Ìjọba àpapọ̀ kéde ọjọ́ Aje àti ọjọ́ Iṣẹgun tó ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ìsinmi ọdún Keresimesi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba apapọ Naijiria ti kede ọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlọgbọn ati ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kejila, gẹgẹ bii ọjọ isinmi lati sami si ayẹyẹ ọdun Keresimesi.
Ijọba apapọ tu kede ọjọ Aje, ọjọ kẹta, oṣu Kinni, ọdu 2022 gẹgẹ ọjọ ọjọ isiinmi ayajọ ọdun tuntun.
Minisita ọrọ abẹle, ọgbẹni Rauf Aregbesola to fi ikede naa sita lorukọ ijọba apapọ ki awọn ọmọlẹyin Kristi ku imura ọdun Keresimesi naa ati ayẹyẹ ọdun tuntun.
- Olùwọ́de EndSARS kan móríbọ́ lẹ́yìn ọdún kan lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Kirikiri
- $5.8bn tí Nàìjíríà tún fẹ́ yá, SERAP ní kí Buhari dẹ́kun owó yíyá
- Èdèàìyedè láàrín Ààrẹ Buhari àtàwọn aṣòfin àpapọ̀ lórí òfin ìdìbò ní Nàìjíríà
- Mu pàrágá wakọ̀ l'Oyo, kóo kó sí gbaga ìjọba
- Wò ìdí tí téélọ̀ rẹ fi já ọ kulẹ̀ lásìkò ọdún Kérésìmesì
- Gómìnà Bornu fáwọn ọlọ́dẹ àtàwọn JTF tó ń kojú Boko Haram ní ẹ̀bùn ráìsì àti owó fún ọdún kérésì
- Èrò àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí N305 bílíọ̀nù náírà tí INEC fẹ́ ná fi ṣètò ìdìbò 2023
Aregbesola sọ fun awọn Kristẹni pe ki wọn maa wo awokọṣẹ Kristi ninu oun gbogbo ti wọn ba n ṣe.
O ni "O yẹ ki a maa wo awọkọṣe Jesu Kristi ninu iwa ati iṣẹ wa."
"Lara awọn iwa awokọṣẹ Kristi ni iwapẹlẹ, aanu, suuru, alaafia ati ododo, eyii ti ìbí rẹ n ṣapẹrẹ."
Minisita naa rọ awọn Kristẹni lati fi akoko ọdun naa gbadura fun alaafia Naijiria, paapaa lasiko yii ti eto abo mẹhẹ.
Aregbesola naa sọ fun awọn araalu lati ṣora ṣe lasiko pọpọṣinṣin ọdun naa nitori ajakalẹ arun Covid-19 to ṣi wa lode.
O tun parọwa si awọn araalu lati maṣẹ kawọ gbera ti wọn ba kofiri ẹnikẹni to ba n ṣe afihan arun Covid-19.
Aregbesola pari ọrọ rẹ pe ki awọn ọmọ Naijiria maṣe sọ ireti nu nitori ọdun 2022 to n bọ lọna yoo dara ju ọdun 2021 yii lọ.'














