Gbogbo àwọn tí kò nílé la ti lé kúrò ní PDP - Makinde sọ̀kò ọ̀rọ̀

Gómìnà Seyi Makinde wọ aṣọ èsúrú, jòkòó lórí àga ó ká ọwọ́ sórí tábìlì, ó ń wo ọ̀ọ́kán

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti sọ pé kò sí àwọn tó máa ń fi ẹsẹ̀ gbalẹ̀ kiri, tí kò nílé mọ́ lẹ́gbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP.

Makinde sọ èyí níbi ètò ṣíṣí ilé ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tó wáyé ní ìlú Ibadan lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹta, oṣù Kejì, ọdún 2026.

Ó sọ pé ní ọdún 2015 ni àwọn ọmọ alè tó wà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP dàgbà, tí wọ́n sì lo ọdún mẹ́wàá nínú ẹgbẹ́ kí àwọn tó le wọn kúrò lọ́dún 2025.

"Ní oṣù Kọkànlá, ọdún 2025 ni a lé wọn kúrò ní PDP. Fún ìdí èyí kò sí àwọn tó ń fẹsẹ̀ gbálẹ̀ ní PDP mọ́."

Gẹ́gẹ́ bí gómìnà náà ṣe sọ, ó ní PDP pàdánù ipò ààrẹ Nàìjíríà lọ́dún 2015 nítorí ìfaǹfà tó ń wáyé láàárín àwọn adarí ẹgb òṣèlú PDP nígbà náà.

Ó ní èyí ló ṣokùnfà táwọn tó ń fẹsl gbálẹ̀ náà ṣe rí ààyè láti di ẹgbẹ́ náà mú lásìkò náà.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Seyi Makinde kò dárúkọ ẹnikẹ́ni nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ìgbàgbọ́ wà pé Mínísítà fọ́rọ̀ ìlú Abuja, Nyesom Wike nil ó ń báwí.

Èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí ní ọjọ́ Ajé ni Nyesom Wike níbi ìpàdé ẹgbẹ́ òṣèlú PDP kan sọ pé òun fẹ́ tojú bọ ètò ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ìpínlẹ̀ Oyo.

Ọ̀rọ̀ yìí ni ọ̀pọ̀ gbà pé Makinde ń fèsì sí pàápàá bí ó ṣe sọ pé ọ̀rọ̀ tí ẹnìkan sọ pé òun fẹ́ tojú bọ ètò ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ìpínlẹ̀ Oyo jẹ́ ohun tó panilẹ́rìn-ín nítorí báwo ló ṣe ẹgbẹ́ rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Rivers.

"Èèyàn kan sọ pé òun fẹ́ dá sí ọ̀rọ̀ PDP ní Oyo, ẹ jẹ́ ká bèèrè pé kí ló ti ṣe ní Rivers", Makinde sọ nínú fídíò kan tó gba orí ayélujára.

Láti bíi oṣù díẹ̀ sẹ́yìn báyìí ni ẹnu ti ń kun Makinde àti Wike lórí ìfaǹfà tó ń wáyé láàárín wọn pàápàá lẹ́yìn bí wọ́n ṣe lẹ̀ papọ̀ lásìkò ètò ìdìbò gbogbogbò lọ́dún 2015 níbi tí wọ́n ti lòdì sí olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú wọn.