Èṣù tiwa kì i ṣe Sátánì, olùgbàlà aráyé ni -Àwọn Oníṣẹ́ṣe Ilẹ̀ Iwo.

Lọsẹ to kọja yii, lasiko ti pọpọṣinṣin ọdun Keresi gbode ni ọdun Eṣu ti awọn oniṣẹṣe maa n ṣe waye.
Nibi ọdun naa ti wọn ṣe niluu Iwo, ipinlẹ Osun, ni awọn alakooso ọdun Esu ti ṣalaye awọn ohun ti ọpọ eeyan ko mọ nipa Esu.
Araba Awo ilu Iwo, Ifatayo Afolabi, ṣalaye fun BBC News Yoruba, pe Esu ti awọn Oniṣẹṣe n foribalẹ fun, yatọ si Satani ti awọn Kristẹni ati Musulumi gba pe ko daa.
Araba Awo Iwo sọ pe Esu ti awọn n bọ ni iṣẹ pataki to wa jẹ laye, nitori iranṣẹ Olodumare ni.
O ni Esu ti awọn Onisẹse n foribalẹ fun ki ṣe esu ti awọn Kristeni ati awọn Musulumi pariwo rẹ, ati pe olugbala araye ni Esu tawọn.
"Ko si olugbala miran to ju Esu lọ"

Ninu alaye tirẹ lori Esu, Ifawole Ajani, ẹni to jẹ Awiṣẹ Awo ti ilu Iwo, sọ pe ko si olugbala miran to ju Esu ti awọn n sọ nipa rẹ yii lọ.
Ifawole ṣalaye pe Esu yii ki i ṣe alawọ funfun, iranṣẹ Olodumare to ran wa lati gba gbogbo eeyan kalẹ ni.
Gẹgẹ bi Awisẹ Awo ilu Iwo naa ṣe wi:
"Ko si olugbala miran to ju Esu lọ, olugbala kan ṣoṣo ti Olodumare ran si awa eniyan ni Esu.''
O ni ki ẹnikẹni ma ṣe daamu ara rẹ nitori igbala, ki wọn tọ Esu wa, ki wọn si yee foju aburu wo o.
Wolii ni mi tẹlẹ ki n too di Oniṣẹṣe- Yeye Olokun

Yatọ si Araba ati Awiṣẹ Awo, ẹlomiran to tun kin ọrọ Esu yii lẹyin ni obinrin kan, Okunteniola Ẹgbẹdiwura, ẹni tawọn eeyan mọ si Yeye Olokun.
Yeye Olokun, ẹni to ni wolii loun tẹlẹ ninu ijọ Kristẹni, ṣalaye pe Esu jẹ ọkan pataki lara iranṣẹ Olodumare.
O fi kun un pe ipa pataki ni Olodumare gbe le Esu lọwọ, o si n kopa naa bo ṣe yẹ.
Olootọ ni Esu bi Yeye Olokun ṣe ṣapejuwe rẹ, oun si ni oninuure julọ ninu awọn irunmọlẹ ti Olodumare da gẹgẹ bo ṣe wi.
Okunteniola tun tẹsiwaju pe, oun mọ Bibeli daadaa, oun ti fi igba kan ri jẹ ojisẹ ni ilana kristeni, koun too pada sibi ori da oun si.
"Mo mọ Bibeli daadaa, wolii ni mi tẹlẹ, ṣugbọn aṣiṣe ni awọn to n pe Esu ni Satani n ṣe. Esu ki i ṣe Satani rara, iransẹ Olodumare ni.
"Mo ti figba kan ri jẹ ojiṣẹ nilana Kristẹni, ki n too pada sibi ti ori da mi si bayii."
Awọn to n bọ Esu naa sọ pe ko si bi ọba kan yoo ṣe ni kawọn ma bọ ọ niluu Iwo, nitori ilana Iṣẹṣe ti Esu jẹ ọkan ninu wọn ni gbogbo ọba ilẹ Yoruba n gba jọba.













