Àwọn ajínigbé yọ̀nda àwọn mẹ́rin tí wọ́n jígbé ní Kwara

Eni ti wọn ji gbe to n gba itọju nile iwosan
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn ajinigbe to ji eeyan mẹrin gbe lopopona Isanlu Isin si Omu-aran ipinlẹ Kwara ti pada yọnda awọn mẹrin naa.

Awọn ajinigbe yọnda awọn eeyan naa lẹyin ti wọn gba ọkada mẹta ati owo ọgbọn milionu náírà lọwọ mọlẹbi awọn eeyan naa.

Ọkan lara awọn mọlẹbi awọn ti wọn ji gbe ọgbẹni Yinka Ọmọniyi sọ fun BBC News Yoruba pe lootọ ni wọn ti yọnda awọn mẹrin naa, ti wọn si ti darapọ mọ awọn ẹbi wọn.

O ṣalaye pe ọjọru, ọjọ Kọkanla, oṣu Keji ni awọn ajinigbe naa yọnda awọn mẹrin naa ni nnkan bii aago meji ọsan.

O sọ pe awọn ti wọn yọnda naa ti n gba itọju lọwọ ni ile iwosan ti ko darukọ ni ilu Ilọrin ati Omu Aran ni ipinlẹ Kwara.

O fi kun pe awọn ajinigbe naa gba ọkada Bajaj tuntun mẹta ati ọgbọn milionu naira ko to dipe wọn tu awọn ti wọn jigbe naa silẹ.

Omoniyi kọminu pe ko i tii si awọn ọmọ ogun ni ilu naa bayii lati tọ inu igbo lọ ba awọn agbeṣumọmi naa nitori wọn ṣi tun ji eeyan kan gbe lọjọ Aje ọjọ Kẹsan-an, ti wọn si tun ṣekupa ẹlomiran.

O woye pe ko si ẹnikẹni to le lọ soko lagbegbe naa mọ bayii nitori ibẹru bojo iṣẹlẹ ijinigbe lagbegbe naa.

O fi kun pe lati ọjọ Karun-un, oṣu Kiini ọdun yii ni wọn ti ji awọn eeyan naa gbe lopopona Isanlu Isin si ìlú Omu-aran nipinlẹ Kwara.

Lasiko ti oun naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ Kansilọ to n ṣoju wọọdu ilu Isanlu Isin ni ijọba ibilẹ Isin, Emmanuel Akolapo naa sọ pe lootọ ni awọn ti wọn jigbe naa ti gba itusilẹ.

Ọkan lara awọn ti wọn tu silẹ ti orukọ rẹ n jẹ Samson Abegunde ni olori awọn ọdọ lẹgbẹ oṣelu APC ni ilu Isanlu Isin.

Titi ti a fi ko n iroyin yii jọ, agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Adetoun Ejire-Adeyemi ko fesi si ibeere wa lori iṣẹlẹ naa.

Ki lo ṣẹlẹ sẹyin?

Ọjọ Karun-un oṣu Kiini ọdun yii ni wọn ji awọn eeyan naa gbe lopopona Isanlu Isin si ìlú Omu-aran nipinlẹ Kwara.

Awọn eeyan naa ni wọn n lọ lati ilu Omu-aran si Isanlu Isin ti wọn si ṣe kongẹ awọn ajinigbe lọna.

Ori Ọkada ni wọn wa lasiko tawọn ajinigbe ji wọn gbe lai gbe ọkada wọn lọ.

Ọmọ bibi ilu Isanlu Isin ni ijọba ibilẹ Isin Ipinlẹ Kwara lawọn mẹrẹrin

Lati igba naa lawọn ajinigbe ti n pe mọlẹbi wọn lori ẹrọ ibanisọrọ pe ki wọn mu owo ọgọrun-un kan million naira wa.

Lẹyin ogoji ọjọ lọdọ awọn ajinigbe, awọn ajinigbe tu wọn silẹ lẹyin ti wọn gba owo itusilẹ ọgbọn millionu naira ati Ọkada tuntun mẹta.