Òbí Shatu Garko tó jáwé olúborí nínú ìdíje 'Miss Nigeria' ní àlàyé láti ṣé fún wà- Hisbah

Miss Nigeria

Oríṣun àwòrán, Shatu Garko

Olori ikọ Ọlọpaa ẹsin Hisbah nipinlẹ Kano, Sheikh Harun Ibn Sina ti sọ pe awọn yoo fi iwe pe obi ararabinrin to jaweolubori ninu idije arẹwa to waye laipẹ ni Naijiria.

Ọmọ ọdun mejidinlogun Shatu Garko lo jaweolubori ninu iidje yi to waye ni ọjọ Kẹtadinlogun, osu Kejila, ọdun 2021.

Miss Nigeria

Oríṣun àwòrán, @Shatu Garko

Oun ni obinrin alakọkọ to n wọ Hijabi ti yoo gbe igbaoroke ninu idije yi.

Wọn ni idi tawọn fi fẹ bawọn ni gbolohun ni pe o lodi si ofin Islaamu ki ọmọ wọn kopa ninu idije arẹwa iru eleyi.

"A ti fidi ọrọ mulẹ pe musulumi lati ipinlẹ Kano ni Garko n se ati pe ijọba ibilẹ Garko lawọn obi rẹ ti wa ni Kano.Ipinlẹ Sharia ni Kano jẹ tori naa laa fi ni jẹ ko lọlai se pe a ba wọn sọrọ''

O ni awọn yoo fiwe pe obi arabinrin naa nitori nkan to se lodi si ofin sharia.

Àkọlé fídíò, Parental Guidance: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀

Sheikh Ibn Sina tẹsiwaju pe ''To ba wa jẹ pe ko mọ,a o ba sọrọ ko ba le jawọ ninu iru iwa bẹẹ ati ki awọn ọmọbinrin mii ma ba fẹ kọ ise rẹ.''

Ohun ti Hisbah sọ pe Qurani sọ

Àkọlé fídíò, 8kyti,j

Sheik Ibn Sina to jẹ ilumọọka Onimọ ẹsin Islammu saaju ko to gba ipo olori Hisbah fi awọn ọrọ lati inu Quran lati gbe ọrọ rẹ.

O ni ''Lati ọjọ to ti pẹ ninu islammu ni wọn ti lodi si ki eeyan kopa ninu idije arẹwa.

Àkọlé fídíò, 'Èmi ò kí ń lu ìyàwó mi'

O ti pẹ ti olukọ wa agba Mustafa Saba'i ti dahun ibeere lori ọrọ yi to si ni eewọ ni nitori awọn idi wọn yi''

•Ọpọ nkan to n sẹlẹ nibiidije yi tako Islammu bi apẹrẹ ki a maa fi ara obinrin han

Àkọlé fídíò, KieKie

•Bẹẹ ni idije yi n kọ awọn obinrin bi wọn ko se ni ni itiju

•Allah sọ fun Anọbi pe ko sọ fun awọn iyawo rẹ ati awọn obinrin onigbagbọ mi pe ki wọn bo ara wọn daada

Àkọlé fídíò, BBC News: Ifọrọwerọ pẹlu Sẹnẹtọ Olujimi

•Ninu ọrọ Quran mii, Allah pa awọn musulumi lasẹ lati rẹju wọn silẹ nibi iwokuwo

Nigba ti Sheikh Ibn Sina yo kasẹ ọrọ rẹ nile, o sọ fun BBC pe ibinu Allah yoo maa wa pẹlu awọn to se agbatẹru iru idije to n fi ihoho obinrin han yi nitori Allah ko nifẹ si.

Àkọlé fídíò, Odindi ọjọ́ kan ni mo fi wà ní ìhòhò ní Libya tí gbogbo èrò n fi ọwọ́ pa mí lára

Arabinrin Garko lo gbade oge lọwọ Etsanyi Tukura ọmọ ipinlẹ Taraba to jẹ ẹni ikẹtalelogoji to gba idije Miss Nigeria.

Gẹgẹ bi awọn to seto idije yi ti se sọ, Garko yoo gba ile kan, miliọnu mẹwaa Naira, anfaani lati gbe aaye igbadun lọdun kan,ọkọ ayọkẹlẹ ati anfaani lati jẹ asoju awọn ileesẹ.

Àkọlé fídíò, Wo àwọn ohun tí o kò kàsí nípa mátírẹ́sì tí o ń sùn, ṣùgbọ́n tó ń ní ipa nínú ayé rẹ