A máa ń ta ẹ̀kú eégún kan ní N400,000, Alaran Egba ṣàlàyé èèwọ̀ tó rọ̀ mọ́ ẹ̀kú eégún rírán

Àkọlé fídíò, A máa ń ta ẹ̀kú eégún kan ní N400,000, Alaran Egba nípa ẹ̀kú eégún rírán
A máa ń ta ẹ̀kú eégún kan ní N400,000, Alaran Egba ṣàlàyé èèwọ̀ tó rọ̀ mọ́ ẹ̀kú eégún rírán
Aworan Oloye Idowu Babatola

Oloye Idowu Babatola, Alaran Ẹgba ti i ṣe Oluwo ilu Aibo nipinlẹ Ogun ti n ran ẹku egungun fun bi ogoji ọdun.

Oloye Babatola ṣalaye pe o maa n to oṣu meji si mẹta ti oun maa n lo lati ran ẹku eegun kan tan.

''A maa n ta ẹku eegun kan to ẹgbẹrun lọna irinwo naira, N400,000.

Eewọ to wa nibẹ ni pe iyawo tabi ọmọbinrin wa ko gbọdọ wa nibi ti a ba ti n ran ẹku egungun,'' Oloye Babatola lo sọ bẹẹ.

Alaran Egba ni ''aṣọ ofi gbajumọ ninu aṣọ ti a maa fi n ran ẹku eegun, lẹyin naa ni aṣọ aran.

Ti a ko ba ri ofi ati aran ni a maa n lo leesi tabi ankara, amọ, ofi ati aran lo dara ju fun aṣọ eegun riran.

Bi ooru kii ṣe mu egungun ninu ẹku ni pe ti o ba kudiẹ ki egungun gbe ẹku yẹn wọ, ẹmi eegun maa ti wa lara rẹ eyi to maa mu un yatọ si bo ṣe wa tẹlẹ gẹgẹ bi eeyan lasan.

Ooru ko le mu un tori o di oriṣa.''

Oloye Babatola fikun ọrọ rẹ pe ''eegun ti waye gẹgẹ bi eeyan tẹlẹ ri.

Awọn naa ti logba wọn, koda, eegun de ade l’Oyo gẹgẹ bi eeyan.

Eegun jọba niluu Oyo gẹgẹ bi eeyan ṣugbọn o ti lọ.

Ami Jesu ni agbelebu, ami Anabi ni oṣupa ti wọn n ya si mọṣalaaṣi, ami eegun ni eyi ti a n gbe kiri,'' Alaran Egba ṣalaye.

Oloye Babatola tun sọ pe ''idi ti eegun fi maa n mu ẹgba lọwọ ni pe o ni lati jẹ oriṣa to maa ja eeyan laya.''