Àjọ NIDCOM rọ àwọn òbí láti má ran ọmọ lọ kàwé ni Northern Cyprus mọ́

Àjọ NIDCOM ti rọ àwọn òbí láti maa ran ọmọ lọ kàwé ni Northern Cyprus mọ́

Oríṣun àwòrán, Abike Dabiri/Instagram

Àjọ to n ri sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè, ti rọ àwọn òbí ni Naijiria láti yé ran àwọn ọmọ wọn láti lọ kàwé ni Àríwá Cyprus mọ́ nítóri ìkú àìnídìí ti àwọn ọmọ Nàìjíríà ń kú níbẹ̀.

Àlága àti olùdari àjọ náà àrábìnrin Abike Dabiri-Erewa, ló fi ìkìlọ̀ yìí síta pé ó jẹ ǹkan tó ni èwu gidigidi ní àsìkò yìí láti máa ran àwọn ọmọ láti lọ kàwé ni àgbègbè ọhun.

Ó ní ogúnlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ni wọ́n ti pa ni àwọn ilé iwé tí ẹnikẹni ko si mọ́ ìdí ikú to pa wọ́n àti pé, kò si ìwádìí kan to kẹ́sẹ jári nínú àwọn tó ti kú.

Dabiri-Erewa sàlàyá ọ̀rọ̀ yìí lásìkò ti adájọ́ Aminu Bello, ìyá Ibrahim Khaleel ti wọ́n pa láì nidìí lórílẹ̀-èdè náà kọ́wọ́rín sàbẹ̀wò si ọfíísì rẹ̀.

Ó ni ikú Khaleel, tó jẹ́ ọmọ ipele kẹta nínú ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ lo jẹ́ èyí tó burú jùlọ to ti wáyé lórílẹ̀-èdè náà.

Àdari NIDCOM to ka àwọn orúkọ bíi mẹ́ẹ̀dógún nińú èèyàn bi ẹgbẹ̀rún kan ti wọ́n ti pa ní Ariwa Cyprus, àti pé o sọ pe o níra láti ṣe ìwádìí gẹ́gẹ́ bi orílẹ̀-èdè nítorí Turkey níkan lo ri gẹ́gẹ́ bi orilẹ̀-èdè.

"Ikú Khaleel lo yẹ kó jẹ́ àṣemọ láti dẹ́kun pípa àwọn ọmọ wa níbikíbi lágbàyé pàápàá jùlọ ni Ariwa Cyprus."

"kìí ṣe Ibrahim nìkan, Kennedy Dede ẹni ọdun mejidinlọgbọn Augustine Ngok, Gabriel Sorewei, Osabanjo Owoyale, Augustine Wallace, Stanley Eteno, Hassan Babatunde, Temitayo Adigun, àti Kubat Abraham jẹ́ díẹ̀ ti a le dárúkọ."

Àkọlé fídíò, 'Ìgbà tí mo máa fi lajú sáyé padà, ọ̀fọ̀ ikú mi ní wọ́n ń kígbe'

"Orílẹ̀-èdè náà kìí ṣe eyí ti àjọ iṣọkan agbáyé rí gẹ́gẹ́ bi orílẹ̀-èdè, kò sì sí orílẹ̀-èdè to rí Ariwa Cyprus bi orilẹ̀-èdè to dá dúró."

Abike Dabiri fi kún pé ni kété ti àjàkálẹ̀ ààrùn Covid-19 bá ti kásẹ̀ nílẹ, ìjọba yóò ṣe àbẹ̀wò si ibẹ̀ láti le mọ bi ǹkan ṣe ń lọ.