Ìyá ìbejì Twinz Love sá bá ọkọ míì lọ sí Ibadan, ó bímọ kùnrin síbẹ̀ ló fa ìpínyà wa - Baba Ibeji
"Ìyá ìbejì kúrò nílé fún oṣù méjì, tá à mọ ibi tó wa, kò fi mí lọ́kàn balẹ̀ rárá"

Yoruba ni eti to ba gbọ alọ, lo yẹ ko gbọ abọ.
Bẹẹ ba gbagbe, laipẹ yii ni BBC Yoruba mu fidio kan wa fun yin nipa ifọrọwerọ wa pẹlu obinrin kan, arabinrin Adeyinka Oladimeji.
Oun si lo bi ibeji adẹrinposonu ti orukọ wọn n jẹ Doyin ati Moyin Oladimeji, ti wọn jẹ Twinz Love lori ayelujara.
Ninu ifọrọwerọ naa si ni mama ibeji ti salaye awọ ilakọja to ni lasiko to n tọju awọn ọmọ naa, bi ọkọ rẹ se ni ko gbe awọn ọmọ naa silẹ niwaju ile olowo kan ati bi baba ibeji naa se salọ kuro nile ti wọn n gbe.
Lẹyin ọsẹ meji ta gbe fidio naa sita, ni Baba awọn ibeji yii kan si BBC Yoruba lati sọ alaye tiẹ lori awọn ẹsun ti Iya ibeji fi kan an.
Amọ Yoruba ni agbọ ẹjọ ẹnikan da, agba osika ni nitori o yẹ ka wadi ohun gbogbo daju, ka si di eyi tii se otitọ mu.
Alaye ree lori bi emi ati Adeyinka, mama Ibeji se pade, ta fi fẹra wa – Sunday Oladimeji
Pasitọ Sunday Oladimeji, to jẹ Baba Ibeji sọ fun BBC Yoruba pe osu February 1998 ni awọn pade ara awọn nilu Akure, ni adugbo ti awọn mejeeji dijọ n gbe, ti awọn si se ayẹyẹ mọmi n mọ ọ nilana idana tilẹ Yoruba lẹyin osu mẹrin.
Baba Ibeji, tii se ọmọ bibi ilu Ila Orangun amọ to ti di ojisẹ Ọlọrun bayii nilu Akure fikun pe lẹyin osu kan ti wọn se idana iyawo ni Adeyinka loyun, to si fi bi ibeji obinrin meji.
O ni Ọgbọnjọ osu kẹta March ọdun 1999 ni obinrin naa bi awọn ibeji yii, ti awọn si se isọmọ lorukọ, sọọsi iya Arẹmọ si ni awọn n lọ nigba naa.
Baba Ibeji ni ọpọ eeyan pupọ lo peju sibi ayẹyẹ isọmọlorukọ awọn ibeji naa nitori se ni ẹnu n ya gbogbo eeyan pe oun Oladimeji bi meji.

Oríṣun àwòrán, Sunday Oladimeji
‘Eeyan lile ni iya ibeji, o maa n ja kiri inu ile ni’
Nigba to n salaye iru ajọsepọ to wa laarin oun ati iya ibeji ati iru ẹni to jẹ, Oladimeji ni eeyan lile ni iya ibeji naa ati pe onijagidijagan ni.
O ni kii gbọ, kii gba ni Adeyinka, ti ko si pe osu mẹrin ti awọn bi ibeji, ti mama onile fi ni ki awọn ko kuro ninu ile naa.
“Mama onile naa wa laye bayii o, o ni ka kuro nile tori wahala iyawo mi ti pọ ju, yara meji ninu ile kọjusimi ki n kọjusiọ si la n gbe.
Bi awọn tẹnanti yoku ta jọ n gbe ile ba n ja, iyawo mi ni yoo fi ọlọpaa mu wọn, yoo ti wọn mọle, ibi ti wahala yẹ ti bẹrẹ niyẹn.
Bi wọn ba n ja, yoo fi tiẹ si, idi si ree ta fi kuro ninu ile mama naa, ta si tun lọ gba ile miran.”

Oríṣun àwòrán, Sunday Oladimeji
“Awọn ibeji pe osu mẹjọ ni iya wọn kọkọ lọ kuro nile, mama mi si ko wọn lọ si Ila”
Oladimeji tẹsiwaju pe onisẹ ọwọ atọkọse Panel Beater ni oun amọ iya ibeji ko sisẹ kankan nigba naa.
O ni nigba ti awọn ibeji pe osu mẹjọ pere lọdun 2000 ni mama wọn ti n gbe awọn ọmọ naa si ibudo itọju ọmọde, ta mọ si Day Care.
Oladimeji ni iyawo oun jade lọ fun ọjọ meje lai pada wale, to si ko awọn ọmọ silẹ nigba to ni oun fẹ lọ si ile ẹkọ Gbogbonse Poly Offa.
Baba Ibeji ni asiko yii ni mama oun wa bẹ awọn wo, nigba ti wọn si duro bii ọjọ meji si mẹta, wọn ko ri iya ibeji, to si de ni ọjọ keje to ti kuro nile.
“Ni kete to de, ko dahun ibeere ti mo n bi pe ibo lo lọ, amọ se lo tun wọ sokoto, to tun jade nile, ti ko si tun pada wa sile wa sun.
Nigba ti mama mi si ri bi mo ti n se wahala, wọn ba ko awọn ibeji lọ sile wọn ni Ila.”
“Iya ibeji kuro nile fun osu meji lọ sọdọ ọkọ mii to ni ni Ibadan”
Baba ibeji tẹsiwaju pe nigba ti iya ibeji pada sile, o n bẹbẹ ni titi ti oun fi sọ fun mama oun pe ki wọn ko ọmọ fun.
O ni lẹyin eyi, iyawo oun le jade lọ lati aarọ titi di alẹ tabi ko ma wale fun odidi ọjọ mẹta.
“Lọjọ kan ta n mura lati lọ si sọọsi lọjọ Sunday lọdun 2021, ni iya ibeji ni oun tun fẹ lọ si irin ajo, bo se lọ, ti a ko ri mọ niyẹn fun osu meji.
Lẹyin osu meji, nigba ti wahala itọju wọn pọ fun mi, mo ko awọn ọmọ lọ sọdọ mama mi.
A se Ibadan lo lọ, o ti ni oju tuntun ni Ibadan, ohun to fi de Ibadan di oni niyẹn, mo ro pe o lọ haaya ile sibẹ ni.
Nigba to pada de, o lọ si Ila lati lọ beere ọmọ rẹ, amọ mo ni wọn ko gbọdọ ko ọmọ fun.
A maa n pade nile ẹkọ awọn ọmọ, yoo wa lati Ibadan, emi yoo wa lati Ila, a si dijọ n tọju awọn ọmọ yii.
Sugbọn ko ni asiko pe ko duro tọju awọn ọmọ yii fun isẹju kan.”

Oríṣun àwòrán, Sunday Oladimeji
“Wọn ba emi ati mama ibeji pari ija, mo si ni maa fẹ pada”
Sunday Oladimeji ni nigba to ya, wọn pe awọn mejeeji lati ba wọn pari ija, ti wọn si bi oun pe se oun si le fẹ iytawo oun pada, ti oun si ni oun yoo fẹ.
Asiko yii naa ni wọn sọ pe kawọn se igbeyawo nitori mọmi n mọọ lasan ni awọn se tẹlẹ, to fi ko wa sile.
“Ase mo n tan ara mi jẹ ni, o de lọjọ naa, o ni ka ko ọmọ wa si Akure, ọkan kan ati osu mẹta si ni awọn ọmọ lo lọdọ mama mi.
O maa n lọ si Ibadan ni osoosu, nigba to ya mo ni ko maa ko bọ wa si Akure, ibi ti ija ti bẹrẹ niyẹn.
“Iya Ibeji ko ọmọ ati ẹru mi lọ titi di oni”
Nigba to di 2005, Oladimeji ni iya ibeji tun sọ fun oun pe oun fẹ rinrin ajo, ti oun si ni ko le lọ, amọ nigba ti oun jade lọ, iya ibeji ti ko awọn ọmọ rẹ lọ.
“Lẹyin ọsẹ meji, o wa sile, o fọ ilẹkun si meji, o si ko gbogbo ẹsọ ile lọ. Mo si pinnu pe ko maa lọ, nitori o ti n fooro ẹmi mi ju.
Nigba to di 2007, o wa si Akure nile ẹgbọn rẹ, wọn si pe mi amọ se lo n sepe fun mi, n ko fọhun tori epe rẹ ko le mọ mi.
Ẹgbọn rẹ ba wa pari rẹ, mo si fa mọra.’”
Iya Ibeji ti bimọ ọkunrin fun ọkọ miran lọdun 2007 – Baba Ibeji
Sunday Oladimeji ni lasiko ti wọn ba awọn pari ija tan, ni iya ibeji gbe ọmọkunrin kan lọwọ, to si n fun ni ọyan.
“Mo wa bi i pe ta lo ni ọmọ, to si ni oun ti fẹ ọkọ miran, mo si sọ fun pe sebi oun ni oun n duro de lati ọjọ yii, ti oun ko fi fẹ iyawo miran?
Funra ara rẹ lo sọ fun mi pe ki n lọ fẹ iyawo miran, to si ni ki n maa fi owo ransẹ si oun fun itọju awọn ọmọ.
Igba yii ni mo sọ pe ko ba mi ko awọn ọmọ amọ o ni rara, mo si ni ko jẹ ki ohunkohun ti mo ba fun maa tẹ lọrun.”

Oríṣun àwòrán, Sunday Oladimeji
“Iya Ibeji n gbe mi sepe pe owo ti mo fi ransẹ kere”
Baba Ibeji ni oun n san owo si akanti iya ibeji amọ epe lo n fi ransẹ si oun pe owo naa kere.
Lati igba naa si lo ti pa foonu, igbakuugba ta ba si pe e, epe lo maa n sẹ fun gbogbo wa.
Iya ibeji mọ pe n ko sọnu, o mọ ibi to le wa mi si, o wu lo ko awọn ọmọ sa fun mi.”
“2015 ni mo gba isẹ iransẹ, ko si igba kankan ti mo ni ko gbe ọmọ lọ si ile alainiya, irọ ni iya ibeji n pa”
Baba ibeji wa sẹ lori ọrọ ti iya ibeji sọ pe oun wi fun pe kawọn gbe ibeji lọ sile ọmọ alainiya.
O ni ko si oun to jọ bẹẹ rara, irọ lasan ni to si salaye pe epe to n sẹ fun awọn lo mu ki oun fisilẹ.
“Odidi ọdun mẹwa ni wahala iya ibeji fi wa lara mi, mo si sa fun ẹmi mi, kii se pe mo fẹ tọrọ owo lọwọ rẹ, ni mo se sọrọ yii sita.
Bi kii ba se ohun ti ẹyin BBC kọ pe ẹ wa mi, ẹ ko ri mi, lo mu ki n wa sọ tẹnu mi.
Ọlọrun sisẹ agbara rẹ ninu aye mi, mo ti ni sọọsi temi, Ọlọrun si n jẹwọ agbara rẹ.”
‘Ti iya ibeji ba fẹ ki awọn ibeji mọ mi, deede, to ba ni bẹẹ kọ, ko buru’
Nigba ti BBC Yoruba beere lọwọ Baba ibeji pe se o setan lati fa awọn ọmọ rẹ mọra pada, o ni o wu oun ki ifẹ pada bọ sipo, ti iya wọn ba fẹ ko pada.
“Iya ko jẹ mi amọ to ba fẹ ki awọn ọmọ yẹn ri mi, deede, to ba si ni ko ni ri bẹẹ, ko buru.
Eleyi to ba ti wu ni ko se, sebi oun ni agbara wa lọwọ rẹ, ko dẹ si nnkan ta le se si.
Ti mo ba ri wọn, inu mi yoo dun, ayọ mi ni wọn, ayọ mi wọle niyẹn.”







