Economic recession: Ìjọba ní àfàìmọ̀ kí ọrọ̀ ajé má tún dẹnu kọlẹ̀ fún ìgbà kejì láàrin ọdún mẹ́rin

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Others

Lai si eto itaniji to muna doko, afaimọ ki ọrọ aje orilẹede Naijiria maa tun dẹnu kọlẹ fun igba keji laarin ọdun mẹrin, ijọba apapọ lo ke gbajare bẹẹ.

Minisita keji fun eto iṣuna ni Naijiria, Ọgbẹni Clem Agba lo sọrọ yii niwaju igbimọ ile aṣofin agba to n ri si ọrọ eto inawo ati ọrọ aje l'Abuja.

Minisita ni oṣuwọn idagbasoke ọrọ aje ni Naijiria laarin oṣu mẹta to kọja, GDP ko wu ni lori rara.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọgbẹni Agba ṣalaye pe ti ọrọ aje orilẹede yii ko pa gbe pẹẹli diẹ sii ni oṣu mẹta si asiko yii, o ni ewu n bẹ loko longẹ fun ọrọ aje Naijiria.

Nigba to n sọrọ lori bi pasipaarọ owo dọla ṣe n ṣakoba fun ọrọ aje Naijiria, minisita ni banki apapọ Naijiria, CBN gbe owo dọla kan to wa ni ọta le lọdunrun un (N360) naira tẹlẹ lọ si ọrin le lọdunrun un o din kan(N379).

Àkọlé fídíò, Rape cases in Nigeria: Ọmọ ọdun 5 àti 14 ni Kalu wà nígbà tí obìnrin fipá ba lòpọ̀

Minisita Agba ni ohun to n ṣẹlẹ si ọrọ aje agbaye lọwọlọwọ yoo jẹ ki owo to n ba ọja wọle si Naijiria gberu sii.

Ọgbẹni Agba ni lootọọ ni awọn eto iṣede ti ijọba ṣe lori ati dẹkun ajakalẹ aarun covid-19 dara, amọ o ti ṣakoba nla fun ọrọ aje Naijiria.

O ni lati ibẹrẹ oṣu kinni si ipari oṣu ọdun 2020, owo to din diẹ ni tiriliọnu meji(N1.81tn) lo wọle si apo ijọba, eyi ti ko ju ida mejidinlaadọrin ninu ida ọgọrun un ti ijọba n reti lọ.

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Instagram/Bashir Ahmad

Minisita keji fun eto iṣuna ṣalaye pe ijọba ṣe ifilọlẹ eto lati mu owo wọle sii nigba didan inawo ijọba ku.

Iṣé nlá n bẹ̀ níwájú ààrẹ Buhari àti àwọn Gómìnà lórí owó èpo robi tó dénú kọ́lẹ̀

Oju ọjọ lẹka ọrọ aje ni Naijiria ṣe bi ẹni ṣokunkun latari bi iye owo epo rọbi lagbaye ti ṣe dẹnu kọlẹ.

Eyi ko ṣẹyin ija ọrọ aje to n waye laarin orileede Russia ati Saudi to fi mọ airi ọja epo ta ti aisan corona virus naa ṣokunfa rẹ.

Bi nkan ti ṣe ri bayi ti banki apapọ orileede Naijiria ti ni kawọn eeyan ma mura kalẹ de igba ti yoo le diẹ, BBC Yoruba fọrọwa awọn onimọ nipa ọrọ aje lẹnu lati ṣalaye ohun ti awọn ọmọ Naijiria yoo ba pade.

Ijakulẹ ọrọ aje Naijiria di dandan

Onimọ nipa eto ọrọ aje ọmọwe Chijioke Ekechukwu ni iru nkan bayi ko ṣẹṣẹ ma ṣẹlẹ.

Aarẹ Buhari tẹwọ adura pẹlu awọn ọmọ igbimọ isejọba apapọ nibi ipade wọn

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad

Àkọlé àwòrán, Adura ko ran ọrọ to wa nilẹyi bi kii ṣe ki atunto eto ọrọ aje waye

O ni gbogbo igba ti nkan ba ti deba owo epo rọbi lagbaye yala owo rẹ lọ si oke tabi o walẹ, o di dandan ki Naijiria mọ lara.

Latari iṣẹlẹ eyi ti o mu iye owo epo rọbi walẹ di bi ọgbọn dọla lati ọgọta dọla Ọmọwe Chijioke sọ pe ijakulẹ ọrọ aje eleyi ti a mọ si Recession lede oyinbo di dandan

Iduro ko si mọ fawọn to n ṣe ijọba bayi

Ẹlẹẹkeji ipa to ni adinku iye owo epo yi yoo ni lara awọn eeyan Naijiria ni pe iye owo gbogbo nkan lọja yoo gbowo lori.

''Ati ẹni to n ta ata lọja ati awọn ti ko ni nkan ṣe pẹlu dọla,gbogbo wọn ni yoo gbe owo ọja lọ soke.''

Pẹlu iru nkan bayi, anfaani wa bẹẹ si ni ipenija wa ṣugbọn gbogbo rẹ ku si ọwọ awọn to n ṣe ijọba.

Dollar bills

Oríṣun àwòrán, Thinkstock

Fun idi eyi onimọ Chijioke ni asiko re ti aarẹ Naijiria ati awọn Gomina ni lati ṣan ṣokoto wọn daada ki wọn si mu adinku ba owo inakuna.

Rẹgi ni ọrọ r ṣe pẹlu ọjọgbọn Nazif Abdullahi Darma to ni iIpenija nla ni ọrọ to wa nilẹ yi nitori abaṣepọ to wa laarin ọrọ aje ati ilera kii ṣe kekere.

Darma ni asiko re lati ṣe agbeyẹwo awọn afojusun Naijiria nipa iṣuna ọdun 2020.

Eniyan to nka owo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Idajọ ileẹjọ lee mu ekuru gba ẹyin ni ifanfa fun ajọ EFCC

Bakanna o ni agbeyẹwo iye ti a man gbe le owo iṣẹ amayedẹrun ni Naijiria ti wa di dandan bayi.

''A ko le ma darukọ owo gọboi pe a fẹ fi ṣe isẹ agbaṣe.Nibo la ti fẹ ri bayi ti owo dọla ti dẹnu kọ ilẹ?''

''O ti di dandan lati se agbeyewo ibasepọ laarin awọn ọlọdani ati ẹka ijọba ti a mọ si PPP''

Arinrinajo lọ si ilẹ okere fun ẹkọ tabi ilera yoo mọ asiko yi lara

Ninu awọn ti Ọjọgbọn Nazifi Abdullahi Darma sọ pe yoo mọ asiko yi lara ju ni awọb ti wọn ma n na owo dọla yala lati fi gba itọju nilẹ okere ni tabi fẹkọ ni oke okun.

O ṣalaye pe bi eeyan ba ni dọla bayi, ki o ṣọra lati naa.Bi anfaani ba si wa fun lati yanju nkan to n wa lọ si ilẹ okere, ki o yara yanju rẹ nile lai lọ si ita.