Colin Powell: COVID-19 mú ẹ̀mí Mínísítà f'ọrọ ilẹ́ ókéré tẹlẹ l'Amerika lọ́

Aworan Powell ni ibẹrẹ ọdun yi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọgbẹni Powell jẹ olubadamọran pataki si awọn eekan oloṣelu kan lorileede Amẹrika.

Minisista fọrọ ilẹ okere nigba kan ri lorileede Amẹrika Collin Powell ti jade laye.

Gẹgẹ bi ikede taa ri gbọ lẹnu mọlẹbi rẹ, aarun Covid-19 lo ṣokunfa iku rẹ lẹni ọdun mẹ́rinlelọgọrin.

Nigba aye rẹ, oun ni alawọdudu akọkọ ti yoo jẹ ipo yi labẹ ijọba aarẹ tẹlẹ George W Bush.

O figba kan jẹ ọmọ ologun ni Amẹrika bakan naa.

''A ti padanu baba oninu're,baba baba ati ọmọ ilẹ ilẹ Amẹrika to lamilaaka.'' ni nkan ti wọn fi sita ninu atẹjade .

''A fẹ dupẹ lọwọ awọn oṣiṣẹ ilera fun itọju ti wọn ṣe fun un''

Atẹjade naa tun sọ pe gbogbo abẹrẹ Covid-19 lo ti gba pe.

Ọgbẹni Powell jẹ olubadamọran pataki si awọn eekan oloṣelu kan lorileede Amẹrika.

Lasiko ogun Vietnam, o kopa nibẹ to si farapa,iriri yi ran lọwọ pupọ nigba ti oun naa bẹrẹ si ni gbe ilana kalẹ nipa iṣẹ ologun ati lagbo oṣelu.