Oba Aṣigangan ti ìlú Igangan tó wà lórí alééfà nígbà tí Sunday Igboho lọ sí Igangan ti jadé láyé

Oríṣun àwòrán, @Oba Igangan
Asigangan ti ilu Igangan ti jade laye
Asigangan ti ilu Igangan, Ọba Lasisi Adeoye ti re ibi agba n ree. Ọba Alayeluwa naa tẹri gbaṣọ lọwurọ oni, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹjila, ọdun 2021.
Ọkan lara awọn olugbe aafin Asigangan to fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ ṣe alaye pe ikede yoo waye nipa ipapoda Ọba naa laipẹ.
- Ṣé oyún ní Aisha Buhari ni àbí àìsàn jẹjẹrẹ tàbí kí ló fa ẹ̀jọ́ lórí ikún aya Aàrẹ Buhari?
- Ìdí rèé tí Buhari fi kọ̀ láti buwọ́lu àbá àtúnṣe ètò ìdìbò Nàìjíríà
- Olùkọ́ni ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù U-17 ní Gabon di èrò àtìmọ́lé fún ẹ̀sùn fífipá bá àwọn agbábọ́ọ́lù ọ̀kùnrin sùn
- Tinubu, fi ipò ààrẹ sílẹ̀ fáwọn ọ̀dọ́ lọ́dún 2023- Osita Okechukwu
- Wọ́n ti iléèwòsàn pa nítorí àwọn àlùjànú tó n fi ipá bá àwọn nọ́ọ́sì lòpọ̀
- Ìjọba fòfin de lílò tàbí títà èédú bí gáàsì ìdáná ṣe gbówó lórí
Bakan naa ni alaga ijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa, Lateef Akorede ti fi ọrọ naa lede lori itakun ayelujara.

Oríṣun àwòrán, @Asigangan
O ni, "Mo gbọ iroyin to bani lọkan jẹ nipa ipapoda Ọba wa, Oba Abdul- Azeez Adeoye Adewuyi, Aribiyan ||, Gbadewolu 1, Asigangan ti ilu Igangan to jade laye lowurọ oni.
Adanu nla ni eleyii jẹ fun ilẹ Ibarapa ati gbogbo ilẹ Yoruba lapapọ".













