Sleeping Lawmakers: Àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin l'Abuja ti wọ́n ń sùn lásìkò ìjókòó ilé

Àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ asolfin to lo n sún lasiko ijoko ile

Oríṣun àwòrán, Others

Ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà ló n gba ọ̀rọ̀ náà bi ẹni gba igbá ọti láti ìgbà ti adájọ́ àgbà ilé ẹjọ́ FCT Ishaq Bello ti ni ojú má a ń gbà òun ti nígbà ti òun bá ri ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣofin (kékeré tabi àgbà ) tó bá ń sùn lásìkò ìjókó ilé.

Bello ní ó ṣe pàtàkì ki àwọn ọmọ ọ̀dọ́ ayé òde òní gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ láti mú àyípadà rere bá orílẹ̀-èdè yìí.

Eyí lo fàá ti BBC Yorùbá ṣe n ṣe àkójọ pọ̀ àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin tó ti ń sùn lásìkò ìjòkó ilé.

Ọ̀pọ̀ ló mi ìgbàgbọ́ pé àwọn asojú ilé ìgbìmọ̀ asoin yiìí kan ń lọ síbẹ̀ láti ná owó ìlú ni kò sí ǹkan pàtó tí wọ́n n ṣe níbẹ̀ ju oorun lọ

Ọmọ ilé ìgbìmọ̀ asoju sòfin míràn rèé to ti sùn fọ́nfọ́n lásìkò ìjọkó ilé

Oríṣun àwòrán, Others

Rochas Okorocha bẹ̀rẹ́ iṣẹ́ nile ìgbìmọ̀ asofin kò tii ju oṣù mẹ́ta lọ to ti bẹ̀rl iṣk oorun sísùn

Oríṣun àwòrán, Others

Rochas Okorocha bẹ̀rẹ́ iṣẹ́ nile ìgbìmọ̀ asofin kò tii ju oṣù mẹ́ta lọ tó ti bẹ̀rl iṣẹ́ oorun sìsùn

Yoruba bọ̀ wọ́n ni kò si ẹni tó le yan ẹran ara jẹ́, asiko to ba ti ni ki ènìyàn sinmi, o dí dandan ki oluwa rẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀

Oríṣun àwòrán, Others

Yoruba bọ̀ wọ́n ni kò si ẹni tó le yan ẹran ara jẹ́, asiko to ba ti ni ki ènìyàn sinmi, o dí dandan ki oluwa rẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀

Iṣẹ́ ẹni ni náà ni iṣẹ́ ẹni.

Oríṣun àwòrán, Others

Ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ọmọ Naijiria ti maa n gbarata lórí bi àwọn ọmọ ilé igbímọ̀ aṣofin àgbà ṣe ma sùn lásìkò ìjòkó ilé.

Wọ́n ní ọ̀ps wọ́n lo ti sọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà di ilé ìfẹ̀yìnti àti ìfọ̀kànbálẹ̀.

Àwọn ọmọ Naijiria ni, èyí n wáye nítori pé Naijira ni ibi ti gbogbo ńkan ti le ṣẹlẹ̀ láìsì ǹkan ti yóò tẹ̀yì rẹ̀ jáde.