Ẹ bẹ̀rẹ̀ síí kò owó dọ́là tí o wà ní ìpamọ́ síta bí bẹ́ẹ̀ kọ́...Oluwo figbe ta

Aworan Oluwo Ilu Iwo

Oríṣun àwòrán, Facebook/Hope for Iwo

Oluwo ilu Iwo Oba Abdulrosheed Adewale Akanbi ti di ẹbi ọwọngogo paṣiparọ owo Naira orileede Naijiria si dọla ti ilẹ Amẹrika ru awọn ọmọ Naijiria to n ko owo naa pamọ.

O wa tori rẹ parọwa si awọn to n ko dọla pamọ lati fi ifẹ orileede wọn han nipa tita dọla ti wọn ko pamọ ki wọn si da pada si owo Naira.

O ṣalaye ọrọ yi ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin.

Oriade naa ṣalaye pe ti dọla ba wa nit abo ṣe yẹ, eyi yoo fa iye owo paṣiparọ rẹ si Naira walẹ.

O fikun pe ṣiṣe bẹẹ yoo si mu ki ọwọngogo nkan tawọn ọmọ Naijiria n koju di afisẹyin ti eegun n fiṣọ.

Ẹ bẹru atubọtan ẹyin tẹ n ko dọla pamọ!

Lẹnu ọjọ mẹta yii, ọrọ paṣiparọ owo Naira si dọla jẹ nkan to n kan ọpọ lominu lorileede Naijiria.

Idi si ni pe iye owo ọja lọpọ igba ni awọn ọlọja so mọ lilọ soke tabi wiwalẹ dọla si Naira.

Oluwo sọ pe awọn to n ko dọla pam lo n mu inira bae to ọrọ aje Naijiria.

O tẹsiwaju pe pupọ awọn olowo Naijiria lo lọwọ ninu iru iwa yi to si parọwa si wọn lati ko dọla to wa ni ipamọ sita.

‘’Mo n parọwa si awọn ọmọ Naijiria paap julọ awọn olowo to n ko dọla pamọ.Mo fẹ ki wọn ko sita ki wọn si parọ rẹ si Naira lọna ati fi ifẹ ti wọn ni si orileede Naijiria han.Awọn to n ko dọla pamọ lo jẹ ko dabi ẹni pe ko si dọla nita.’’

Mo ti ko gbodo dọla to wa ni akoto mi sita

Oluwo ṣalaye pe oun gaan alara ti ko gbogbo dọla to w ani akoto oun sita ti ko si si nkankan nibẹ mọ.

O ni ‘’aṣeyọri wa ko le waye ayafi ti a baa ṣe ifarajin ki a si jawọ ninu awọn iwa ti yoo fun okun mọ ọrọ aje wa lọrun’’

O wa kesi awọn ọmọ Naijira lati maa ra nkan ti a ba fi ọwọ arawa ṣe ni Naijiria .

O sọ pe oun ni akọkọ oriade ti yoo ra ọkọ lọwọ ileeṣẹ Innoson to n pese ọkọ ni Naijiria .

‘’Awọn aṣọ ọryun mi paapa awọn ofi ti mo n wọ, Naijiria nibi la ti n pese wọn’’

O ni ti ipolongo to peye ba wa, eto ọrọ aje Naijiria yoo gunrege.