Adeleke: Iléẹjọ́ dá Sẹ́nétọ̀ Adeleke sílẹ̀ lórí ẹ̀sùn màgòmágó ìdánwò tí wọn fi kàn án

Sẹnetọ Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Facebook/SEN Ademola Adeleke

Ile ẹjọ giga ijọba apapọ niluu Abuja ti dajọ pe oludije gomina fẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Oṣun, Ademola Adeleke ko jẹbi ẹsun magomago lasiko idanwo ti wọn kan an.

Adajọ Inyang Ekwo to dajọ ọhun lọjọ Ẹti lo paṣẹ wi pe ki Sẹnetọ Adeleke maa lọ lalaafia.

Simon Lough tii ṣe agbẹjọro awọn olupẹjọ sọ fun adajọ Ekwo l'Ọjọbọ pe awọn olupẹjọ fẹ ki ẹjọ naa wa sopin nitori bi Adeleke ko ṣe maa yọju nigba kugba ti igbẹjọ ba n lọ lọwọ.

Adeleke ko tii yọju sile ẹjọ lati ọjọ kẹfa oṣu karun un ti ileẹjọ ti fun un laye lati rinrin ajo lọ si orilẹede Amẹrika fun itọju ara rẹ.

Ọga ileewe girama Ojo-Aro ti Adeleke ti ṣedanwo, Sikiru Adeleke, Alhaji Aregbesola Muftau to jẹ akọwe ileewe naa ati olukọ kan nibẹ Dare Samuel Olutope, gbogbo wọn lọ nileẹjọ pe awọn o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn.

Agbẹjọro Adeleke. Alex Izinyon (SAN), naa ko tako aba lati wọgile ẹjọ ti wọn pe onibara rẹ.

Ohun ti agbẹjọro agba naa sọ fun adajọ ni pe ko paṣẹ idasilẹ oludije ibo gomina Oṣun, Ademola Adeleke.