Man city lulẹ̀, Pep Gardiola, Ten Hag jiyàn lórí ‘Offside’ Rashford tó mú góòlù tó sọ Man Utd jí jáde

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United gbo ewuro soju Manchester city pẹlu goolu meji si ẹyọkan ni ifẹsẹwọnsẹ wọn to waye ni papa iṣire Old Trafford lọjọ Satide.
Ọpọ lamẹtọ ere bọọlu lo n ṣe ariyanjiyan pe ‘offside’ ni Rashford agbabọọlu Manchester United wa to si di awọn agbabọọlu ati aṣọle Manchester city lọwọ ki Bruno Fernades to gba bọọlu wọle sinu awọn nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ ọgọrin iṣẹju.
'Rashford di awọn agbabọọlu wa lọwọ'

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ninu ọrọ to sọ pẹlawọn akọroyin lẹyin ifẹsẹwọnsẹ naa, akọnimọọgba ikọ agbabọọlu Manchester city, Pep Guardiola ṣalaye fun BBC pe ko si wahala bi ik Manchester city ko ba gba Carabao cup tabi premier league ni saa bọọlu yii, ṣugbọn ifẹsẹwọnsẹ ṣi pọ lati gba nitori naa orun to wa loke ṣi to aṣọ n sa.
“Offside ni Marcus Rashford wa, Bruno Fernandes ko si ni offside. Rashford di aṣọle wa ati awọn agbabọọlu wa lọwọ. Amọ ko si nnkan ti a le ṣe sii. A mọ bi papa iṣire ti a ti gba ifẹsẹwọnsẹ yii ṣe ri. Bakan naa lo ṣoro fun awọn alamojuto ere bọọlu ati ṣe iṣẹ wọn lawọn papa iṣire wọnyii.”
Ofin ti sọ pe Rashford ko di ẹnikẹni lọwọ, emi gan rii nibi ti mo wa - Ten Hag

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Amọṣa akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Manchester faake kọri pe ọrọ ko ri bi akọnimọgba Manchester City atawọn kan ṣe n sọ ọ.
Ten Hag ni oun rii daadaa ni ibi ti oun wa.
“Ofin sọ pe Marcus ko fara kan bọọlu ko si di ẹnikẹni lọwọ. Bruno si wa lati ẹyin – mo lee ri lati ibi ti mo wa.”








