Burundi president: Wo àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Pierre Nkurunziza, ààrẹ orílẹ̀-èdè Burundi tó dolóògbé

Late Burundi president
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Pierre Nkurunziza ni Aarẹ ti idibo wọle rẹ fun saa kẹta da fa ki n fa a silẹ. O fẹrẹẹ to ọdun mẹwaa to ti jẹ aarẹ orilẹede Burundi.

Laarin igboro lawọn ilu nla nla, awọn alatako oloogbe Nkurunziza ẹni ọdun mọkanlelaadọta ni afi la, ko gbudọ lọ fun saa kẹta tori pe o lodi si ofin.

Ni idakeji ẹwẹ, awọn alatilẹyin tirẹ ni o jare tori ile aṣofin lo kọkọ yan an sipo lọdun 2005 kii ṣe awọn oludibo gẹgẹ bi ile ẹjọ Burundi ṣe sọ ọ.

Adari awọn agbẹsan ni Nkurunziza jẹ tẹlẹ, o ni idunu si bi o ṣe ti mu alafia de ba Burundi to si nkọ orilẹede to jẹ ọkan lara awọn ti ko lọrọ lagbaye.

Iroyin kan tilẹ sọ wi pe wọn gbe awọn akọṣẹmọṣẹ kan to wa ba Nkurunziza ṣepade lọ si igberiko lati igboro ti wọn si ba aarẹ t n kọ ebe pẹlu awọn agbẹ ilu Bujumbura.

Iwọde ti waye ri ni olu ilu orilẹede naa lodi si saa kẹta ti Nkurunziza n ja fun.

Bakan naa, iwa irẹlẹ arakunrin yii kọja sisọ pẹlu bo ṣe maa n ba awọn ara abule jẹ̀ lawọn ilu igberiko to ti maa n lo akoko rẹ ju.

Iwa yii ti sọ ọ di mọlumọka lawọ abule ṣugbọn ko ri bẹẹ nigboro nibi ti ọpọlọpọ awọn alatako rẹ n gbe.

Onigbagbọ Ododo ati Kristẹni

Ṣaaju ogun abẹle, Ọgbẹni Nkurunziza lẹyin to kẹkọọ gboye ninu imọ ikọni ere idaraya, o ṣe iṣẹ olukọni ni fasiti Burundi.

O tun ṣe akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu awọn ologun Muzinga ati ti Union Sporting nibẹrẹ 1990s.

Baba rẹ, gomina tẹlẹri ti wọn pa lọdun 1972 jẹ ọmọ ijọ Katoliki ti iya rẹ si jẹ ọmọ ijọ Angilika. Ọmọ marun un ni Nkurunziza funrarẹ bi.

Nibayii to ti di atunbi Kristẹni, ko le rinrinajo lai ko ikọ agbabọọlu tara rẹ, Hallaluya FC ati ẹgbẹ akọrin rẹ dani fun anfani gbigbabọọlu pẹlu awọn agbẹbọọlu igberiko ati ṣiṣe ipolongo ihinrere pẹlu eto adura gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin AFP ṣe sọ ọ.

Àkọlé fídíò, Say no to rape: Àwọn òṣèré tíátà Yorùbá pariwo síta lórí wàhálà ìfipábánilòpọ̀

Koda iroyin ti sọ ọ ri pe oun ati iyawo ti wẹ ẹsẹ awọn eeyan laarin ero pupọ ri eyi si jẹ ki awọn eniyan nigbagbọ ninu rẹ.

Aarẹ Nkurunziza gbagbọ pe atọrun wa ni ipo aarẹ oun o si n fi eyi ṣe atọna igbe aye rẹ ati iṣejọba rẹ. Eyi ni agbẹnusọ rẹ Willy Nyamitwe sọ.

Wọn fi ẹsun ijọba ẹni ti ko fẹ gbe agbara silẹ kan an nigba to fẹ gbe igba saa kẹta.

Àkọlé fídíò, Ibadan Murder: Oyún oṣù méje ló ń bẹ nínú Azeezat, kí wọ́n tó f'òkúta fọ́ ọ lórí

Ọgbẹni Nkurunziza mori bọ lọwọ igbiyanju awọn kan lati pa a ninu oṣu karun eyi ti ologun kan fẹ fi gba ijọba lọwọ rẹ. Ṣe ni awọn ọmọ ogun tirẹ ba iṣẹ naa jẹ.

Idajọ iku

Ọpọlọpọ igba ni wọn gbiyanju lati pa a, igba mii loju popo ti ẹmi awọn mii lọ si i.

Lẹyin rẹ, ile ẹjọ Burundi kan dajọ iku fun aarẹ Nkurunziza lọdun 1998 ṣugbọn o tun gba idalare eyi to mu ki ija dopin.

Ẹwẹ nigba ti ọlọjọ yan lati wa mu u, aarẹ Nkurunziza jẹ Ọlọrun nipe lọjọ kẹsan oṣu kẹfa ọdun 2020.

Àkọlé fídíò, #JusticeforTina: Àwọn obi Tina Ezekwe ń bèrè fún ìdájọ́ òdodo pẹ̀lú omijé lójú

Pierre Nkurunziza, Ààrẹ orilẹede Burundi ti jáde láyé lẹ̀ni ọdún 55

Aarẹ orilẹede Burundi, Pierre Nkurunziza

Aarẹ orilẹede Burundi, Pierre Nkurunziza ti jade laye.

Aisan ọkan ni iroyin ti a gbọ ṣọ pe o gbẹmi rẹ.

Ijọba orilẹede Burundi fi iroyin iku aarẹ naa sita loju opo twitter rẹ.

Wọn ni ni ọjọ Aje ni aarẹ Nkurunziza jade laye.

Ọdun marundinlọgọta ni aarẹ Nkurunziza ko to jade laye.

Ọjọ Abamẹta ni wọn gbe e lọ si ileewosan Karusi ẹyin to n wo idije ere idaraya kan nitosi ile rẹ.

Àkọlé fídíò, Say no to rape: Àwọn òṣèré tíátà Yorùbá pariwo síta lórí wàhálà ìfipábánilòpọ̀

Ijọba orilẹede naa ti wa kede eto idaro ọlọjọ meje, bẹrẹ lati ọjọ Iṣẹgun jakejado orilẹ€de naa ni iranti rẹ.

Lati ọdun 2005 ni Pierre Nkurunziza ti di aarẹ orilẹede Burundi, o si n mura lati fa aṣẹ ipo aarẹ le ẹni ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan sipo aarẹ nibẹ, Evariste Ndayinshimiye ni ogunjọ oṣu kẹjọ ọdun 2020.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ni ọjọ kejidinlogun oṣu kejila ọdun 1963 ni wọn bi aarẹ Burundi tẹlẹ to jade laye, Pierre Nkurunziza.

Ọdun 2005 lo gori aleefa gẹgẹ bi aarẹ ilẹ Burundi, ipo aarẹ yii naa lo si dimu titi to fi jade laye.

Pierre Nkurunziza

Oríṣun àwòrán, others

Lọdun 2015 ni ẹgbẹ rẹ tun fa a kalẹ lati dije fun ipo aarẹ fun saa kẹta eleyi ti ọpọ awọn ẹgbẹ alatako koro oju si.

Awọn ẹgbẹ alatako ni o lodi si ofin ilẹ naa fun ẹnikẹni lati lọ fun saa kẹta ni orilẹede naa.

Wọn ditẹ lati gbajọba rẹ lọdun lọjọ kẹtala oṣu karun un ọdun 2015 nigba ko si nile.