Àwọn kókó tó jẹyọ nínú ọ̀rọ̀ ìkínikúọdún tí Ààrẹ Tinubu fi ránṣẹ́ sáwọn ọmọ Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Bayo/X
Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Tinubu, ti ni ọrọ aje orilẹede yii, eto aabo ti ko fi ọkan balẹ atawọn nnkan mi-in to n koju araalu bii iṣoro yoo dara si i ni 2026 ti a mu yii.
Ninu ọrọ ikini ku ọdun rẹ si awọn ọmọ Naijiria, eyi to sọ laaarọ oni, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 ni Tinubu ti kede bẹẹ.
Aarẹ ko ṣai mẹnuba ọrọ owo ori to n kọ ọpọ araalu lominu, pẹlu bi awọn nnkan kan ko ṣe ye wọn nipa ofin owo ori sisan, ati bawọn kan ṣe n pe fun di ọwọ ofin naa duro fungbe diẹ na.
Tinubu sọ pe asiko yii gan-an lo ṣe pataki ju lati bẹrẹ ofin owo ori sisan naa, lati mu ki ọrọ aje rugọgọ.
Nipa ti aabo, Tinubu ni oun naa mọ pe nnkan ko fararọ, ṣugbọn Naijiria ti n fọwọsowọpọ pẹlu awọn ilẹ okeere, paapaa ilẹ America, lati ṣẹgun awọn amookunṣika.
"Pẹlu suuru, ninu ẹkọ iṣuna owo, ati ki ero wa jẹ ọkan ṣoṣo, orilẹede Naijiria yoo lagbara si i ni 2026, yoo si le duro ṣinṣin nipo agba."
Bẹẹ ni Aarẹ Tinubu wi.
O fi kun un pe bi ọrọ aje ṣe daagun to kaakiri agbaye, iṣakoso oun ṣi gbiyanju lati mu atunto ba ti Naijiria, eyi to se eso rere lẹka ọrọ aje tiwa.
Àwọn kókó míràn nínú ọ̀rọ̀ Ààrẹ
- Pinpin iṣẹ aabo si ẹlẹkajẹka
Tinubu tẹnumọ igbagbọ rẹ ninu pinpin awọn ẹṣọ alaabo si ẹka-ẹka.
Eyi lo ni o fa igbesẹ awọn ẹṣọ aṣogbo to le ṣe iranwọ, awọn ti yoo le dọdẹ awọn agbesunmọmi lagbegbe wọn ati ninu igbo.
- Mimu ileri ọtun ṣẹ:
Aarẹ Tinubu kede pe eto ti wa lati gbe ileri ọtun ti wọn fi polongo lati wọọdu kan sikeji dide (Renewed Hope Ward Development Programme.)
Afojusun rẹ lori eyi bo ṣe wi, ni lati jẹ ki o kere tan, miliọnu mẹwaa ọmọ Naijiria, jẹ anfaani ironilagbara kaakiri wọọdu 8,809 to wa lorilẹede yii.
- Agbara Naira
Nipa bi agbara owo naira ṣe to ni ọja ilẹ okeere, Aarẹ Tinubu sọ pe $45.4 billion lo duro si titi di ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kejila ọdun 2025,
O ni eyi ṣi fọkan balẹ bi ohunkohun ba ṣẹlẹ lẹka naa.
O fi idaniloju sọ pe nnkan kan ko ni i yingin ni 2026 lẹka owo yii, yoo tubọ lagbara si i ni.
- Ọwọngogo ọja ati owo ori dinku
Bi owo ori awọn ọja ṣe walẹ, ti ele ori ọja naa si wa ni odiwọn to yẹ, Tinubu sọ pe ijọba oun ni ireti pe yoo ran idokoowo lọwọ, nnkan amayedẹrun ati idagbasoke yoo si pọ si i.
- Gbigbe ogun ti asanju owo ori
Aarẹ Tinubu tun kede pe ijọba oun yoo koju awọn ti wọn maa n mu ki araalu sanwo ori ju bo ṣe yẹ lọ lẹka ijọba kaakiri.
O gboriyin fun awọn ipinlẹ to ti n ṣamulo ilana owo ori to yẹ, eyo to din owo ti araalu ati awọn olokoowo n sanku.
" Ọdun tuntun yii jẹ abala to ṣe pataki lati ṣe amulo ofin owo ori tuntun, ti a ba jọ gba a wọle, yoo ran bi owo ṣe n wọle lọwọ, ṣe atunṣe sibi to yẹ, yoo si tun ro Naijiria lagbara lati pese nnkan amayedẹrun ati awọn eto awujọ."
- Lilo iṣẹ ọgbin, okoowo, iwakusa fun iranlọwọ awọn eeyan lẹsẹkuku
Gẹgẹ bi Aarẹ Tinubu ṣe wi, iṣẹ ọgbin, okoowo, ipese ounjẹ ati iwakusa yoo jẹ ijọba logun lọdun yii, lati pese iṣẹ fun awọn araalu lẹsẹkuku.
- Ipese ọna, ina mọnamọna, papakọ ofurufu ati ti ebute omi, reluwee, eto ilera ati bẹẹ bẹẹ lọ ti ijọba ti n ṣe tẹlẹ lo ni awon yoo tun tẹpẹlẹ mọ ni 2026, lati mu aye dẹrun fun araalu.
Aarẹ Tinubu wa rọ awọn ọmọ Naijiria lati gba iṣọkan laaye, ki wọn nifẹẹ orilẹede yii, ki wọn si ma ṣe da iṣẹ ilu da ijọba lọdun tuntun.
Tinubu sọ pe mimu orilẹede duro ṣinṣin ki I ṣe iṣẹ ẹnikan ṣoṣo, bi ko ṣe pe agbajọ ọwọ la fi n sọya lo ba de.














