Ọ̀pọ̀ ọlọ́pàá ṣe ìwọ́de l‘Osun lórí àjẹsílẹ̀ owó àjẹmọ́nú ọdún kan àbọ̀

Police Constabularies Protest in Osun

Oríṣun àwòrán, @insightlinkstv

Nnkan bii ẹẹdẹgbẹta awọn ọdọ tijọba apapọ gba sisẹ lati kun awọn ọlọpaa lọwọ nipinlẹ Osun, lo ti ṣe ifẹhonuhan.

Alaye wọn ti wọn se n fi honu han ni pe ijọba apapọ jẹ awọn lowo oṣu ọdun kan abọ.

Awọn olufẹhonuhan naa tun sọ pe, awọn ọlọkada ti fẹ ẹ gba iyawo awọn tan nitori owo ti ko si lọwọ awọn.

Lara awọn agbegbe ti wọn ṣe ifẹhonuhan naa de ni Oke-fia titi de afara Olaiya niluu Osogbo.

Wọn ni awọn ko tii gba owo kankan lati igba ti wọn ti pari idanilẹkọọ wọn loṣu Karun un, ọdun 2021.

"Awọn ọlọkada ati onimaruwa lo n fẹ iyawo wa nitori pe a ko ni owo lọwọ"

Lara awọn olufẹhonuhan naa gun alupupu, ti wọn si gbe awọn kaadi kan lọwọ pẹlu oniruru akọle bii “Ẹ san owo oṣu wa,”

“Awọn ọlọkada n ba iyawo wa lopọ,” ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Wọn ni nitori airi owo fi silẹ nile, lo mu ki awọn ọlọkada atawọn awakọ Maruwa maa gba iyawo wọn.

Awọn ọlọpaa naa wa rawọ ẹbẹ si ijọba lati san gbogbo owo to jẹ wọn.

Police Constabularies Protest in Osun

Oríṣun àwòrán, @MEzeaka

‘Mẹta ninu wa lo ti ku ṣẹnu iṣẹ’

Awọn ọlọpaa naa fi kun pe ko din ni mẹta lara awọn ti ẹmi wọn ti sọnu lẹnu isẹ naa.

Ọkan lara wọn, Tijani Olawale sọ fun awọn akọroyin pe “A ti lọ si ijọba ibilẹ lati ba awọn ọnarebu atawọn ti ọrọ naa kan sọrọ.

Amọ wọn ko ri nnkan ṣe si ọrọ wa.

“Eeyan mẹta lara wa ni wọn ku lẹnu iṣẹ yii ni Ikire, bẹẹ ni a padanu ẹnikan ni Iree.”

Ẹ n doju ti ileesẹ ọlọpaa pẹlu iwọde yin - Kọmisana ọlọ́paa l‘Osun

Nigba to n da si ọrọ naa, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Osun, Adewale Olokode paṣẹ fun awọn oluwọde naa lati dẹkun ifẹhonuhan naa.

Olokode wa ṣeleri pe awọn ti ọrọ naa kan yoo bujuwo ọrọ ọhun.

O ni “Ẹ n doju ti ileeṣẹ ọlọpaa pẹlu iwọde yin yii ni, n ṣe lo yẹ ki ẹ gbe ẹhonu yin gba ọna totọ.

Ṣe ni ẹ n da alaafia ilu ru bi ẹ ṣe n wọde.”

Ti ẹ ko ba gbagbe, irufẹ iwọde yii ti kọkọ waye ni ipinlẹ Kwara ninu oṣu kẹjọ, ọdun yii.

Ijọba ipinlẹ lo gba awọn ọlọpaa yii, wn ko ni iwe igbanisisẹ - Adejobi

Amọ agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Olumuyiwa Adejobi sọ fun awọn akọroyin pe ọrọ naa ko kan awọn rara.

Adejobi ni ijọba ipinlẹ lo gba awọn eeyan naa fun aabo ilu, ijọba apapọ ko si fun wọn ni iwe igbanisiṣẹ kankan.

Ọlọpaa ni iṣẹ naa ko yọ owo, nitori n ṣe lawọn eeyan naa gba lati fi ara wọn jin fun abi ilu.