Philip Akinyemi gba ìwé lọ rọọ́kún nílé nítorí àwọn ọ̀rọ̀ tó ń sọ lójú òpó Facebook rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Osun

Oríṣun àwòrán, Philip Akinyemi/Gboyega Oyetola
Iroyin kan n kaakiri pe ijọba ipinlẹ Ọṣun ti paṣẹ lọ rọọkun nile fun olukọ ileewe girama kan nipinlẹ naa, Ọgbẹni Akinyẹmi Phillip lori awọn agbejade kan to n fi sita loju opo facebook rẹ.
Iroyin ọhun ni ijọba ipinlẹ Osun ti paṣẹ lọ rọọkun nile fun okunrin naa, to jẹ olukọ nile ẹkọ girama Masifa Community Grammar School, to wa ijọba ibilẹ Ejigbo.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ẹṣẹ kan ṣoṣo ti okunrin naa ṣe ni pe o maa n sọrọ, osi tun maa n fi awọn aworan lede loju opo Facebok ni atẹlẹyin fun ẹgbẹ The Osun Pregressives, TOP, eyii to jẹ abala kan ninu ẹgbẹ oṣelu APC, eyii igbagbọ wa pe wọn jẹ alatako si gomina Gboyega Oyetola to wa lori alefa lọwọlọwọ.
- Olòrì Silekunola Naomi Ogunwusi: Mo ti sún síwájú, mo gbìyànjú pé kí ìgbèyàwó yìí ṣiṣẹ́ ṣùgbọ́n....
- Kò tíì pẹ́ jù bí ìjọba bá leè sọ ẹni tó pa olóògbé Bola Ige- Gani Adams
- Kí ló dé tí Ooni Ile Ife fẹ́ gbẹ̀mí ara rẹ̀?
- Àìsàn tó ń ṣe ọ ní ohun ṣe pẹlú oorun rẹ - Onímọ
- Kí ló dé tí Hisbah Kano ṣe fìwé pe Òbí Shatu Garko tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹ 'Miss Nigeria'?
- Ìjọba àpapọ̀ kéde ọjọ́ Aje àti ọjọ́ Iṣẹgun tó ń bọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ìsinmi ọdún Keresimesi
- Alaafin ìlú Oyo gba adé lórí babalawo tó pe ara rẹ lọ́ba, ó fi adé náà kọ́ igi
- Ẹgbẹ́ àwọn olùgbé Magodo Phase 2 gbé kọ́kọ́rọ́ sẹ́nu ọ̀nà iléègbé náà nítorí àwọn ọmọ onílẹ̀
Ṣaaju ni wọn ti kọkọ fun okunrin naa lẹta wa wi tẹnu rẹ lori idi to ṣe n "tabuku" Oyetola loju opo Facebook rẹ.
Lẹta wa wi tẹnu rẹ naa ni "Awọn ọrọ ti o maa fi lede loju opo Facebook fi han pe o ti n ya bara kuro ninu isẹ ti ijọba gba ọ fun gẹgẹ bii olukọ."

Oríṣun àwòrán, Philip Akinyemi
"O ti mu ọrọ oṣelu ni okunkundun ju iṣẹ olukọ ti wọn gba ọ fun lọ, nipa ṣiṣe bẹẹ, o ko jẹ olotitọ si ijọba ipinlẹ Osun gẹgẹ bii oṣiṣẹ ijọba."
"Awọn atẹjade rẹ lori ayelujara jẹ iwa aibọwọ fun ijọba ipinlẹ yii ati gomina to n ṣiṣẹ takun-takun lati san owo oṣu awọn oṣiṣẹ rẹ̀."
Amọ ṣa, ninu lẹta ti wọn ti ni ko lọ rọọkun nile, ẹṣẹ ti wọn ni o ṣẹ ni pe o ṣi ọọfisi rẹ lo gẹgẹ bii olukọ.
Lẹta naa, ti wọn kọ logunjọ, oṣu kejila, ọdu 2021 yii, ti E.O Onatola buwọlu sọ pe "Wọn ni ki n fi akoko yii sọ fun ọ pe lẹyin ti o ṣi ọọfisi rẹ lo, iwa ti o wu ko dun mọ awọn alaṣẹ ninu."
"Pe, iwọ ọgbẹni Akinyemi Philip ti o jẹ olukọ nile ẹkọ Masifa Community Grammar School, Ejigbo, gbajumọ ọrọ oṣelu ju iṣẹ olukọ ti ijọba gba ọ fun."
"Awọn ọrọ ti o maa n kọ lori itakun ayelujara lodi si ofin to gbe iṣẹ oṣiṣẹ ijọba ro, o ko si ni aṣẹ lati wọ inu ile ẹkọ lai kọkọ gba aṣẹ lati ṣe bẹẹ."
BBC Yoruba kan si okunrin naa, o si fi idi ọrọ naa mulẹ.
Abẹwo BBC si oju opo Facebook okunrin naa fi han pe ọrọ oṣelu pọ daadaa loju opo rẹ.
Ọpọ awọn eeyan ipinlẹ Osun lo ti bẹrẹ si n bu ẹnu atẹm ijọba ipinlẹ naa lori igbesẹ ọhun, beẹ si ni awọn ọrẹ okunrin naa lori itakun Facebook ti n sọrọ atilẹyin fun un.
















