Fresh $5.8bn loan: SERAP kìlọ̀ fún Buhari pé kó yé kó Nàìjíríà sí gbèsè

Oríṣun àwòrán, @serap
Ajọ to n gbogun ti iṣowo ilu kumọ kumọ, SERAP ti kepe Aarẹ Muhammadu Buhari lati dẹkun owo yiya ijọba apapọ at'awọn ijọba ipinlẹ mẹrindinlogoji lati le yanju gbese to wa nilẹ ti Naijiria jẹ.
Ajọ SERAP ni ẹyawo ijọba apapọ ati ipinlẹ mẹrẹẹrindinlogoji n ṣakoba fun ọrọ aje Naijiria.
Ajọ naa sọ pe awọn mẹkunnu l'awọn ẹyawo yii n ṣakoba fun julọ.
- Ìdí rèé tí Buhari fi kọ̀ láti buwọ́lu àbá àtúnṣe ètò ìdìbò Nàìjíríà
- Ṣé oyún ní Aisha Buhari ni àbí àìsàn jẹjẹrẹ tàbí kí ló fa ẹ̀jọ́ lórí ikún aya Aàrẹ Buhari?
- Aṣigangan ti ìlú Igangan ti jadé láyé
- Èrò àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí N305 bílíọ̀nù náírà tí INEC fẹ́ ná fi ṣètò ìdìbò 2023
- Wo orílẹ́èdè tó fẹ́ fi òfin de sìgá mímú fún ìran ọmọ wọn tó ń bọ̀
SERAP ke gbajare bayii lẹyin ti ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja buwọlu aba Aarẹ Buhari lati ya $5.8bn ati ẹbẹ fun miliọnu mẹwaa dọla laipẹ yii.
Ninu lẹta ti SERAP fi ranṣẹ si Buhari, igbakeji oludari ajọ naa, Kolawole Oludare ni ti ijọba ba le dẹkun ẹyawo, ọrọ aje Naijiria yoo gberu sii.
SERAP ni didẹkun ẹyawo yoo tun mun ipadabọ sipo wa fun Naijiria lẹyin ajakalẹ arun covid-19.
Ajọ naa ni owo yiya ni gbogbo igba yoo dena mọ ijọba lati le nawo sí ẹka eto idajọ lati le ri pe ẹtọ ọmọnìyàn wa.
SERAP ni ẹyawo gbogbo igba tun maa jẹ kí owo ori sisan pọ si eyi ti yoo pa awọn ọmọ Naijiria lara.
SERAP kọminu lori bi ijọba kii ṣe jẹ kí o han si araalu bi wọn ti na awọn owo ti wọn ya tẹlẹ.
- $5.8bn tí Nàìjíríà tún fẹ́ yá, SERAP ní kí Buhari dẹ́kun owó yíyá
- Mu pàrágá wakọ̀ l'Oyo, kóo kó sí gbaga ìjọba
- Wò ìdí tí téélọ̀ rẹ fi já ọ kulẹ̀ lásìkò ọdún Kérésìmesì
- Gómìnà Bornu fáwọn ọlọ́dẹ àtàwọn JTF tó ń kojú Boko Haram ní ẹ̀bùn ráìsì àti owó fún ọdún kérésì
- Èdèàìyedè láàrín Ààrẹ Buhari àtàwọn aṣòfin àpapọ̀ lórí òfin ìdìbò ní Nàìjíríà
SERAP ni o yẹ ki ile aṣofin agba l'Abuja ṣe agbeyẹwo awọn koko to wa ninu owo ti ijọba fẹ ya ati ọna ti o fẹ gba san owo naa pada ki ile to buwọ luu.
SERAP ni eyi wa ni ibamu pẹlu pẹlu ojuṣe ile aṣofin agba l'Abuja gẹgẹ bi o ti wa ni akọsilẹ ninu iwe ofin Naijiria.
SERAP ninu obiti biti gbese ni ijọba apapọ ati awọn ipinlẹ Naijiria wa tẹlẹ, ki ile aṣofin to tun buwọ lu ẹyawo mii.
SERAP sọ ninu iwe to kọ ranṣẹ si Buhari pe, oun yoo ṣa gbogbo ipa oun lati ri pe ijọba apapọ at'awọn ti ipinlẹ tẹlẹ imọran oun lori owo yiya.
- Olùkọ́ni ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù U-17 ní Gabon di èrò àtìmọ́lé fún ẹ̀sùn fífipá bá àwọn agbábọ́ọ́lù ọ̀kùnrin sùn
- Wo ààrẹ orílẹ̀-èdè tó ṣiṣẹ́ awakọ̀ "taxi" kó tó di ààrẹ
- Tọkọ-taya dèrò àtìmọ́lé lẹ́yìn tí wọ́n ta ọmọ wọn tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò ju oṣù kan lọ ní ₦50,000
- Ìjọba fòfin de lílò tàbí títà èédú bí gáàsì ìdáná ṣe gbówó lórí
- Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn dá olùkọ́ èwe ṣọ́ọ̀ṣì Sotitobire sílẹ̀
- Wo bí olórí ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tẹ́lẹ̀, Gabriel Boric, ẹni ọdún 35 ṣe wọlé ìbò ààrẹ Chile















