Boko Haram: Gómìnà Borno ṣe kóríyá fáwọn ọlọ́dẹ àtàwọn JTF tó ń kojú Boko Haram

Zulum

Oríṣun àwòrán, @Zulum

Ku isẹ lo maa n mu ori iṣẹ ya.

Eyi lo difa fun gomina ipinlẹ Bornu, Babagana Zulum to ṣe koriya fawon ọlọdẹ, at'awọn ẹṣọ JTF to fi mọ gbogbo awọn to fi ara wọn sílẹ lati kọju ija si Boko Haram nipinlẹ naa.

Gomina kede pe ijọba yoo fun wọn ni raisi ati owo gẹgẹ bí ẹbùn ọdun fun iṣẹ ribi ribi ti wọn ṣe nipa bi wọn n ṣe gbogun ti Boko Haram.

Gomina ko yọ awọn agbalẹ to n maa tun awọn ilu t'awọn agbesunmọmi ba kọlu ṣe silẹ ninu awọn ti yoo gb'ẹbun ipari ọdun yii.

Bakan naa ni awọn agbalẹ l'awọn ileeṣẹ ijọba gbogbo at'awọn oniruuru ajọ ki gbẹyin.

Àkọlé fídíò, Wa ko iṣẹ ọwọ nipa lilo ede Yoruba

Gomina Zulum f'ọrọ yii lede nigba to n b'awọn olori awọn oṣiṣẹ ìmọ toto at'awọn to fi ara wọn silẹ lati kọju ija si Boko Haram niluu Maiduguri.

Gomina ni igbesẹ yii jẹ ọna lati fi emi imore han si gbogbo awọn to n ṣiṣẹ ran àwọn ẹṣọ ologun lọwọ lẹnu ija si Boko Haram.

Àkọlé fídíò, 8kyti,j

"Gbogbo yin patapata ni ẹ n ṣiṣẹ takuntakun lẹnu ija ti a n ja ki abo le wa nipinlẹ Bornu.

Bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹẹgbẹrun ni yin, ko si iru ohun ti a le ṣe fun yin to le to iṣẹ ti ẹ n ṣe.

Lori awọn oṣiṣẹ onimọtoto wa, lati ago mẹfa aarọ ni ẹ ti maa n ji lati gba oju titi.

Àkọlé fídíò, Odindi ọjọ́ kan ni mo fi wà ní ìhòhò ní Libya tí gbogbo èrò n fi ọwọ́ pa mí lára

A mọ riri iṣẹ ti ẹ n ṣe, a si dupẹ lọwọ yin gidi gidi.

Apo raisi kọọkan ní Gomina Zulum kede pe ki wọn fun ẹni kọọkan wọn.

Àkọlé fídíò, Ibadan Young Girl: Obi Demilade salaye iru iku to pa ọmọ wọn