Àṣírí ohun tó fa aáwọ̀ láàrín ẹbí Bunmi Akinnaanu 'Omije Oju mi' àtàwọn akọrin ẹ̀mí lórí ètò ìsìnkú rẹ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Bunmi Akinnaanu Adeoye/BBC
Ni ọjọ ti gbajumọ akọrin ẹmi, Bunmi Akinnaanu ti ọpọ m si omije oju mi' mi eemi ikẹyin, ti iroyin iku rẹ si jade da omi tutu si ọkan awọn ololufẹ rẹ kaakiri agbaye, ireti ọpọ ni pe ipa kekere kọ ni awọn akẹrẹ rẹ ti wọn jẹ akọrin ẹmi yoo ko ninu eto isinku rẹ.
Ni ibẹrẹ pẹpẹ eyi n lọ bẹẹ, amọṣa ọfọn tọ si gbẹgiri ọrọ laarin ẹbi oloogbe naa atawọn akọrin ẹmi, ni kaluku ba ko ẹkọ rẹ dani o.
Awọn akẹgbẹ Omije Oju mi to ti kọkọ kede eto isinku rẹ, pe yoo waye laarin ogunjọ oṣu kinni ki awọn ẹbi Oloogbe naa to ni a kii kere nidi nnkan ẹni ti wọn si yi i pada nigba naa.
Tẹ o ba gbagbe, olorin ẹmi miran, Alayo Melody Singer lo kọkọ kede ilana eto isinku naa pe yoo bẹrẹ lọjọ Iṣẹgun, ogunjọ oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 yii.
Ko pẹ sigba naa ni ẹnikan to pe ara rẹ ni Lanre Alewilese, toun naa jẹ akẹgbẹ Omije Oju mi, tun kede pe ẹbi Oloogbe ti fagile ikede iṣaaju, fun idi kan tabi ikeji.
Ki gan lo fa edeaiyede laarin ẹbi 'omije oju mi' atawọn akọrin ẹmi lori eto isinku nigba naa?

BBC News Yoruba wa nibi eto isinku ti ẹbi Akinnaanu gbe kalẹ naa, nibẹ ni ọkunrin kan, Eretan Olusola Olufemi ti iyawo rẹ jẹ ọmọ iya ati baba kan naa pẹlu Oloogbe Omije Oju mi ti ṣalaye lorukọ ẹbi naa pe:
"Emi jẹ bii ana si Sista Bunmi Akinnaanu, iyawo mi ni wọn bi tẹle e.
"Loootọ ni ẹbi yi ọjọ isinku pada, Sista Bunmi ku lọjọ Iṣẹgun, nigba ti yoo fi di Ọjọbọ ni a ri iwe ipe nipa bi wọn ṣe fẹ sinku.
"Mo pe iyawo mi lori ẹ, o loun ko mọ nipa ẹ.
"Igba ti mo pe ẹgbọn Sista Bunmi to jẹ àna agba fun mi, iyẹn Ọgbẹni Wale Akinnaanu, wọn sọ fun mi pe loootọ lawọn wa nibi ti wọn ti mu ọjọ isinku akọkọ, awọn si gba bẹẹ nitori ipo tawọn wa nigba naa, awọn ko tiẹ mọ nnkan kan, nitori aburo ni Oloogbe jẹ sawọn, gbogbo ẹ si ti daru mọ awọn loju."
Eretan ni oun sọ fun ẹgbọn Oloogbe pe ko yẹ ko ri bẹẹ, awọn ni lati gbọ lati ọdọ awọn ẹbi Oloogbe naa, kawọn naa si ṣepade tawọn.

Eyi lo mu Wale Akinnaanu sọ fun awọn akẹgbẹ Omije Oju mi lai ṣe suuru na, ki wọn ma ti I jẹ ki eto isinku naa waye.
"Nigba to sọ fun wọn, niṣe ni wọn binu. Wọn ni awon ti ra posi, awọn ti ṣe aṣọ funfun tawọn eeyan yoo wọ (vest) awon si ti sanwo sibi ti eto isinku naa yoo ti waye.
"Emi ba ni ṣe o wa ya bẹẹ yẹn ni, ṣe wọn ti ro pe o maa lọ tẹlẹ ni. Mo ni ki wọn fun mi ni nọmba aṣoju eto naa, mo si fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si i pe ko jọọ, ki wọn fun mi laye lorukọ ẹbi. Niṣe ni wọn sọ fun mi pe awọn ko fẹ da si ọrọ oku yẹn mọ."
O fi kun un pe awọn tun pe baba kan lati ba wọn sọrọ, niṣe ni wọn sọ fun baba naa pe to ba jẹ ọrọ Oloogbe Bunmi, awọn ko ni nnkan kan lati sọ lori ẹ.
Eeyan mẹfa ninu ẹbi lo pada ṣeto isinku yii bi Eretan ṣe wi, eyi ti oun naa wa ninu rẹ.
O ni awọn tuwọ jọ lawọn fi n ṣeto naa bo ṣe n waye.
- Ohun tí a mọ̀ rèé nípa àríyànjiyàn láàrin APC àti Gómìnà Adeleke tó ní sáà àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ APC l'Osun ti parí
- "Ìtọ̀ ara mi ni mo mu fún ọjọ́ mẹ́jọ nínú igbó lẹ́yìn tí mo sá máwọn ajínigbé lọ́wọ́"
- Ẹ fi Osugbo kún ìgbìmọ̀ afọbajẹ tí yóò yan Awujale tuntun- Ẹgbẹ́ Òsùgbó rọ Dapo Abiodun
- Itan Manigbagbe: Oba Asanike Yefusu Oloyede, Olubadan tó gbóyà, aláwàdà, tó tún kún fún ọgbọ́n
Awọn ọta inu ile oloogbe lo da ọrọ ru laarin ẹbi atawọn akọrin ẹmi lori eto isinku 'Omije Oju mi' - Aarẹ olorin ẹmi

Oríṣun àwòrán, Bunmi Akinnaanu/Facebook/ BBC
Nigba ti ọrọ ri bayii, BBC News Yoruba tun kan si awọn ẹgbẹ akọrin ẹmi, GOMAN lorilẹede Naijiria, leyi ti aarẹ ẹgbẹ naa, Ajihinrere Philip Olufẹmi Ọlayiwọla, tawọn eeyan mọ si Folat ti dahun pe kii ṣe pe awọn akọrin ẹmi ko fẹ wa sibi eto idagbere fun Bunmi Akinnaanu, ṣugbọn Bunmi Akinnaanu kere jọjọ si ọpọ awọn miran ninu wọn to si jẹ pe ko boju mu ninu aṣa Yoruba ki eeyan maa lọ sibi oku ẹni to kere sii.
Amọ nigba ti yoo sọrọ ọhun jake, Ajihinrere Ọlayiwọla ni "Ọta maa n wa ninu ile nigba mi-in, wọn bẹrẹ daadaa, wọn si n ṣe daadaa, pẹlu awọn ẹbi ni wọn papọ lati ibẹrẹ ti wọn jọ n ṣe e, ṣugbọn ọta wọle lai mọ.
Gẹgẹbi ọrọ rẹ, ọta yẹn lo fa ipinya to ṣẹlẹ yii, ko si ẹni to jẹbi, ọta lo wọle, wọn o dẹ fura.
"To ba jẹ pe agbalagba wa lati tete ṣe aarin yẹn ni, ko ba ma ri bayii."
Bi o tilẹ jẹ pe aarẹ ẹgbẹ GOMAN ko sọ ni pato ẹni ti wọn n pe ni ọta inu ile to da ọrọ ru yii, o ni ọpọ
Oni eyi jẹ idi ikan ti wọn ko fi wa.
Aarẹ GOMAN sọ pe idi miran ni pe ọpọlọpọ awọn gbajumọ olorin ẹmi yii ni ko si nile lasiko yii, nitori oun pe wọn, wọn si jẹ koun mọ pe wọn ko si nile.
"A ko bẹ olorin ẹmi kankan lati waa ṣere nibi Aṣalẹ awọn oṣere fun Oloogbe Omije Ojumi"

Amọṣa Ọgbẹni Olufẹmi Eretan sọ pe irọ lasan lawọn akọrin ẹmi n pa pe ẹbi oloogbe naa n ja. O ni eyi ko ri bẹẹ rara nitori pe ibanujẹ nla lo gba ọkan awọn ẹbi rẹ nigba ti iku rẹ ṣẹlẹ.
" A ko fẹ ija, idi niyẹn ti ẹbi ko fi da wọn lohun lori ayelujara, nitori ohun to n ṣe wọn yatọ si ohun to n ṣe awa. Iyawo mi gan-an o le jẹun, awọn kan jẹ ọrẹ si i ni, wọn o mọ ohun ti awa ẹbi n la kọja."
Eretan sọ pe oun ri i lori ayelura tawọn kan sọ pe awọn n bẹ awọn olorin ẹmi naa lati waa ṣere nibi eto ti ẹbi gbe kalẹ yii, o ni irọ ni wọn fi pa.
Ni itẹsiwaju ọrọ rẹ, Olufemi Eretan sọ pe aiyọju awọn olorin ẹmi naa ko da ohunkohun duro, ati pe awọn ko bẹ wọn lati waa kọrin nibi eto aṣalẹ oṣere, bawọn kan ṣe n gbe e kiri lori ayelujara.
"A ko bẹ ẹnikẹni lati wa ṣere, amọ awọn oṣere to mọ pe ọrẹ ati akẹgbẹ awọn ni lo pinnu lati wa sibi, wọn si yẹ Oloogbe Bunmi Akinnaanu si."

Bakan naa lo ni mọlẹbi Akinnanu ko ba ẹnikan kan ja, bi wọn ba ni ẹri ibi ti ẹbi ti sọrọ ibinu, ki wọn mu un jade.
O ni ki wọn sun eto siwaju lawọn wi, iyalẹnu lo jẹ pe niṣe ni wọn ni awọn ko ṣe mọ rara.
Bi ẹnikẹni ba wa tẹsiwaju lati maa ba orukọ ẹbi Akinnaanu jẹ, Olufemi Eretan sọ pe ofin to de sisọ ohun ti ko ri bẹẹ lori ayelujara wa ni Naijiria.
O ni oun yoo funra oun pe iru ẹni bẹẹ lẹjọ, yoo si de kootu ṣalaye ara rẹ, Adajọ yoo ba wọn da a.
Lara awọn olorin ẹmi to ṣẹṣẹ n gunke agba to wa nibi eto naa ni: Jojolo Jesu ati Oniṣẹ Ara.
Asiko ọrọ ko ti i to, ẹ jẹ ki ẹni to kú sinmi- Alayo Singer

Oríṣun àwòrán, Alayo Medody Singer/ Facebook
BBC NEWS Yoruba kan si akọrin ẹmi ati Tungba, Akinola Ayoola Michael tawọn eeyan mọ si Alayo Melody Singer lori ọrọ yii.
Alayo ṣalaye pe ko ti ya ti oun yoo sọrọ lori iṣẹlẹ yii.
Gẹgẹ bo ṣe wo:
"Lakọọkọ, orilẹede UK ni mo wa bayii, mi o si ni Naijiria, iyẹn jẹ idi akọkọ ti mi o fi wa sibi eto naa.
"Ikeji ni pe asiko ọrọ ko ti I to bayii, ohun to ṣe pataki ni pe ka jẹ ki ẹni to ku sinmi.
"Ọmọde lo ku, awọn ọmọ rẹ naa ko si ti i dagba, mi o fẹ sọ ju bẹẹ lọ."
Nipa pe oun lo kọkọ kede eto isinku akọkọ ti ọrọ si pada wa ri bayii, Alayo sọ pe oun ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ GOMAN, oun kan darapọ mọ ikede akọkọ naa gẹgẹ bii oun ṣe n ba gbogbo wọn ṣe ni, oun ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ kankan.
O ni ẹni to ba mọ nnkan ki I tu u ka, oun n ṣe toun lati ria anu Oluwa ni, ki I ṣe lati gba ire lọwọ ẹnikẹni.
O ni ṣugbọn pẹlu ẹ naa, ohun to ṣẹlẹ yii ko to nnkan toun yoo sọrọ si lasiko yii, nitori boun ba sọrọ, ohun ti aye yoo maa gbe kiri niyẹn.
Alayo ni oun ko fẹ ohun ti yoo da wahala silẹ ninu ẹbi tabi nibikibi, o daa lati dakẹ si ohun ti ẹbi ba sọ lasiko yii, ju ki oun sọrọ ti yoo tun da ariwo silẹ lọ.
Ṣaa, oni Ọjọbọ, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026 ni ẹbi Akinnaanu yoo sinku Oloogbe Omije Ojumi si itẹ oku Atan, nipinlẹ Eko.
Aago mẹwaa aarọ ni wọn pe eto ọhun, a o maa mu un wa fun yin bo ba ṣe lọ.
Awọn ohun to yẹ ki o mọ nipa Oloogbe Omije Oju mi ree:

Oríṣun àwòrán, Omije Ojumi/ BBC
Ọjọ kọkandinlogun, oṣù Kọkànlá ọdún 1979 ni wọ́n bi Bunmi Alaba Oriyomi Bolatito Akinnanu nílùú Eko
Ilé ìfowópamọ̀ ló ti ń ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀ kó tóó di olórin ẹ̀mí
Lára àwọn orin tó sọ Olóògbé náà di gbajúmọ̀ ni "Omije Ojumi" ati " Ma sunkun mọ"
Ó ṣe àìsàn fún ọjọ́ púpọ̀ kí ólọ́jọ́ tóó dé
Oun ati ọkọ rẹ ko si papọ mọ gẹgẹ bi akọbi rẹ, Jomiloju, ṣe sọ ọ di mimọ lasiko to n gboriyin fun mama rẹ nibi eto isinku naa.
Jomiloju sọ pe akikanju iya to gbe ile aye rẹ fun awọn ọmọ ni Omije Oju mi.
O ni fun ọpọ ọdun ti baba awọn ko fi yà si awọn, iya to di oloogbe yii lo n da ẹru naa gbe.
Amọ lasiko yii ti iya awọn ku, ọmọ naa sọ pe baba awọn bẹrẹ si i pe lori aago lati beere alaafia oun ati aburo oun ọkunrin ti mama awọn fi saye lọ.
Ọmọ bibi ipinlẹ Ondo ni Bunmi Omije Oju mi, bo tilẹ jẹ pe Mushin, nipinlẹ Eko ni wọn bi I si.
O jade laye lẹni ọdun mẹrindinlaadọta (46).
Ọmọ, awọn ẹbi ati ọkọ lo gbẹyin rẹ.














