Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Ron Kenoly tó di olóògbé

Aworan Ron Kenoly

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Olorin ẹmi, ọmọ orilẹede Amẹrika, Ron Kenoly ti jade laye ni ẹni ọdun mọkanlelọgọrin. Oloogbe yii ni o fi orin ẹmi gba ọkan ọpọ eeyan ni ọna ijọsin kaakiri agbaye.

Ron Kenoly jade laye ni ọjọ keji Oṣu keji ọdun 2026, ti ọpọ ọmọ lẹyin Kristi lagbaye si ti n ṣe idaro rẹ pe eeyan Ọlọrun ti jade laye.

Ikede iku oloogbe ni wọn gbe soju opo ayelujare Instagram oludari orin Bruno Miranda ṣugbọn wọn ko kede ohun to sokunfa iku oloogbe.

Nigba to n sapejuwe oloogbe, Bruno Miranda, ni ohun iwuri lo jẹ lati ba oloogbe siṣẹ papọ fun ogoji ọdun, to si jẹ pe o mu gẹgẹ bii ọmọ dipo oludari orin.

"Baba yii mu mi gẹgẹ bii ọmọ, akẹkọọ, ti mo si ni anfani lati fi oju ri isẹ Ọlọrun ninu igbesi aye rẹ.

"Olorin ẹsin ni Doc, yoo lo gbogbo akoko rẹ lati ṣalaye nnkan fun wa, to si n mu awọn eeyan tọ ilana Ọlọrun."

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Ronald Kenneth Kenoly ni wọn bi si ilu Coffeyville, Kansas, ni ọjọ kẹfa oṣu Kejila ọdun 1944. O bẹrẹ orin kikọ pẹlu abala orin R&B, ko to di pe o yi awọ pada si to si bẹrẹ orin ẹmi ni ọdun 1980.

O kọkọ bẹrẹ irinajo rẹ ni ile ijọsin Jubilee Christian Center ni San Jose, ti eyi ti gba si aye, to si bẹrẹ si ni gbe awo orin sita, eyi to ṣe aṣeyọri kaakiri agbaye.

Lara awọn orin ti oloogbe gbe sita to di ilumọka ni

  • "Joy to the World" (wait, no, praise staples like "Use Me," "Heal Their Land," "Welcome Home."
  • "Jesus Is Alive," "Lift Him Up" (breakthrough 1992 album)
  • "Hallowed Be Your Name," "We're Going Up to the High Places"
  • "We Offer Praises," "It Is Good," "Joshua Generation"

Ron Kenoly fi iyawo silẹ laaye Tavita Kenoly, ẹni to pade lasiko to waye ni Air Force service, ti wọn si lo ọdun mejilelogoji papọ gẹgẹ bii tọkọtaye, ti wọn si bi ọmọ mẹta, Samuel, Ronald, ati Tony.

Ọpọ awọn olusọ aguntan kaakiri agbaye lo ti bẹrẹ si ni ọrọ ibanikẹdun ransi awọn mọlẹbi oloogbe.

Agba Bisọọbu lorilẹede Naijiria, Bisọọbu Wale Oke, bo soju opo ayelujara lati ba awọn mọlẹbi kẹdun, to si gba laadura pe ki Ọlọrun ọba duro ti wọn lasiko yii.