Psychiatric Examination: iÌjọba ní kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ni ṣe àyẹ̀wò ọpọlọ f'áwọn Ọlọ́pàá àti agbófinró

Nigeria Police

Oríṣun àwòrán, Twitter/Police

Igbimọ alaṣẹ fun eto ọrọ aje Naijiria ti fẹnuko lẹyin ipade wọn pe ki awọn olori awọn oṣiṣẹ alaabo lorilẹede Naijiria rii daju pe wọn n ṣe ayẹwo ọpọlọ ati ti oogun oloro fun awọn oṣiṣẹ wọn.

Eyi wa lara abajade ipade wọn to waye lọjọ Ẹti eyi ti igbakeji aarẹ, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo dari.

Ninu ọrọ kan ti agbẹnusọ igbakeji aarẹ, Laolu Akande fi sita, o ni wọn gbudọ rii daju pe ilera ọpọlọ awọn eeyan wọn duro deede lati gbe ibọ̀n ati nkan ijagun.

Ipade yii n waye ni ibamu pẹlu bi igbimọ naa ṣe rii pe awọn ọmọ Naijiria n gbero lati ṣe ayajọ iwọde ifẹhonuhan #EndSARS.

Gẹgẹ bi ọkan lara awọn afẹhonuhan ṣe bere lọdun to kọja, igbimọ naa ni ki ijọba boju to alaafia awọn oṣiṣẹ eleto aabo.

"Igbimọ NEC n pe gbogbo awọn adari oṣiṣẹ eleto aabo Naijiria lati rii pe awọn ti wọn ba n gba si iṣẹ eyi ti wọn yoo ti maa gbe ibọn lati ṣe ayẹwo ọpọlọ ati ti oogun oloro".

Àkọlé fídíò, 'Mi ò yàtọ sí Krìstẹni tàbí Mùsùlùmí tóun náà da ẹsìn rẹ pọ mọ jíjẹ Dokita, Babaláwo Dókítà l'èmi'

Lẹyin ti wọn ba gba wọn wọle tan, igbimọ naa tun ni ki wọn maa ṣe ayẹwo ọhun loorekoore lẹnu iṣẹ.

Igbimọ naa rọ ijọba Naijiria lati faaye silẹ fun igbeaye alafia awọn ọlọoaa atawọn oṣiṣẹ alaabo Naijiria.

Ni pato, wọn pe fun ṣiṣe ayẹwo owo oṣu awọn oṣiṣẹfẹyinti to jẹ ọlọpaa ati riri owo awọn to wa lẹnu iṣẹ gba lasiko to yẹ.

Bakan naa ni igbimọ yii tun gba awọn oṣiṣẹ alaabo ni imọran pe ki wọn maa tẹle ofin ti wọn fi gba wọn siṣẹ lasiko ti wọn ba wa lẹnu iṣẹ lagbegbe ibi ti wọn pin wọn si tabi nita.

Àkọlé fídíò, Irú omi àti oúnjẹ tí wọ́n ń fún Sunday Igboho, a ó mọ̀ọ́, à ń fura sí ohun tó ń lọ lọ́wọ́ látìmọ́lé Cotonou

Nigba to n fun 'pe si awọn oṣiṣẹ alaabo lori ọgbọn amulo lati gbogun ti iwa ọdaran, igbimọ naa ni ki awọn ọlọpaa wa ni ibamu pẹlu ohun ti wọn pese latara ikọni abala ofin ileeṣẹ ọlpaa fun dun 2020.

O ni ṣiṣe ikọni ati idanilẹkọ fun awọn ọlọpaa ṣe pataki fun iṣẹ wọn.

Lafikun, igbimọ NEC ni awọn eeyan ti wọn timọle nitori iwọde EndSARS wa ni ibamu pẹlu ofin to de gbigbọra ẹni ye.

O fi kun un pe wọn ni lati rii pe ilana ti wọn fi lelẹ laarin ileeṣẹ Ọlọpaa Naijiria lati maa fi yanju ẹsun ti awọn araalu ba mu wa kun oju osuwọn ki awọn ọlọpaa to ba ti wa lẹnu iṣẹ si maa wọ aṣọ. wọn pẹlu lilẹ orukọ wọn mọ aya.