Wo àwọn ìdí pàtàkì fífun àwọn ọmọdé ní abẹ́rẹ́ àjẹsára

Ọmọdé tí wọ́nnń fún ní abẹ́rẹ́ àjẹsára

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Àjọ tó ń rí sí ètò ìlera àgbáyé, World Health Organization, WHO ti sọ pé pàtàkì ní abẹ́rẹ́ àjẹsára pàápàá ní ipele ìgbà tí àwọn bá wà ní kékeré.

Wọ́n ní abẹ́rẹ́ àjẹsára yóò dènà àjàkálẹ̀ àti ìtànkálẹ̀ àìsàn àti ààrùn.

WHO ní gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára máa ń dènà ikú àwọn ọmọdé tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́ta lọ́dún lọ́wọ́ àwọn àìsàn bíi pneumonia, tuberculosis, measles àti influenza.

Gẹ́gẹ́ bí WHO ṣe sọ, àwọn ìjọba, iléeṣẹ́ tó ń rí sí ṣíṣe abẹ́rẹ́ àjẹsára, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àtàwọn elétò ìlera ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti lè rip é wọ́n pèsè abẹ́rẹ́ àjẹsára tó pójú owó tí kò ní mú ìpalára bá àwọn ọmọ.

Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni èèyàn pọ̀ sí jùlọ ní Africa, tó sì ń kojú ìṣòro àwọn ìtànkálẹ̀ àìsàn fáwọn ọmọdé èyí tó ṣe é dènà.

Dídá ààbò bo àwọn ọmọdé ní Nàìjíríà

Dókítà Fatima Usman tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ìtọ́jú àwọn ọmọdé ní ilé ìwòsàn ìjọba àpapọ̀ tó wà ní Gombe, orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Ó ṣàlàyé pé abẹ́rẹ́ àjẹsára ní Nàìjíríà máa ń wáyé ní ipele ipele, èyí tí wọ́n máa ń gbà fáwọn láti ìgbà tí wọ́n bá ti bímọ títí di ìgbà tó fi máa pé ọmọ ọdún mẹ́sàn-án.

Lára àwọn tí wọ́n máa ń gbà nígbà tí wọ́n bá ti bímọ ni BCG èyí tó máa ń dá ààbò bo ikọ́ fére, tuberculosis, Hepatitis, tó ń dá ààbò bo ẹ̀dọ̀ àti abẹ́rẹ́ àjẹsára tó ń dá ààbò bo àìsàn rọmọlápá rọmọlẹ́sẹ̀.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ó sọ pé ó dára láti fún àwọn ọmọdé ní abẹ́rẹ́ yìí láàárín ọjọ́ mẹ́ta tí wọ́n bá ti bímọ tán.

Dókítà Fatima Usman sọ pé lẹ́yìn èyí ni wọ́n máa bẹ̀rẹ̀ sí ní gba abẹ́rẹ́ míì tí wọ́n bá ti pé ọmọ ogójì ọjọ́ ni PCV èyí tó máa ń dá ààbò bo pneumonis, polio, IPV tí òun náà ń dá ààbò bo polio, Penta, pentavalent èyí tó ń dá ààbò bo pertussis, tuberculosis, hepatitis, tetanus àti abẹ́rẹ́ àjẹsára Hib tó máa ń dá ààbò bo pneumonia.

Ní Nàìjíríà, abẹ́rẹ́ tó ń dènà àìsàn ibà ni ìjọba ti ń pèsè ṣùgbọ́n kò pọ̀ ní Nàìjíríà.

Lẹ́yìn náà ni wọ́n máa fún àwọn ọmọdé ní abẹ́rẹ́ àjẹsára measles àti rubella nígbà tí wọ́n bá tip é ọmọ oṣù mẹ́sàn-án.

Dókítà náà tún ṣàlàyé pé ó ní àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára kan tí wọ́n máa ń fún àwọn ọmọdé tó ṣe pàtàkì láti dènà àwọn àìsàn bíi sickle cell.

WHO ní àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára tó ń dènà àìsàn ibà bíi typhoid fever àti rotavirus èyí tó máa ń dènà èébì àti ìgbẹ́ gbuuru.

Àjọ náà sọ pé àwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára láti dènà àwọn àìsàn tó lé ní ọgbọ̀n tó le mú ẹ̀mí èèyàn lọ ló wà.

Bákan náà ni wọ́n fi kun pé ó ti lé ní àádọ́ta ọdún táwọn abẹ́rẹ́ àjẹsára ti wà tó ń dènà àìsàn mẹ́rìnlá, èyí tó ń dá ààbò bo ẹ̀mí èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù 154.

Ní àwọn àsìkò yìí, abẹ́rẹ́ àjẹsára ti mú àdínkù bá ikú àwọn ọmọdé pẹ̀lú ìdá ogójì.

Ẹ̀wẹ̀, ìjábọ̀ tí àjọ náà fi sórí ìtàkùn àgbáyé rẹ̀ nínú oṣù Keje, ọdún 2025 ṣàfihàn rẹ̀ pé àwọn ọmọdé tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́rìnlá ni wọn kò gba abẹ́rẹ́ àjẹsára káàkiri àgbáyé lọ́dún 2024.

Wọ́n ní ó ṣeéṣe kí àwọn àìsàn kan bíi measles, nítorí ìtànkálẹ̀ rẹ̀, le mú àwọn ọmọdé tó lé ní ogún mílíọ̀nù ní ìparí ọdún 2024 nítorí àwọn ọmọdé tí kò gba abẹ́rẹ́ àjẹsára wọn.

WHO pẹ̀lú àjọsẹpọ̀ àwọn orílẹ̀ èdè àgbáyé ti fi ọdún 2030 ṣe gbèdéke ọdún táwọn ọmọdé káàkiri àgbáyé gbọdọ̀ gba abẹ́rẹ́ àjẹsára lójúnà àti ri pé gbogbo àgbáyé wà ní ìlera tó péye.