Electoral Act Amendment Bill: Èdèàìyedè láàrín Ààrẹ Buhari àtàwọn aṣòfin àpapọ̀ lórí òfin ìdìbò ní Nàìjíríà

Aworan Buhari, Lawan ati Gbajabiamila

Oríṣun àwòrán, facebook

Kikọjalẹ ti aarẹ Muhammadu Buhari kọ lati buwọlu abadofin eto idibo tuntun ti awọn aṣofin apapọ gbe ka iwaju rẹ ti di eyi to n fa ọpọlọpọ awuyewuye lagbo oṣelu Naijiria bayii.

Ni ọjọ kọkandinlogun oṣu kọkanla ni awọn aṣofin apapọ gbe abadofin tuntun naa ka iwaju aarẹ ki o to di pe aarẹ sun un wọ eyi ti ko wulẹ lee si aye fun ifọwọsi rẹ mọ labẹ ofin.

Amọsa, olori ile aṣojuṣofin Họnọ̀rebu Fẹmi Gbajabiamila ti ṣalaye fun awọn ọmọ Naijiria pe loṣu kinni, ọdun 2022 lawọn aṣofin apapọ yoo to jiroro lori ohun ti wọn ba fẹ ṣe lori abadofin eto idibo tuntun ti aarẹ taare danu.

Họnọrebu Gbajabiamila ṣalaye yii lasiko to fi n ka ọrọ apilẹkọ rẹ lẹyin to ka iwe ti Aarẹ Buhari kọ si wọn lori idi ti oun ko fi lee buwọlu abadofin naa.

Àkọlé fídíò, Wa ko iṣẹ ọwọ nipa lilo ede Yoruba

Aarẹ Buhari ni idi pataki ti oun ko fi ni le buwọlu abadofin naa ni iye owo ti yoo na orilẹede Naijiria.

Gbajabiamila ni awọn ko lee tori pe aarẹ ko buwlu aba naa ki wọn wa kuku da oju gbogbo rẹ kọ igbo.

Aarẹ Mohammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, BUHARISALLAU1/INSTAGRAM

Igbesẹ wo lo wa nilẹ bayii?

Oniruuru ipe lo ti n lọ sọdọ awọn aṣofin apapọ pe ki wọn lo agbara nla ti iwe ofin Naijiria tdun 1999 fun wọn lati fi da oju igbesẹ aarẹ naa bolẹ ki wọn si fi ontẹ lu abadofin naa lati di ofin.

Àkọlé fídíò, 8kyti,j

Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ alatako ni ile aṣofin agba, Sẹnetọ George Sekibo ti ẹgbẹ oṣelu PDP sọ pe ko din ni awọn aṣofin mẹtalelaadọrin ti wọn ti buwọlu iwe ti wọn n gbe kiri lati wọgile igbesẹ Aarẹ Buhari lori abadofin naa.

Àkọlé fídíò, Odindi ọjọ́ kan ni mo fi wà ní ìhòhò ní Libya tí gbogbo èrò n fi ọwọ́ pa mí lára

Sẹnetọ Sekibo to n sọrọ lori eto ileeṣẹ mohunmaworan Channels Television ni eto ti n lọ lọwọ laarin awọn aṣofin lati wọgile aṣẹ aarẹ.