Wo ìdí tí iléeṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS fi yọ òṣìṣẹ́ 115 bí ẹní yọ jìgá

Aworan asia ajọ DSS ati aworan awọn ti wọn gba iṣẹ lọwọ wọn

Oríṣun àwòrán, DSS

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ lorilẹede Naijiria, DSS ti kede pe awọn ti gba iṣẹ lọwọ oṣiṣẹ 115, ti wọn si kilọ fun awọn araalu nipa biba eyikeyi ninu wọn tabi ẹnikẹni to ba n pe ara rẹ ni oṣiṣẹ ileeṣẹ dowopọ.

Ajọ DSS sọ eyi loju opo X rẹ lọjọ Isẹgun, pe igbesẹ yii waye lati se atunṣe si ajọ naa lati inu wa.

Bo ti lẹ jẹ pe ajọ DSS ko ṣalaye idi ti wọn fi gba igbesẹ yii ṣugbọn asiko ti iṣẹlẹ yii waye ti fa ọpọ ariyanjiyan niluu Abuja.

Bakan naa ni DSS ni awọn fi oju awọn eeyan naa han sita nitori wọn si n dibọ gẹgẹ bii oṣiṣẹ ajọ DSS.

Ki nidi ti DSS fi gbaṣẹ lọwọ wọn?

Igbesẹ yii ni waye lẹyin ti iṣẹlẹ iditẹgbajọba kan fẹ waye, eyi ti ijọba dena, ti wọn si ti ọpọ awọn ologun to wa nidi rẹ mọlẹ.

Ọpọ lo gbagbọ pe igbesẹ ajọ DSS le wa lara igbiyanju iṣejọba Aarẹ Tinubu lati tun ṣe afikun eto aabo lorilẹede Naijiria.

"Lara awọn atunṣe si ajọ DSS, a n sọ fun araalu pe a ti gba iṣẹ lọwọ apapọ eeyan 115, ti wọn ko si ni ajọsepọ kankan pẹlu ajọ DSS mọ.

DSS tun jẹ ko di mimọ pe awọn ko ni ajọsepọ kankan pẹlu awọn eeyan kan ti wọn pe orukọ wọn ni Barry Donald ati Victor Onyedikachi Godwon, ati pe awọn eeyan kan ti wọn ko ki n ṣe oṣiṣẹ DSS si n pe ara wọn oṣiṣẹ ajọ lati fi lu araalu ni jibiti.

"A n gba araalu ni imọran pe ki wọn yago ninu biba awọn eeyan yii dowopọ nitori wọn ko ba wa siṣẹ mọ," DSS sọ.

Gbogbo orukọ awọn eeyan ti wọn gba iṣẹ lọwọ wọn ni wọn tig be orukọ wọn soju opo ayelujara ajọ naa.

Ṣaaju ni DSS kede sita pe awọn gba iṣẹ lọwọ awọn oṣiṣẹ meji, Barry Donald ati Victor Godwin, ti ọwọ tẹ fun ẹsun iwa jibiti.

Ajọ DSS wa rọ araalu pe ki wọn ma ṣe foya, ki wọn si tun bọ fi iṣẹlẹ ti wọn ba fura si pe o le ṣe akoba fun alaafia ransẹ si ajọ naa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post