"Ìtọ̀ ara mi ni mo mu fún ọjọ́ mẹ́jọ nínú igbó lẹ́yìn tí mo sá máwọn ajínigbé lọ́wọ́"

Awọn janduku agbebọn faṣọ dudu bo imu pẹlu ibọn lọwọ wọn

Oríṣun àwòrán, AFP

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọkan lara awọn eeyan mọkanla to sa mọ awọn ajinigbe lọwọ niluu Isapa nipinlẹ Kwara, Gbemisola ti sọ pe itọ ara oun loun mu fun ọjọ mẹjọ ninu igbo lẹyin toun moribọ lọwọ awọn ajinigbe.

Arabinrin yii ti awọn araalu rẹ mọ si Iya Bẹskẹ ni awọn ajinigbe ji gbe papọ mọ awọn mẹwaa mii ni ilu Isapa losu kọkanla ọdun to kọja.

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Iya Bẹskẹ sọ pe ti ko si ounjẹ tabi omi ninu igbo toun wa lẹyin ti ori ko oun yọ lọwọ ajinigbe.

Gbemisola sọ pe yatọ si awọn mọkanla ti wọn jọ ko ninu ilu kan naa, awọn eniyan pọ ti wọn ko awọn papọ mọ awọn.

Arabinrin naa ni gbogbo igba ni awọn ajinigbe ọhun maa n jade bi ẹni to n ṣọdẹ lọ lati lọ ji awọn eeyan gbe wa si ibuba ti wọn fi wa si.

Omi ìgò kan ni àwa mẹ́wàá ń pín mu lójúmọ́

Arabinrin Gbemisola ni ''awọn ajinigbe yii maa n jẹ ounjẹ to dara ni ti wọn sugbọn ounjẹ ti ko ni iyọ tabi epo ni wọn n gbe fun awa jẹ.

"Koda omi igo kan ni awa mẹjọ si mẹwaa maa n pin mu lọjọ kan.

Igba ti a bere omi lọwọ wọn, wọn dahun pe, awọn o rowo ra omi nigba ti awọn eniyan wa kọ lati san owo ti awọn n beere fun.

Iya yi pọ to bẹẹ ti gbogbo wa fi pinnu lati sa asala fun ẹmi wa.''

Gbemisola ni awọn to gbọ ede Hausa ninu wa ti kọkọ gbọ ti awọn ajinigbe naa n sọ wi pe, yala bawọn eeyan wa ba sanwo tabi wọn o sanwo, pipa lawọn o pa wa.

O ni eyi lo mu ọkan awọn le wi pe o san kawọn ku bi akọni nibi ti awọn ti n sa asala fun ẹmi awọn ju ki awọn ku bi ojo si ibuba awọn ajinigbe lọ.

Gbemisola sọ pe ''ọna ọtọọtọ ni a gba sa lọ, ki wọn ma baa ri wa mu pada.

A gbera ni nnkan bi ago mọkanla alẹ, mo si n daa rin ninu igbo kijikiji titi di arọ ọjọ keji sugbọn mi o kan ilu kankan.

''Mi o mọ pe bẹẹ ni itọ ṣe maa n koro lẹnu''

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Arabinrin Gbemisola ni ''igba tí ongbẹ gbẹ mi, mo ri ike ọti ẹlẹrindodod kan, inu rẹ ni mo n tọ si ti mo si n mu.

Bi mo ṣe ṣe niyẹn fun ọjọ mẹjọ gbako, mi o mọ pe bẹẹ ni itọ ṣe maa n koro lẹnu.''

Arabinrin Gbemisola sọ pe agara da oun nigba ti oun de aarin kan ti oun o si le tẹ siwaju mọ.

Amọ, o ni ọkunrin Hausa kan to kọja lo foun ni kunnu ati omi toun mu.

O ni boun ṣe mu un tan ni inu rirun gbe oun, nitori inu oun ko fẹ gba nnkankan mọ lasiko yẹn.

Gbemisola ni nigba ti oju oun walẹ, loun tẹsiwaju pẹlu irin ajo oun.

"Mo sa pada ja sinu ilu kan ti wọn ti n sọ ede Hausa ati Yoruba.

Ibẹ ni wọn ti gbami si ile, wọn bami jo ara mi pẹlu omi gbigbona, wọn si fun mi lounjẹ ati aṣọ.

Orukọ ilu naa ni Langta ni ijọba ibilẹ Patigi, ilu yii ni mo ti raye pe ile.''

Ní asiko ti BBC News Yoruba ṣe ifọrọwanilẹwo pẹlu arabinrin yii ni ọjọ kẹtadinlogun osu yii, ko tii dara pọ mọ awọn ẹbi rẹ ni ilu Isapa.

Ṣe ni wọn ṣẹsẹ gbe wa si ilu Ilorin lati Patigi ni.

Iwadii fihan pe oun nikan loku tí wọn n reti ninu awọn mọkanla to sa kuro ni akata awọn ajinigbe.