Eton tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ akẹ́kọ̀ọ́ Nàíjíríà lórí ìwà ẹlẹ́yàmẹ̀yà

Dilibe Onyeama, adulawọ akọkọ to pari iwe rẹ nile ẹkọ Eton,

Oríṣun àwòrán, Dilibe Onyeama

Olukọ agba Ile ẹkọ girama olokiki nii, Eton College to wa nilẹ Gẹẹsi, ti sọ fun BBC pe, ọkan ohun bajẹ pẹlu bi akẹkọọ alawọdudu to kọkọ pari ẹ́kọ rẹ nibẹ, Dilibe Onyeama, se koju idẹyẹsi ati iwa ẹlẹyamẹya nigba to n kẹkọ nibẹ.

Dilibe Onyeama, tii se ilumọọka onkọwe lorilẹede yii, tun jẹ ẹgbọn Minisita fọrọ ilẹ okeere nil wa bayii, Geofrey Onyeama.

Ile ẹkọ Eton si ni Dilibe ti gba iwe ẹri girama jade lọdun 1969.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Dilibe Onyeama si lo kọ iwe kan nipa iwa ẹlẹyamẹya ti oju rẹ ri nileewe naa ati bi ti ile ẹkọ naa ko se gba a laaye lati pada wa sibẹ mọ.

Olukọ agba ile ẹkọ Eton, Simon Henderson ni awọn ti gbe igbesẹ lati dẹkun iru iwa yi sugbọn o ni oun gba pe lootọ ''isẹ si ku tawọn yoo se''

Ogbẹni Henderson tọrọ aforijin yii gẹgẹ bi idahun si ọrọ ti BBC beere lọwọ rẹ, nipa apilẹkọ kan ti akọroyin Adaobi Tricia Nwaubani kọ, lori nnkan ti oju Onyeama ri lori iwa ẹlẹyamẹya ati nipa iwọde Black Lives Matter to n ja rain.

Eton College: Awọn ọhun to yẹ ni mimọ:

Itan nipa ile ẹkọ Eton

Orisun: Eton College ati BBC

Olukọ agba ile ẹkọ naa sọ pe oun yoo fiwe pe Onyeama lati le tọrọ aforijin lọdọ rẹ "ki oun si jẹ ko mọ pe ko si igba ti ko le pada wa si ile ẹkọ Eton''

"Gbogbo wa la gbọdọ sọrọ sita, ki a si mọkan pe a fẹ se daada - mo setan lati samulo anfaani asiko yii lati fi sokunfa iyipada tootọ, tọkan-tọkan''

Ki wa ni Onyeama sọ?

Dillibe Onyeama

Oríṣun àwòrán, Dillibe Onyeama

Onyeama sọ fun BBC pe, ko si wahala kankan ati pe isẹlẹ naa ko mu iyipada si bi oun ti se n foju rere wo ile ẹkọ Eton.

O wa fi kun ọrọ rẹ pe, bi wọn ti se tọrọ aforijin yii ''jẹ ki o di mimọ pe idẹyẹsi eeyan yala nitori awọ ẹni naa tabi ẹya rẹ a maa tẹmbẹlu eeyan, ju orisi iwa abuku miran lọ''

O ti saaju sọ fun BBC pe, ojojumọ lawọn akẹẹgbẹ oun maa n fi oun se yẹyẹ.

Wọn a ma bi ni awọn ibeere pe 'Ki lo de ti o fi dudu?' 'Idin meloo lo wa ninu irun rẹ?' ati pe 'Se iya rẹ a ma fi eegun bọ inu imu rẹ?'

Koda wọn fẹsun kan pe o se magomago ninu idanwo:

Igba kigba ti Onyeama ko ba se daada ninu ẹkọ rẹ tabi lagbo idaraya, wọn a ma sọ pe nitori to jẹ alawọdudu lo fa ti ko fi se daada.

Nigba ti o jawe olubori ninu idanwo asekagba, o jẹ iyalẹnu fun gbogbo ile ẹkọ naa.

Wọn bẹrẹ si ni sọ pe''N gbọ na, bawo ni o se se?''

Onyeama ninu iwe rẹ to kọ, sọ pe ''Wọn bi mi pe, se kii se pe o se magomago ninu idanwo?''

Lẹyin to pari ẹkọ rẹ nibẹ, gbogbo ohun to sẹlẹ yii ni Onyeama kọ sinu itan iriri aye rẹ to kọ.

Lọdun 1972, ile ẹkọ naa kọwe si pe, awọn ko fẹ ja pẹtẹ ẹsẹ rẹ nileewe awọn mọ.

Gbogbo aforijin ti olukọ agba to wa nibẹ nisinsin yii n se, ko sẹyin bi awọn ileesẹ nlanla nilẹ Gẹẹsi bii Lloyd's of London ati Greene King, ti se n tọrọ aforijin pe ọwọ awọn ko mọ ninu sise owo ẹru.

Iwọde 'Black Lives Matter' to n mi igboro titi, lo mu ki gbogbo wọn ma tọrọ aforijin lọdọ awọn alawọdudu.

Lọdun 1440 ni Ọba Henry VI da ileẹkọ Eton silẹ, ti o si di ilumọọka nitori iru ẹkọ to ye kooro ti wọn n kọ awọn akẹkọọ nibẹ.

Lọwọlọwọ bayi, awọn akẹkọọ ile ẹkọ naa n san owo to to ẹgbẹrun lọna aadọta dọla lọdun kan.