Ìyàwó mẹ́wàá ni bàbá mi fẹ́, mó fẹ́ kọ ìyàwó mi sílẹ̀ báyìí kí n lè fẹ́ ìyàwó púpọ̀ - Kunle Afolayan

Oríṣun àwòrán, Kunle Afolayan/X
Gbajugbaja onkọtan ati olootu ere ori itage n ni, Kunle Afolayan, ti sọ pe oun fẹ fun iyawo oun ni iwe ikọsilẹ koun le lanfaani lati fẹ iyawo to pọ.
Afolayan wa rọ ọpọ ọkunrin wi pe ki wọn fẹ ju iyawo kan lọ.
Nigba to n sọrọ lori fiimu rẹ to ṣẹṣẹ jade, 'Anikulapo,' Afolayan ṣalaye pe oun fẹ gbe igbesẹ yii tori lati idile oniyawo pupọ loun ti wa.
Ninu fidio kan to ti lu ori ayelujara pa bayii ni ọnkọtan naa ti sọ pe ''mo ti n lọ sile ẹjọ lati igba de igba lori ati fun iyawo mi ni iwe ikọsilẹ.
Mi o kọ iye owo to le na mi, mo ṣetan lati fẹ iyawo pupọ,'' Ọgbẹni Afolayah lo sọ bẹẹ.
Kunle sọ pe nitori pe baba oun jẹ oniyawo pupọ lo jẹ koun lawọn aṣeyọri toun ni lonii.
''Lai si baba mi, ko ba ti si nnkan ti a n pe ni ileeṣẹ oṣere KAP Village tabi Kunle Afolayan lonii.
Ipo keje ni mo wa ninu awọn ọmọ ti baba mi bi, nitori o fẹ iyawo pupọ.
Iyawo mẹwaa ni baba mi ni, o si bi ọmọ mẹẹdọgbọn.
Ẹyin ọkunrin, o san ki ẹ fẹ ọpọlọpọ iyawo ju ki ẹ maa gbe ọpọ obinrin lọ.
Idi ni pe ka ni baba mi ko fẹ iyawo pupọ ni, ko ba ti bi mi saye.
Otitọ to wa nibẹ niyẹn, awa ọmọ si n ṣe igbelarugẹ ogun ti baba wa fi silẹ bo tilẹ jẹ pe baba wa ti ku.
Ile aye yii ko pẹ lọ titi, gbogbo wa la si maa ku, a ni lati lo akoko ti a ni daadaa,'' Kunle ṣalaye.
Ọpọ eeyan lo ti n sọrọ lori imọran ti Kunle Afolayan fawọn ọkunrin yii.
Nnkan to ya ọpọ lẹnu ni pe Kunle ti sọ ṣaaju ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe lọdun 2021 pe kawọn ọkun ma fẹ ju iyawo kan lọ.
Nigba naa lo sọ pe oun ko ni tẹle ọna baba oun to ni iyawo pupọ tori awọn ipenija to wa ninu ki eeyan fẹ iyawo to pọ.
Afọlayan sọ ninu ifọrọwanolẹnuwo naa wi pe ko si ifarakinra ati ibaṣepọ to dan mọran laarin gbogbo ọmọ baba oun nitori iyatọ aṣa ati ede awọn.
O ni oun mọ pe iyawọ pupọ ti baba oun fẹ ni ko jẹ ki o le gbajumọ iṣẹ rẹ daadaa.



























