọ pe : owo to wọle lati ara igbani sisẹ naa ko ba ofin mú...

" Ajọ EFCC mọ pe ilẹ Yuroopu lo fi ara pamọ si. A ko i ti i ri lati igba ti a ti pe ẹjọ. "

Ileesẹ Ọgbẹni Ahmadu to maa n ṣe eto iwe irinna, Online Integrated Solutions (IOS), sọ loju opo ayelujara rẹ pe oun ṣe asoju ijọba orile-ede Naijiria ni ilu nla mẹẹdọgbọn jakejado agbaye ni Nigeria, China, Lebanon, UAE,

Malaysia, Italy, Netherlands, South Africa, USA, France, Germany, UK, India, ati Canada.

Ileesẹ naa maa n sapejuwe ara rẹ gẹgẹ bi "akọṣẹmọṣẹ ninu ka bani seto iwe irinna ati pasipọọti ilẹ okeere ni Naijiria", pẹlu ajọsepọ awọn ileesẹ aṣoju orilẹ-ede l'agbaye, lati seto irinna silẹ okeere lai mu inira dani rara.

Ọpọlọpọ miliọnu Dọla si ni ileesẹ naa n pa lọdọdun.

Ileesẹ BBC gbiyanju ni ọpọlọpọ igba lati ba ileesẹ ijọba Naijiria to wa fun ọrọ abẹle, ati ileesẹ aṣoju Naijiria nilu London sọrọ, wọn ko fi esi kankan ránsẹ.

Bakan naa ni BBC kan si ileesẹ ilẹ ọrọ abẹle ati eyi to wa fun ọrọ ilẹ okeere nilẹ Gẹẹsi, awọn naa ko setan lati sọ ohunkohun l'ori ọrọ naa .

Ileesẹ ilẹ Gẹẹsi to wa fun ọrọ okowo, amusagbara ati dida ileesẹ silẹ, sọ pe "ọmọ orilẹ-ede miran ti wọn fi ẹsun kan ni ilẹ okeere si lanfaani lati da ileesẹ silẹ nilẹ Gẹẹsi, ni wọn igba ti ko ba ti i si iwe lati fi ofin gbe e.