CAF ní kí akọ́nimọ̀ọ́gbá Senegal san fáìnì N139m, kede faini N278m fún Morocco lórí awọn ọmọ tó fẹ́ jí aṣọ ìnujú Mendy

Akọnimọọgba Senegal Pape Thiaw ati Sadio Mane di ife ẹyẹ AFCON 2025 mu, rẹfiri fi fere bọnu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ajọ CAF to n ṣakoso ere bọọlu nilẹ Afirika ti paṣẹ pe ki akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Senegal, Pape Thiaw, san faini miliọnu 139 ($100,00) gẹgẹ bi ijiya fun ihuwasi rẹ ninu ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije AFCON 2025.

CAF ni Thiaw jẹbi ẹsun wi pe o tabuku ere bọọlu nigba to ni kawọn agbabọọlu Senegal kuro lori papa lẹyin ti rẹfiri fọn fere wi pe ki Morocco to jẹ alatako Senegal gba pẹnariti.

Ede-ai-yede ṣẹlẹ ni papa iṣere ilu Rabat lọjọ kejidinlogun oṣu Kinni ọdun yii nigba tawọn agbabọọlu Senegal binu kuro lori papa pe awọn o gba bọọlu mọ lẹyin ti rẹfiri fun Atlas Lions Morocco ni pẹnariti.

Inu bi akọnimọọgba Thiaw wi pe rẹfiri tete fọn fere rẹ nigba ti Ismaila Sarr gba goolu kan sawọn fun Senegal lati sọ pe oun ko gba goolu naa wọle.

Ọpọ lo gbagbọ wi pe idi niyi ti Thiaw fi sọ fawọn agbabọọlu rẹ wi pe ki wọn kuro lori papa nigba ti rẹfiri fun Morocco ni pẹnariti lasiko ti ifẹsẹwọnsẹ naa ti fẹ pari.

Ko din ni iṣẹju mẹtadinlogun ti wọn fi da ifẹsẹwọnsẹ naa duro ki Sadio Mane to bẹ awọn akẹgbẹ rẹ wi pe ki wọn pada sori papa lati pari ere bọọlu ọhun.

Lẹyin o rẹyin, Brahim Diaz, to gba pẹnariti paneka sọ pẹnariti naa nu tori aṣọle Senegal Edouard Mendy mu pẹnariti naa.

Ni kete to ju pẹnariti ọhun nu tan ni rẹfiri fọn feere pe ere bọọlu naa ti pari fun iṣẹju aadọrun.

Amọ, lẹyin akoko yii ni wọn tun gbayo fun ọgbọn iṣẹju mii nibi ti Pape Gueye Senegal ti gba goolu kan wọle ti wọn si gba ife ẹyẹ naa.

Ajọ CAF tun fofin de Thiaw wi pe ko gbọdọ dari ẹgbẹ agbabọọlu Senegal fun ifẹsẹwọnsẹ marun un.

CAF tun fofin de agbabọọlu Senegal meji, Iliman Ndiaye ati Sarr wi pe wọn o ni kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ meji tori ihuwasi wọn si rẹfiri.

CAF kede faini N278m fun Morocco lori awọn ọmọ to fẹ ji aṣọ inuju goli Senegal

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ajọ CAF tun kede faini $100,000 fun agbabọọlu Morocco, Ismael Saibari, fun ipa toun naa ko ninu wahala to ṣẹlẹ lasiko aṣekagba idije AFCON 2025.

Bakan naa ni CAF tun kede pe Saibari ko ni kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta.

Gbajugbaja agbabọọlu Morocco, Achraf Hakimi, naa gba ibawi tiẹ, ajọ CAF ni ko ni kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ meji.

Ẹwẹ, igbimọ olubawi ajọ CAF yi ẹbẹ ajọ to n ri si ere bọọlu ni Morocco, FRMF, danu.

Awọn faini ti CAF fun akọnimọọgba Senegal ati agbabọọlu mẹrin ko ni ohunkohun ṣe pẹlu igbaradi fun idije ife ẹyẹ agbaye ti yoo waye ni Amẹrika, Canada ati Mexico.

Ajọ CAF tun kede pe ajọ elere bọọlu Morocco FSF yoo tun san faini $600,000 lẹyin ti wọn jẹbi ẹsun ṣiṣe ilodi si alakalẹ ajọ CAF.

Owo ti ko din ni N278m ($200,000) ni CAF kede wi pe ajọ FRMF Morocco yoo san fun bawọn ọmọdẹkunrin to n ṣa bọọlu ninu papa iṣere ṣe gbiyanju lati ji tawẹnu goli Senegal gbe lọ.

Morocco yoo tun san $100,000 fun bawọn agbabọọlu Atlas Lions atawọn olukọni wọn ṣe ya wọ inu ile awọn to n lo ẹrọ VAR.