Àwọn òṣìṣẹ́ fẹ̀yìntì ìpínlẹ̀ Ọyọ fi ẹṣin funfun ta Gómìnà Makinde lọ́rẹ

Àwọn èrò tó pọ̀ níbi tí àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì ti ń fi ẹṣin funfun ta gómìnà Seyi Makinde lọ́rẹ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ẹgbẹ awọn Oṣiṣẹ fẹyinti orilẹ-ede Naijiria (NUP) ẹka ti ipinlẹ Oyo ti fun Gomina Seyi Makinde ni ẹṣin funfun gẹgẹ bi ọna lati mọriri rẹ fun inu rere ati bi o ṣe n tọju awọn ọmọ ẹgbẹ wọn.

‎‎Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ feyinti eyi ti akọwe wọn, Olusegun Abatan ko sodi lọ gbe ẹṣin funfun ọhun fun Gomina Seyi Makinde lorukọ awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ ni sekiteriati ijọba Ipinlẹ Oyo to wa ni agbegbe Agodi níbi eto adura apapọ ti ijọba Ipinlẹ Ọyọ gbe kalẹ.

‎‎Abatan ṣalaye wi pe ẹgbẹ naa pinnu lati fun Gomina Seyi Makinde ni ẹṣin funfun nitori awọn itumo to rọ mo ẹṣin naa paapaa julọ pẹlu bíi ẹṣin naa ṣe tumọ si alaafia, iṣọkan, iwa itẹlọrun ati ibeere tuntun.

‎‎O sọ pe ti ẹgbẹ oṣiṣẹ ba bẹrẹ si ni kọ nipa awọn isẹ ribiribi ti Gomina Seyi Makinde ti ṣe fun awọn oṣiṣẹ fẹyinti paapaa julọ pẹlu bí igbesoke ti ba owo awọn oṣiṣẹ fẹyinti nipinlẹ Ọyọ ati bi Gomina Seyi Makinde ṣe n san owo ajemonu awọn oṣiṣẹ fẹyinti loju ọjọ atawọn ajẹẹlẹ owo oṣiṣẹ fẹyinti eyi ti ijọba to lọ ko san.

‎‎Abatan tun rọ Makinde lati na ọwọ si awọn oṣiṣẹfeyinti tọ fẹyinti ni awọn ile ẹkọ giga to wa ni Ipinlẹ Ọyọ ati awọn to fẹyinti ni ẹka ijọba ibilẹ.

Àwọn èrò tó pọ̀ níbi tí àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì ti ń fi ẹṣin funfun ta gómìnà Seyi Makinde lọ́rẹ

‎‎Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Ọyọ tó yẹ ni yóò gba igbega - Makinde

‎‎Ninu ọrọ rẹ, Gomina Ṣeyi Makinde kan saara sawọn ẹgbẹ oṣiṣẹ fẹyinti NUP fun ẹbun naa to si fi dawọn loju wi pe ohun yoo lọ ẹṣin naa lọna to tọ.

‎‎Gomina Makinde ṣeleri lati mu awọn oṣiṣẹ Ipinlẹ Oyo ninudun, o fi kun wi pe olori oṣiṣẹ ijọba ibilẹ jakejado ipinlẹ Ọyọ lo ti jẹ anfaani ẹkunwo owo oṣu lati inu oṣu Kiini ọdun 2025.

‎O ṣeleri lati san gbogbo ajẹmanu awọn oṣiṣẹ ki oṣu Kiini ọdun 2026 to pari, to si tun ṣalaye pe gbogbo awọn oṣiṣẹ to yẹ fun igbega lẹnu isẹ ìjọba ni òun yoo buwọlu.

‎‎Ijọba ipinlẹ Oyo ninu atẹjade ti wọn fi lede ninu oṣu Kẹrin ọdun 2025 ni Ipinlẹ Ọyọ lo n san owo ju fun awọn oṣiṣẹ fẹyinti lorile-ede Naijiria pẹlu bi Ipinlẹ Oyo ṣe n san ọgọta millionu naira fun awọn oṣiṣẹ fẹyinti to le ni 22,212.