Ọwọ́ tẹ afurasí mẹ́rìn lórí ikọlù tó mú ẹ̀mí èèyàn 115 lọ́ ní Russia-Ààrẹ Putin

Oríṣun àwòrán, AFP
Aarẹ orileede Russia, Vladimir Putin ti kede pe ọwọ awọn agbofinro ti tẹ awọn eeyan mẹrin kan to lọwọ si ikọlu to waye ni orileede naa lọjọ Abamẹta.
Lasiko to n ba raalu sọrọ lori ẹrọ amohunmaworan lo ti kede ọrọ yi to si ni wọn wa ni ahamọ bayii.
Eeyan marundinlọgọfa ni Aarẹ sọ pe o ti padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ yi to si fi kun pe awọn mẹrin ti ọwọ tẹ yi n gbiyanju lati sa lọ si Ukraine ki ọwọ to ba wọn.
Putin sọ pe iwadii ibẹrẹ fi han pe awọn eeyan kanlati apa Ukraine ṣetn lati faaye gba wọn lati ṣoda si odi keji.
Ṣaaju asiko yi ni ileeṣẹ Aarẹ tii ṣe Kremlin ti sọ pe ahesọ ni pe Ukraine lọwọ ninu ikọlu yii.
Bakan naa ni aarẹ Putin kede ọjọ Kẹrindinlogun oṣu Kẹta gẹgẹ bi ọjọ idaro.
O ni aimọye awọn ti ko mọwọ mẹsẹ lo farakasa ikọlu Crocus ọhun.
O fikun pe gbogbo awọn to lọwọ ninu iṣẹlẹ buruku yi ni awọn yoo ṣawari ti wọn yoo si jẹyan wọn niṣu.
O ṣapejuw ikọlu yi gẹgẹ bi ''iwa awọn agbesunmọmi ti ko bikita'' ati pe awọn to ṣe ikọlu yi ''ko ni mu ipinya wa laarin wa''

Èèyàn 93 kú, ọ̀pọ̀ farapa báwọn agbébọn ṣe síná ìbọn bolẹ̀ níbi ayẹyẹ ní Russia

Kò dín ní èèyàn àádọ́rùn-ún tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn níbi ètò ayẹyẹ kan ní orílẹ̀ èdè Russia bí àwọn agbébọn ṣe síná ìbọn bolẹ̀ níbẹ̀.
Iléeṣẹ́ ètò ààbò Russia tó fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ ní ènìyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún ló tún farapa nínú ìkọlù ọ̀hún.
Bákan náà ni wọ́n ní ó ṣeéṣe kí ẹ̀mí èèyàn tó máa bọ́ tún lékún si gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìgbìmọ̀ tó ń ṣe ìwádìí ìkọlù náà ṣe sọ.
Fídíò kan tí BBC ṣàgbéyẹ̀wò rẹ̀ ṣàfihàn àwọn ọkùnrin mẹ́rin tí wọ́n wọ aṣọ ológun tí wọ́n sì ń dáná ìbọn yá àwọn ènìyàn ní Krasnogorsk.
Ètò ayẹyẹ orin kíkọ ló fẹ́ wáyé ní gbọ̀ngán Crocus City Hall kí àwọn agbébọn náà tó ya wọ ibẹ̀, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní yìnbọn bá àwọn ènìyàn.
Ní alẹ́ ọjọ́ Ẹtì ní ìkọlù náà wáyé.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Wọ́n ní àwọn ọmọdé wà lára àwọn tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ.
Èèyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ló wà nínú gbọ̀ngàn Crocus City Hall tí àwọn ẹgbẹ́ olórin Picnic ti fẹ́ ṣeré kí ìkọlù náà tó wáyé.
Ẹni tí ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ṣojú rẹ̀ kan sọ fún BBC pé ó kù díẹ̀ kí ètò orin kíkọ náà bẹ̀rẹ̀ ni àwọn agbébọn náà ṣíná ìbọn bolẹ̀.
Àwọn ikọ̀ olorin Picnic kò farapa gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́.
Iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù náà, tí wọ́n sì ní ìwà ìgbéṣùmọ̀mí ló wáyé níbẹ̀.
Ìròyìn tí a kò lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ kan lórí ayélujára ní àwọn ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí Islamic State ní àwọn ni wọ́n wà nídìí ìkọlù ọ̀hún.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ìjọba orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ní àwọn ti sọ fún Russia tẹ́lẹ̀ pé àwọn agbéṣùmọ̀mí ń gbèrò láti ṣe ìkọlù sí orílẹ̀ èdè náà, tí àwọn sì ti ṣe ìkìlọ̀ fún wọn láti yàgò fún àpéjọ elérò púpọ̀.
Iléeṣẹ́ ológun ní àwọn ti ìwádìí láti nawọ́ gán àwọn tó ṣiṣẹ́ láabi yìí.
Ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn ni Amẹ́ríkà ti kìlọ̀ fún àwọn òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ Amẹ́ríkà tó wà ní Russia láti yàgò fún àpéjọ ńlá nítorí àwọn ń gbọ́ fìnfìn pé àwọn agbéṣùmọ̀mí fẹ́ ṣe ìkọlù sí orílẹ̀ èdè Russia.
Russia ni àwọn mẹ́rin nínú àwọn mọ́kànlá tí ọwọ́ àwọn agbófinró ti tẹ̀ ni ìrètí wà pé mẹ́rin nínú wọn jẹ́ afurasí agbéṣùmọ̀mí tó ṣe ìkọlù náà.















