Ọlọ́pàá Egypt mú ẹni tó dúnàá-dúrà pẹ̀lú àwọn ajínígbé tó dá rélùwéè Kaduna lọ̀nà

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni awọn ọlọpaa lorilẹede Egypt ti fi panpẹ ọba mu Tukur Mamu, to jẹ adari awọn to n duna-dura pẹlu awọn ajinigbe to ko awọn arinrinajo ni oju irin Abuja si Kaduna.

Iroyin ni ilu Cairo to jẹ olu -ilu orilẹede Egypt, ni wọn ti fi panpẹ mu ni ọjọ Iṣẹgun.

Mamu naa ni wọn fi panpẹ ọba mu pẹlu mọlẹbi rẹ nigba ti wọn n lọ fun isẹ Hajj ni Saudia Arabia.

Amọ papakọ ofurufu ni Cairo ni wọn ti fi panpẹ ọba mu, ti ko tii si ẹnikẹni to tii ba sọrọ.

Bakan naa ni ifipanpẹ mu Mamu n waye lẹyin ti oludije sipo igbakeji aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Kashim Shettima sabẹwọ si Mamu ati Gumi ni ipinlẹ Kaduna.

Alaaye ree ta se mu Mamu - DSS

Wayi o, ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS lorilede Naijiria ti kede pe oun ti gbe Mamu wa sorilẹede Naijiria.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun DSS, Peter Afunanya fisita salaye pe lootọ ni oun gbe Mamu, to si ti wa ni ahamọ oun.

DSS ni lara idi ti oun se gbe Mamu ni ko le wa salaye awọn ohun to mọ nipa awọn isẹlẹ ijinigbe to n waye yika orilẹede yii gẹgẹ bi ara iwadi ileesẹ naa to n lọ lọwọ nipa eto aabo Naijiria.

O ni awọn ri ọkunrin naa mu pẹlu iranwọ awọn alajọsepọ awọn nilẹ okeere to wa nilu Cairo.

“A gbe Mamu nitori bi ileesẹ ologun, awọn ọtẹlẹmuyẹ atawọn agbofinro se sọ fawọn alajọsepọ wọn nilẹ okeere pe ki wọn mu Mamu wa silẹ yii.

O si yẹ ko ye awọn ọmọ Naijiria pe ofin gbọdọ sisẹ rẹ.”

‘Inu ijọba ko dun si bi Mamu se n dunadura pẹlu ajinigbe, wọn dunkooko mọ ni‘

Ileeṣẹ iroyin ti Mamu jẹ adari fun, to fi idi ọrọ naa mulẹ ni ara idunkokomọni lati ọdọ ijọba apapọ ni bi wọn ṣe fi panpẹ ọba mu.

Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Ibrahim Mada ni ijọba apapọ Naijiria lọwọ ninu bi wọn ṣe mu ẹni to n dunna-dunra naa.

‘’Gbogbo ipa ti Mamu n sa lati ri pe wọn doola ẹmi awọn to wa ni panpẹ awọn ajinigbe ni ijọba apapọ Naijiria ko fi ọwọ si rara.’’

‘’N ṣe ni wọn n dunkoko mọ, ti wọn si n ba orukọ rẹ jẹ ni gbogbo igba.’’

‘’Bakan naa, kii ṣe igba akọkọ niyii ti arakunrin naa yoo ke gbajare sita pe awọn kan n lepa ẹmi oun fun iṣẹ ilu ti oun n ṣe.’’

Ọjọ kejidinlọgbọn,Oṣu Kẹta ni awn agbebọn naa ṣekọlu si ọkọ oju irin opopona Kaduna si Abuja, ti wọn si ko awọn eniyan to fẹrẹ to irinwo eniyan.

Titi di asiko yii, awọn eniyan to le ni ọgọta ṣi wa ni ahamọ awọn agbebọn, nigba ti awọn miran ti ku.

Amọ ajinigbe ti tu awọn miran silẹ lẹyin ti wọn gba owo idande ẹmi wọn lọwọ ẹbi ati ara.