PTECSSAN vs MTN: Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ń gbáradì láti gbéná wojú MTN, lórí bó ṣe ń ṣe àwọn òṣiṣẹ́ rẹ̀ ní Naijiria

MTN

Oríṣun àwòrán, others

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ labẹ asia Private Telecommunications and Communications Staff Association of Nigeria, PTECSSAN, ti sọ pe wọn yoo da iṣẹ ileeṣẹ MTN ru nitori bi ileeṣẹ ọhun ṣe n ṣe awọn oṣiṣẹ rẹ ni Naijiria.

Bo tilẹ jẹ pe ko ṣalaye bi wọn yoo ṣe da iṣẹ MTN ru, akọwe apapọ ẹgbẹ ọhun, Okonu Abdulahi sọ fun BBC pe, wọn yoo gbena woju ileeṣẹ naa ti gbendeke ti wọn da a ba ti to.

Abdulahi ni awọn ọmọ ẹgbẹ PTECSSAN wa kaakiri ninu ileeṣẹ MTN, nitori naa, yoo rọrun lati da sẹria fun MTN.

Abdullahi tẹpẹlẹ mọọ fun BBC pe PTECSSAN ti kọ lẹta ranṣẹ si MTN lọpọ igba ṣugbọn niṣe ni ileeṣẹ ọhun kọti ọgbọnin si gbogbo ibeere wọn.

Abdulahi ṣalaye pe oriṣiriṣi ọgbọnin arekereke ni MTN maa n da lati yọri bọrọ ninu gbogbo ipade ti wọn ba pe e si.

O ni "A tilẹ ti kọ iwe si ọga agba patapata MTN lori ọrọ yii ni igba meji ọtọọtọ, nitori gbogbo awọn to maa n ran si wa sọ pe wọn ko lagbara lati yanju iṣoro ti a n lọgun rẹ, ṣugbọn ko si iyatọ kankan ti a ri."

"Nigba miran ti a ba pe wọn si ipade, wọn le má yọju si wa fun nnkan bi odidi oṣu kan, eyii n sọ iru ọga to jẹ ati iru ọwọ to fi mu awọn oṣiṣẹ rẹ.

Abdulahi pari ọrọ rẹ pe PTECSSAN yoo gbe igbesẹ lati gbena woju MTN ni ọjọ Kẹrinlelogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2020, ayafi to ba ṣe gbogbo ohun ti wọn a fẹ.

Lara ẹsun ti PTECSSAN fi kan MTN ni bo ṣe maa n di ẹru iṣẹ wuwo le awọn oṣiṣẹ rẹ lori, bi kii ṣe n fun awọn to ba da duro lẹnu iṣẹ ni owo gba mabinu, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Àkọlé fídíò, Alaafin: Olori Aanu Adeyemi ṣàlàyé ìdí tó ṣe gẹ́ Oba Lamidi Adeyemi ti ìlú Oyo

Kini oṣiṣẹ MTN sọ fun BBC?

Ẹwẹ, ọkan lara awọn oṣiṣẹ MTN to ba BBC sọrọ ni ootọ ni pe iṣe n pa wọn lara.

Ọkunrin ọhun ti ko fẹ ki BBC darukọ rẹ sọ pe ti ileeṣẹ naa ba fẹ da eeyan duro lọpọ igba, yoo sọ fun wọn pe ki wọn funra wọn kọwe fi iṣẹ silẹ ni.

O ni eyii jẹ ọna alumọkọrọyi ti MTN n lo lati ṣalai san owo gba mabinu to yẹ ki ileeṣẹ san fun ẹnikẹni ti wọn ba fẹ daduro.

Ki iru ẹni bẹẹ ma le ri owo fi bẹrẹ ohun ọtun laye rẹ ti ko ba ni ajẹṣẹku tẹlẹ.

Àkọlé fídíò, Sextuplet: Àdúrà Ìbùkún ló kú lẹ́yìn ọmọ mẹ́fà yìí- Ifeoma Thelma àti Onyemaechi Chiaka

Oṣiṣẹ naa sọ pe MTN n gbiyanju nipa fifun awọn oṣiṣẹ rẹ lowo oṣu deede atawọn ajẹmọnu miran, ṣugbọn o ni o yẹ ki ileeṣẹ ọhun ṣe ju bo ṣe n ṣe lọ, paapaa nipa ti iye wakati ti awọn fi n ṣe iṣẹ ati iye owo to n san fun awọn.

BBC Yoruba gbiyanju pupọ lati ba aṣoju MTN sọrọ, ṣugbọn pabo ni gbogbo akitiyan rẹ ja si.

Àkọlé fídíò, Teach your children Yoruba: Wo àwọn òyìnbó tó ń kẹ́kọ̀ọ́ èdè Yorùbá ní Michigan, America