Ẹgbẹ́ àwọn olùgbé Magodo Phase 2 fẹ̀sùn kan àwọn ọmọ onílẹ̀ pé wan fẹ́ wó ilé àwọn

Magodo Phase 2 Residents

Oríṣun àwòrán, @Nairametrics

Ogunlọgọ awọn eeyan to n gbe ni ileegbe Magodo, niluu Eko ni ko ri aye wọ ile wọn lẹyin ti awọn adari ẹgbẹ awọn olugbe agbegbe naa gbe agadagodo si ẹnu ọna abawọle rẹ.

Eyii ko ṣẹyin bi awọn adari ẹgbẹ olugbe ileegbe ọhun ṣe sọ pe awọn ọmọ onilẹ ya bo awọn lọna ati wo ile wọn.

Iroyin ni awọn ọmọ onilẹ naa ya bo ileegbe Magodo, pẹlu iranlowọ ọlọpaa lati fi ami pupa si ara awọn ile tuntun nibẹ lọna ati wo awọn ile naa.

Agbẹjọro awọn olugbe agbegbe naa, Tunji Abdulhameed sọ pe awọn ọmọ onilẹ ọhun gbe katakata wa si ẹnu ọna abawọle ileegbe naa lati wo awọn ile kan nibẹ.

O ni "Nnkan bii aago kan ọsan ni wọn wa, awọn ọmọ onilẹ ya bo ileegbe naa, awọn ọlọpaa si n ṣatilẹyuin fun wọn."

"Mo bere lọwọ ọlọpaa ọhun ohun ti wọn wa ṣe, o ni awọn wa lati mu ofin ṣẹ ni."

"Wọn fi atẹjade kan han mi lati inu iwe iroyin lẹyin ti mo bere lọwọ wọn pe ki wọn fi ẹda iwe idajọ ti wọn wa mu ṣe han mi, eyii to jẹ pe awọn funra wọn ni wọn kọ atẹjade naa."

"Lootọ ni ile ẹjọ ti kọkọ dajọ pe ki a fun wọn ni pilọti ilẹ 549 lọdun 1993, amọ ile ẹjọ ko sọ ni pato ibi ti ilẹ naa yoo wa."

Àkọlé fídíò, Wa ko iṣẹ ọwọ nipa lilo ede Yoruba

Alaga ẹgbẹ awọn olugbe ileegbe magodo, Ọjọgbọn Ayodele Ogunye sọ fun awọn akọroyin pe kii ṣe igba kọkọ ree ti awọn ọmọ onilẹ yoo kọlu ileegbe naa, awọn si n fẹ ki ijọba da si ọrọ ọhun.

Ọjọgbọn Ogunye sọ pe "Ọdun 1992 ni mo ti n gbe nibi ṣugbọn o ti pẹ ti a ti n ni iṣoro pẹlu awọn ọmọ onilẹ yii, titi ti ẹjọ naa fi fẹ loju."

"Lootọ ni ile ẹjọ to ga julọ ti kọkọ dajọ pe ki wọn fun ẹbi Adeyiga ni pilọti ilẹ 549 ṣugbọn ile ẹjọ ọhun ko sọ pe ki wọn fun wọn nilẹ naa ni Magodo."

"Lẹyin naa ni ijọba Eko fun wọn ni lawọn ilẹ kan loju ọna Badagry ati Ibeju Lekki, nnkan bii ọọdunrun lara wọn si ti gba ilẹ naa."

Ogunye pari ọrọ rẹ pe bo tilẹ jẹ pe gomina Babajide San-Olu ni oun ko tii gbọ nipa bi awọn onilẹ naa ṣe n yọ awọn lẹnu, kii ṣe ohun to bojumu ki awọn ọmọ onilẹ kan maa da awọn laamu lori ilẹ ijọba ti wọn kọ ileegbe si.

Àkọlé fídíò, Parental Guidance: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀