Alaafin Oyo korò ojú sí babalawo tó pe ara rẹ lọ́ba lásìkò ọdún ifá

Oríṣun àwòrán, @AkedeOyo
Aláàfin ti ìlú Ọ̀yọ́, Ọba Làmídì Adéyemí ti gba adé lọ́wọ́ aláwo kan tó sì fi kọ́ ori igi lẹ́yìn tí babaláwo náà wọ adé to si tun pe ara ẹ̀ ní Ọba ní ìsàlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Babaláwo náà ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ifatokun Jayeola Morakinyo, tí awọn kan n pe ní ọba Edu, ní ó wọ adé sórí níbi ayẹyẹ ọdún ifá nínú ìlú Ọ̀yọ́, tí ó sì ní òuń ní àṣẹ láti wọ adé sórí.
Nínú àtẹ̀síta tí kábíyèsí Ọba Lamidi Adeyemi fi síta ní ọjọru ni ó ṣàlàyé pé ìdí tí kábíyèsí fi gbé ìgbésẹ̀ náà ni láti ri wípé kò di ìjà tàbí bíba dúkìá jẹ́ ní agbègbè ìsàlẹ̀ Ọ̀yọ́ lẹ́yìn tí awọn eeyan kan rí gbọ́ pé àwọn ọ̀dọ́ kan fẹ́ ṣe ìkọlù sí ilé babaláwo náà.
- Ìjọba àpapọ̀ kéde ọjọ́ Aje àti ọjọ́ Iṣẹgun tó ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ìsinmi ọdún Keresimesi
- Ẹgbẹ́ àwọn olùgbé Magodo Phase 2 gbé kọ́kọ́rọ́ sẹ́nu ọ̀nà iléègbé náà nítorí àwọn ọmọ onílẹ̀
- Olùwọ́de EndSARS kan móríbọ́ lẹ́yìn ọdún kan lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Kirikiri
- $5.8bn tí Nàìjíríà tún fẹ́ yá, SERAP ní kí Buhari dẹ́kun owó yíyá
- Wò ìdí tí téélọ̀ rẹ fi já ọ kulẹ̀ lásìkò ọdún Kérésìmesì
- Èdèàìyedè láàrín Ààrẹ Buhari àtàwọn aṣòfin àpapọ̀ lórí òfin ìdìbò ní Nàìjíríà
- Mu pàrágá wakọ̀ l'Oyo, kóo kó sí gbaga ìjọba
- Gómìnà Bornu fáwọn ọlọ́dẹ àtàwọn JTF tó ń kojú Boko Haram ní ẹ̀bùn ráìsì àti owó fún ọdún kérésì
Atẹjade naa ni "Awọn eeyan ti kọ oniruru lẹta si Alaafin lori ọrọ babalawo Ifatokun, to n ṣiṣẹ awo labẹ oloye Ifaleye Ikusannu, to jẹ Oluawo ilu Oyo."
"Babalawo naa wọ ade ọhun lasiko ọdun ifa, aworan rẹ si milẹ titi lori ayelujara, eyii ti Alaafin juwe gẹgẹ bii ohun ajeji."
Alaafin si ti bu ẹnu atẹ lu ohun ti babalawo yii ṣe ati pe iru rẹ ko gbọdọ waye mọ."
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ọba Adéyemí ní ìwà babalawo ọhun jẹ́ kàyééfì tí kò sì bójú mu pẹ̀lú ìṣe àti àṣà ilẹ̀ Yorùbá.
Adé náà ni kábíyèsí ti pa láṣẹ pé kí wọ́n kàn mọ́ ìdí Ògún tó wà nínú ààfin ti Aláàfin ti ìlú Ọ̀yọ́.
Alaafi ni igbesẹ naa jẹ ọna lati fi han pé kò sí ẹnikẹ́ni tó lè fi ara rẹ̀ jẹ ọba tàbí pe ara rẹ̀ ní ọba.
















