Shatta Wale: Iléesẹ́ ọlọ́pàá Ghana mú akọrin tàkasúfèé, Shatta Wale wọ́n ní ayédèrú ìròyìn ló ń gbé kiri pé ẹnì kan yinbọn mọ́ òun

Oríṣun àwòrán, Twitter/ shattawalegh
Ileesẹ ọlọpaa orilẹ-ede Ghana ti mu akọrin takasufe, Shatta Wale, lori ìbọn to ni awọn kan yin mọ oun.
Eyi waye lẹyin wakati mẹrinlelogun ti iroyin jade pe eeyan kan yinbọn mọ.
Bakan naa ni awọn ọlọpaa mu afurasi meji, nitori pe wọn pín ayederu iroyin kaakiri pe eeyan kan yinbọn mọ Shatta Wale.
Ileesẹ ọlọpaa sọ pe iwadii awọn fihan pe ẹnikẹni ko yinbọn mọ Wale.
Awọn meji ti wọn mu ni Kojo Owusu Koranteng (Nana Dope) ati Eric Venator (Gangee), fun pe wọn fi ayederu iroyin naa da ìpayà ati ẹ̀rù silẹ niluu.
Alẹ́ ọjọ Aje ni iroyin jade pe ẹnikan yinbọn mọ Shatta Wale.
Koda, diẹ lara awọn ọmọ ikọ rẹ fi idi iroyin naa mulẹ loju opo ayelujara wọn.
Lẹyin wakati diẹ si ni Wale fúnra rẹ sọ pe irọ ni iroyin naa.









