Ibo Jews: Mọ̀ nípa àwọn ọmọ Naijiria tó fẹ́ kí Ísírẹ́lì tẹ́wọ́ gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà Júù

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Fun ọpọlọpọ ọdun, ni awọn ọmọ Naijiria kan to ko ara wọn jọ ti n pe ara wọn ni ẹ̀yà Júù, sugbọn bi orilẹ-ede Ísírẹ́lì ko ṣe tẹwọ gba wọn jẹ ibanujẹ.
Lara awọn eeyan yii n ko ara jọ ni ọkan lara awọn agbegbe to wa nilu Abuja, Jikwoyi, nibi ti wọn ti n jọsin.
Ni ile ijọsin wọn ti wọn pe ni Gihon Hebrew Synagogue, to tumọ si Sínágọ́gù àwọn Hébérù, ni wọn gbe tabili kan si inu agọ ti wọn fi imọ̀ ọ̀pẹ ṣe, lati fi ṣe ajọyọ Sukkot, to n ṣàpẹẹrẹ iye ọdun ti awọn Júù lo ninu aginjù lasiko ti wọn n lọ si ilẹ ileri.
Olori wọn, Shlomo Ben Yaakov sọ fun akọroyin BBC to bẹ ile ijọsin naa wo lasiko ajọyọ ọhun pe bi awọn ṣe n ṣe lọwọ lọwọ naa ni wọn n ṣe ni Ísírẹ́lì.
O sọ eyi lasiko ti awọn eeyan naa n ṣe àjọpín akara ati waini.
Ẹya Igbo ni Ọgbẹni Yaakov ti wa. Orúkọ abisọ rẹ si ni Nnaemezuo Maduako.
Ọpọlọpọ àwọn eeyan ẹ̀yà Igbo lo gbagbọ pe Júù ni orírun wọn, ati pe awọn jẹ ọkan lara ẹ̀yà Ísírẹ́lì mẹwa to sọnù ni wọn, botilẹjẹ pe kii ṣe gbogbo wọn lo n ṣe ẹsin awọn Júù bí ti Ọgbẹni Yaakov.
Awọn ẹ̀yà yii ni igbagbọ wa pe wọn di awati lẹyin ti wọn ko Ísírẹ́lì lọ si igbekun ni bi ọdun 8th Century.
Àṣà dida abẹ fun ọmọkùnrin, ṣíṣe ọ̀fọ̀ oku fun ọjọ meje, ajọyọ òṣùpá tuntun, ati ṣíṣe igbeyawo ni abẹ àtíbàbà, to wọpọ nilẹ Igbo, jẹ ara nkan to mu wọn gbagbọ pe ẹ̀yà Júù ni wọn.
'Kò sí ẹ̀rí'
Sugbọn Chidi Ugwu, ọmọ ẹya Igbo to tun jẹ onimọ nipa àwọn nkan abalaye ni University of Nigeria, nilu Enugu, sọ pe lẹyin ogun Biafra to waye ni 1967 si 1970 ni ọrọ jíjẹ ẹ̀yà Júù bẹrẹ laarin awọn Igbo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O ni nitori bi awọn eeyan ẹ̀yà Igbo ṣe n ja fun ominira lati kuro ni Naijiria, to si jọ iru awọn ipenija ti awọn ọmọ Ísírẹ́lì ní, lo mu wọn ma a pe ara wọn ni ẹ̀yà Júù, lati ṣe iwuri.
O ni nkan itiju ni lati ma a pe ẹ̀yà Igbo ni ẹ̀yà to sọnù lati ibi kan.
"Free Sunday Igboho" lariwo tó gbóde bí àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ ṣe darapọ̀ mọ́ ìwọ́de ENDSARS ní Ibadan
Bakan naa lo sọ fun BBC pe ayẹwo DNA to waye ni ọpọ ọdun sẹyin lati mọ boya lootọ ni, ko fihan pe wọn tan pẹlu Júù.
Rabbi Eliezer Simcha Weisz, alaga igbimọ to n mojuto àwọn Rabbi (Olukọni) - ajọ to n buwọlu àwọn to ba pe ara wọn ni ẹ̀yà Juu, naa sọ pe ko daju.
"Wọn sọ pe ẹ̀yà Gad ni awọn, ọkàn lara awọn ọmọ Jakọbu - sugbọn wọn o ni ẹ̀rí pe ọmọ Júù ni baba nla wọn."
O tun sọ fun BBC pe kaakiri aye ni awọn eeyan ti n lo awọn àṣà ti wọn n tọ́ka si pe o jẹ ti Júù.
O ni ayaafi ti awọn ọmọ Naijiria to jẹ Juu ba yipada si ẹsin Juu ki awọn to le tẹ́wọ́ gba wọn.
Àmọ́, Ọgbẹni Yaakov sọ pe abuku ni ayipada si ẹsin naa jẹ fun awọn.

















