Kò sí à ń padà sẹ́yìn lórí ìlànà owó orí tuntun - Ààrẹ Tinubu

Ààrẹ Bola Tinubu wọ aṣọ olomi aro, de igo sójú ní apá òsì, aṣọ dúdú tí wọ́n kọ àkọ́lé san owó orí rẹ̀ wà ní apá òsì

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu/Facebook/Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Ahmed Tinubu ti ní kò sí à ń padà sẹ́yìn lórí ọ̀rọ̀ owó orí tuntun èyí tó máa bẹ̀rẹ̀ lọ́la òde yìí, ìyẹn ọjọ́ Kìíní, oṣù Kìíní, ọdún 2026.

Tinubu sọ èyí nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde pé gbogbo awuyewuye tó ń wáyé lórí ọ̀rọ̀ owó orí náà, báwọn kan ṣe ń pè fún kí ìjọba ṣe ìdádúró àmúṣẹ owọ orí náà, kò tó láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Ṣáájú ni awuyewuye ti ń wáyé lẹ́yìn tí ilé aṣòfin buwọ́lu àbá owó orí náà, táwọn kan ṣe ń fẹ̀sùn kàn pé ohun tí wọ́n gbá jáde fún aráàlú kọ́ ni ilé aṣòfin buwọ́lù, pé àwọn àyípadà kan ti wáyé lórí rẹ̀.

Ẹgbẹ́ àwọn agbẹjọ́rò, NBA, ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́, NLC, ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Nàìjíríà, NANS àtàwọn míì ni wọ́n ti pè fún ìdádúró ṣíṣe àmúṣẹ owó orí náà lẹ́yìn tí aṣòfin kan, Abdussamad Dasuki fẹ̀sùn kàn pé ìyàtọ̀ wà láàárín ohun tí ìjọba gbé síta àti èyí tí àwọn aṣòfin buwọ́lù.

Ní oṣù Kẹta, ọdún 2025ni ìjọba gbé àbá tuntun jáde lórí owó orí èyí tí wọ́n pè ní National Revenue Service, Joint Revenue Board of Nigeria, Nigeria Tax Administration Act àti Nigeria Tax Act èyí tí wọ́n buwọ́lù nínú oṣù Kẹfà, ọdún 2025.

Lẹ́yìn àwọn ẹ̀sùn yìí ni olórí ilé aṣojúṣòfin, Abbas Tajudeen gbé ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni méje dìde láti ṣe ìwádìí àwọn ẹ̀sùn náà kí wọ́n sì jábọ̀ padà fún ilé lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan, tí ìgbìmọ̀ náà sì ṣèlérí láti fi ijábọ̀ wọn léde láìpẹ́.

Àmọ́ Ààrẹ Tinubu tin í gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi ń kàn lórí àbá náà kò tó láti ṣèdádúró ṣíṣe àmúṣẹ owó orí náà.

Ààrẹ ní àmúṣẹ owó orí náà táwọn kan ti bẹ̀rẹ̀ láti inú oṣù Kẹfà ọdún 2025 ni àwọn ipele yòókù yóò jẹ́ ṣíṣe àmúṣẹ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Kìíní, oṣù Kìíní, ọdún 2026.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ààrẹ ní ìgbésẹ̀ náà jẹ́ ojúná fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti ṣàgbékalẹ̀ ìlànà tó dúró ire àti níní ìpìlẹ̀ tó yanrantí lórí ètò ìnáwó rẹ̀.

Ó ṣàlàyé pé àtúntò owó orí tuntun yìí kò ní mú àlékún bá owó orí táwọn èèyàn ti ń san tẹ́lẹ̀ bíkòṣe láti mú ìrẹ́pọ̀ bá àwọn èyí tó ti wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀.

Ó wá rọ gbogbo àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ láti ṣe àtìlẹyìn fún ipele ṣíṣe àmúṣẹ òfin náà èyí tó ti dé báyìí.

Ó fi kun pé ìṣèjọba òun mọ̀ sí gbogbo awuyewuye tó ti ń wáyé lórí owó orí tuntun náà èyí tó níṣe pẹ̀lú àwọn àyípadà tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé wọ́n ti ṣe si.

Tinubu sọ àrídájú rẹ̀ pé ìṣèjọba òun ní ìfarajìn sí títẹ̀lé ìlànà òfin àti ṣíṣe òótọ́ lorí òfin owó orí náà.

Bákan náà ló ní iléeṣẹ́ ààrẹ ti ṣetán láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ilé aṣòfin láti lè ri dájú pé wọ́n ṣe àtúnṣe gbogbo àwọn kùdìẹ̀kudiẹ tó wà lórí ọ̀rọ̀ owó orí náà ní kíákíá.

Ó tẹ̀síwájú pé ìṣèjọba òun yóò túnbọ̀ máa ṣe àrídájú rẹ̀ pé wọ́n fi aráàlú s akàn lórí gbogbo ìgbésẹ̀ tí wọ́n bá fẹ́ gbé lójúnà àti rip é wọ́n ṣètò owó orí èyí tí yóò mú ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú bá tẹrútọmọ.