Osusan Oluwatobi tricycle accident: Ààrin ìṣẹ́jú kan tí mo wọ 'Maruwa' ni ìjàmbá tó gbá ẹsẹ̀ mi wáyé

Oluwatobi Osusan

"Ko to iṣẹju kan ti mo wọ kẹẹkẹ Marwa, ni mo deede gbọ ariwo ti awọn eeyan n pa lati doola ẹmi mi."

Eyi ni ọrọ ti Arabinrin Osusan Oluwatobi ti ori ko yọ ninu ijamba kẹẹkẹ, bo tilẹ jẹ pe ẹsẹ rẹ kan.

O ni ariwo obinrin oloyun yii ti lọ ti awọn eeyan n pariwo lo ta oun ji, ti ọpọlọpọ eeyan si n gbiyanju lati fa ẹsẹ rẹ yọ kuro ni abẹ 'Maruwa' to ha si.

O ṣalaye pe oun ti pinnu lati dẹkun ọmọ bibi, ṣaaju ki o to loyun eyi ti ijamba ka mọ lara.

O ni ijamba naa waye ni ọjọ mẹta ṣaaju ọjọ ibi rẹ, lasiko ti oun n jade.

"Bi mo sẹ de ibudokọ, mo ba Maruwa yẹn, ṣugbọn ko ti to iṣẹju kan ti mo wọ inu rẹ, ti mo fi gbọ 'gba!'.

"Ọkọ kan lo gba kẹkẹ ti mo wa ninu rẹ lati ẹyin, ti a si fi ori sọ ọkọ akolẹ-ko idọti PSP to n bọ niwaju.

Bi a ṣe ko si abẹ rẹ niyẹn. Gbogbo awọn ti a jọ wa ninu rẹ lo fi ara pa, ṣugbọn emi nikan ni temi buruju pẹlu ẹsẹ mi to ha si abẹ Maruwa."

Àkọlé fídíò, 'Ìgbà tí mo máa fi lajú sáyé padà, ọ̀fọ̀ ikú mi ní wọ́n ń kígbe'

Kii ṣe ẹsẹ nikan ni Oluwatobi fi pa, ẹnu rẹ paapa là.

To si jẹ pe ọpẹlọpẹ awọn eeyan to sugbaa rẹ, lati yọ ọ jade ni abẹ Maruwa, lo fi tete di eero ileewosan.

Ni ileewosan ni wọn ti sọ fun pe, iṣẹ abẹ ni wọn o ṣe si ẹsẹ naa, nitori pe o kan kọja bo ṣe yẹ lọ.

I ba jẹ pe wọn le ṣe iṣẹ abẹ naa lasiko naa, ọrọ i ba dun. Ṣugbọn, awọn olutọju alaisan sọ pe wọn ko ni i le ṣe e , nitori oyun to wa ninu rẹ.

Ironu dori agba kodo wayii.

Wọn fun Oluwatobi ni ọna abayọ meji: ikinni ni pe ko fi ọwọ si iwe pe ki wọn o yọ oyun inu rẹ, ki wọn le ṣe iṣẹ abẹ fun ẹsẹ.

Ikeji ni pe ko fi ẹsẹ naa silẹ bẹẹ, ko san fun'ra rẹ, bo tilẹ jẹ pe, yoo pẹ ẹ ko to o san.

"Wọn sọ fun mi pe iṣẹ abẹ ni ọrọ ẹsẹ mi gba a. Ati pe mo ni anfanni lati duro ki n fi bimọ, to si jẹ pe oṣu mẹfa lẹyin ti mo ba bimọ tan ni wọn to o le ṣe e, ki ọmọ mi le mu ọyan diẹ."

"Ṣe ki n ma parọ, ẹmi mi kọkọ lọ, nitori pe irora kekere kọ ni mo n jẹ lati ọjọ ijamba naa.

"Bẹẹ ni wọn o le fun mi ni oogun ara riro to le din irora mi ku, nitori ọmọ to wa ninu mi."

Koda, o ni oun n bẹbẹ fun oogun orun, ṣugbọn oyun inu rẹ ko faaye gba lilo iru oogun bẹ ẹ.

Àkọlé fídíò, Wo àwọn ìbejì tó lẹ́ pọ̀ lẹ́yìn àṣeyọrí ìṣẹ́ abẹ dókìtà 70

Nigba to n gbe ọrọ Oluwatobi lẹyin, ọkọ rẹ, Adebambo Osunsan, sọ pe ọrọ aye kọkọ su oun lọjọ naa, pe iru ki leyi.

"Kii ṣe ọrọ owo lo tiẹ kọkọ fa ironu, bi koṣe pe nkan ti mi o ro tẹlẹ, ṣẹlẹ.

O ni kii ṣe iriri to rọrun fun oun lati ma a tọju iyawo to wa nileewosan, ati awọn ọmọ meji to wa nile, ti oun naa si gbọdọ lọ si ibi'ṣẹ oun.

Pẹlu igi ni ẹsẹ ni Oluwatobi rin irin ajo rẹ lasiko to wa ninu oyun, titi to fi bimọ pẹlu iṣẹ abẹ.

Àkọlé fídíò, 'Inu mi bàjẹ́ nígbà tí mo bí i, odidi oṣù mẹ́ta, mi ò lè gbàdúrà s'Ọ́lọ́run'

O ṣalaye pe, awọn to gbẹbi ọmọ naa sọ pe ko kè é, bẹẹni ko mí.

"Igba ti mo laju saye lẹyin iṣẹ abẹ naa, ọmọ mi ni mo kọkọ n beere.

Wọn sọ fun mi pe o wa nibi ti wọn ti n tọju rẹ, amọ nigba ti mi o ri i fun ọjọ meji, ẹru tun n ba mi pe laduru gbogbo nkan ti mo ti la kọja."

"Lootọ, wọn n fi aworan rẹ han mi, amọ ko tẹmilọrun."

Ọjọ mẹjọ ni ọmọ tuntun naa fi gba itọju nileewosan, ki ara rẹ to ya.

Arabinrin Oluwatobi sọ pe adura ki oun o ma jẹbi gbogbo irọju oun ni oun n gba, ki wahala o ma ja si asan.

O ni idunnu pe oun ri ọmọ oun gbe jo, fi oun lọkan balẹ pe oun yoo dide rin ni ọjọ kan.