'Akẹ́kọ̀ọ́ 15,000 yóò fojú balé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn yíyí ìwé ìgbaniwọlé sílé ẹ̀kọ́ gíga kí wọ́n lè kópa nínú ìsìnrúùlú NYSC'

Oríṣun àwòrán, Facebook
Ọga agba fun ajọ Jamb lorilẹede Naijiria, Ọjọgbọn Is-haq Oloyede ni ajọ naa ti ṣawari akẹkọọ ẹgbẹrun lọna mẹẹdogun ti wọn yi iwe ẹri igbaniwọle wọn si ile ẹkọ giga lati le ni anfani lọ fun iṣẹ agunbanirọ NYSC.
Oloyede ni ajọ naa ti bẹrẹ lati maa gbe awọn ti ọwọ tẹ fun ẹsun yiyi iwe ẹri naa lọ si ile ẹjọ.
Ọrọ yii jade nigba ti Ọjọgbọn Oloyede n sọrọ nibi ipade awọn agunbanirọ kan to waye niluu Abuja.
O tẹsiwaju pe igbakeji ọga fasiti (DVC) mẹtadinlogun, igbakeji akọwe fasiti, to fi mọ oṣiṣẹ Jamb mẹrin lo wa ni ahamọ ajọ ICPC bayii lori ẹsun pe wọn lọwọ ninu yiyi iwe.
O sọ pe "Lọjọ kan, mo sa wa ba ọga yin, (o n ba ọga ajọ NYSC sọrọ) nitori n ko gbagbọ pe akẹkọọ ẹgbẹrun mẹdogun le yi iwe igbaniwọle wọn.
"Bi mo ṣe n ba yin sọrọ yii, igbakeji ọga fasiti (DVC) mẹtadinlogun, igbakeji akọwe fasiti, to fi mọ oṣiṣẹ Jamb mẹrin lo wa ni ahamọ ajọ ICPC bayii lori ẹsun pe wọn lọwọ ninu yiyi iwe.
"Mo fẹ gbayin ni imọran: ẹ ri pe ẹ tẹle ofin ki ẹ ma ba ni wahala. Mo n rọ yin ki ẹ gba ọna to yẹ, ẹ wa ri pe ọpọ wahala to n waye lo jẹ afọwọfa."
Nigba to n sọrọ, Ọga agba fun NYSC, Brig.-Gen. Olakunle Nafiu, rọ awọn ti ọrọ kan pe ki wọn dẹkun gbigba ọna eru fi ko awọn akẹkọọ wọle tabi ki wọn ri ijiya ofin.
DG ni otitọ ni pe awọn n koju ọpọ ayederu iwe ẹri ni NYSC ṣugbọn ọpọ wọn ni ṣawari latara iwadii finifini.
O ni ''a mọ pe iṣẹ wa ni ki a ṣe amojuto bi awọn akẹkọọ jade ile ẹkọ giga yoo ṣe lọ agunbanirọ, ti a si n se igbaradi fun ọdọ lati wulo fun orilẹede Naijiria.
"Fun ọpọ ọdun bayii, NYSC ni ọpọ iyi lawujọ fun iṣẹ ti wọn n ṣe, ti a ko si ni faye gba ki awọn eeyan kan tabuku wa bayii."















