Hike in cooking gas price: Àlàyé rèé lórí ohun tó ń fa ẹ̀kúnwó gegele lórí owó orí afẹ́fẹ́ ìdáná gáàsì

Oríṣun àwòrán, other
Lọwọlọwọ yii, gbogbo ọmọ Naijiria paapaa julọ awọn to n lo afẹfẹ idana gaasi ni wọn n pariwo bayii pe owo gegele ti afẹfẹ idana naa gbe lori bayii ti fẹ gbẹmi awọn. Amọṣa o awọn alaṣẹ ipese afẹfẹ idana gaasi lorilẹede Naijiria ti ṣalaye sita ohun to ṣokunfa owo gegere to gun ori afẹfẹ idana naa bayii.
Farouk Ahmed to jẹ alaṣẹ agba ileeṣẹ to n ṣe ṣakoso awọn ileeṣẹ ati lajọlajọ lẹka epo rọbi lorilẹede Naijiria, NPRA ti ṣalaye pe aisi idokoowo to kuna lẹka ipese afẹfẹ gaasi lorilẹede Naijiria, LPG lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin lo n faa.
- Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ UI méjì fórí kó ọta ìbọn lọ́jọ́ kan ṣoṣo, wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn lọ́jọ́ kan náà
- Ìdí tí Ooni Ogunwusi fi gbé ọmọ rẹ̀ obìnrin tó ṣe ọjọ́ ìbí 28 sáyé àti bó ṣe tọ́ ọ dàgbà
- ₦500 tí màá fi ra 'Data' láti fí ṣé Yahoo-yahoo ló mú mí yín ọlọ́kadà lọrùn pa
- Ìgbìmọ̀ tí ìjọba ìpínlẹ̀ Eko gbé kalẹ̀ lórí #ENDSARS ti parí ìṣẹ́, àbọ̀ rèé
Ahmed ṣalaye siwaju sii pe ajọ naa yoo mu iṣẹ ṣe lori rẹ lati rii daju pe nnkan pada si bo ṣe yẹ. O ni ko yẹ ki Naijiria o maa ni ipenija ẹkunwo owo afẹfẹ idana gaasi nitori bi Eleduwa ṣe fi jinkin orilẹede naa lọpọ yanturu ti kii ba ṣe ailakasi awọn ijọba iṣaaju lori mimu idokoowo to jọju wọ ẹka naa lawọn ọdun to ti lọ.
Ni bi a ṣe n sọrọ yii, owo agolo silinda oniwọn 12.5kg ti wọn n ra ni ẹgbẹrun mẹrin naira (N4000) loṣu kini ọdun 2021 gbera lọ si ẹgbẹrun mẹfa ati igba Naira (N6,200) loṣu keje ọdun 2021, ki o to tun gbera di ẹgbẹrun meje ati ẹẹdẹgbẹrin Naira (N7,800) loṣu kẹsan ọdun 2021 kan naa. Eyi tumọ si ẹkunwo onida mẹtala ninu ọgọrun (13%) lori iye owo ori afẹfẹ idana gaasi.
Ọpọlọpọ awọn oniṣowo ohun elo idana yii atawọn to n raa lo ni wọn ti n kerora lori rẹ bayii.









