Iléeṣẹ́ ìrẹsì dàwó, èèyàn kan kú, márùn ún míràn há sábẹ́ irin

Oríṣun àwòrán, other
Apakan ileeṣẹ irẹsi kan to wa ni ilu Birnin Kebbi ti dawo to si ti pa eeyan kan, ti awọn marun un miran ṣi ha si abẹ awoku ile ati irin ileeṣẹ naa.
Gẹgẹbi iroyin abẹle ṣe sọ, oṣiṣẹ ileeṣẹ irẹsi naa ni ni eeyan to di oloogbe naa.
Lasiko ti igbakeji gomina ipinlẹ Kebbi, Sẹnetọ Umar Abubakar Tafida de ibudo ile to dawo naa, eto idoola ẹmi awọn to ha si abẹ awoku ile naa ṣi n lọ lọwọ.
Ijọba ipinlẹ Kebbi ti daro pẹlu awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa atawọn oṣiṣẹ ibẹ.
igbakeji gomina ipinlẹ Kebbi, Sẹnetọ Umar Abubakar Tafida ṣalaye lasiko abẹwo rẹ laṣalẹ ọjọ Aje wa lati le mọ ọwọja ijamba naa.
Awọn oṣiṣẹ panapana atawọn osiṣẹ ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri pawọpọ ṣe iṣẹ idoola lati yọ awọn to ha si abẹ awoku orule naa.
Ko tii si ẹni le sọ ni pato ohun to ṣokunfa ijamba naa. Ijọba ipinlẹ naa ti sọ pe iwadi yoo waye lori ni kete ti wọn ba pari iṣẹ idoola ẹmi ti wọn n ṣe lọwọ.










