EndSARSprotest: Olùwọ́de EndSARS kan móríbọ́ lẹ́yìn ọdún kan lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Kirikiri

Robert ati Amofin Festus Ogun

Oríṣun àwòrán, Festus Ogun/facebook

Iroyin ayọ ree fun awọn oluwọde EndSARS ti awọn agbofinro fi si ahamọ kaakiri awọn ibudo aham lorilẹede Naijiria.

Robert Kpanou, to wa lara awọn oluwọde to jade fun iwọde EndSARS wọ gbaga agbofinro ni ọjọ kejilelogun oṣu kẹwaa ọdun 2020. Lati igba naa lo si ti wa ni gba ẹwọn Kirikiri nilu Eko.

Amọṣa lẹyin ọpọlọpọ atotonu ati wahala, ile ẹjọ fa iwe ẹjọ rẹ ya ni ọjọ Ẹti, ọjọ kẹtadinlogun oṣu kejila.

Agbẹjọro rẹ, Festus Ogun ṣalaye pe oniruru idiwọ ni wọn ba pade lẹyin idajọ ile ẹjọ naa ki wọn to ri arakunrin naa yọ jade lọjọ Aje.

Amofin Ogun ni lati orilẹede Benin republic ni Robert ti wa si Naijiria lati wa roko iwankanjẹ ki o to kagbako yii.